Ìyá àgbà pín gbogbo ogún rẹ̀ fún olóńgbò àti ajá nítorí pé àwọn ọmọ tó bí kò rántí rẹ̀ lásìkò tó n ṣàìsàn

Oríṣun àwòrán, Aja ati Olongbo/Google
Iya agbalagba kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Liu ti kede sita pe oun ti pin gbogbo ogun oun fun awọn ohun ọsin toun ni.
Liu sọ pe oun ti gbe awọn ogun oun naa to din diẹ ni miliọnu mẹta owo dọla ($2.8 million) le awọn ohun ọsin toun n sin lọwọ ati awọn ọmọ ti wọn ba bi, nitori aibikita awọn ọmọ oun lasiko toun wa ni idubulẹ aisan.
Liu, ọmọ bibi ilu Shanghai ọhun sọ pe awọn ọmọ mẹta toun bi saye ko gbọdọ ni anfaani si ogun toun fẹẹ si silẹ, nigba toun ba ti ku.
O sọ pe awọn ohun ọsin naa nikan loun n ri lawọn asiko toun fi wa lori idubulẹ aisan.
Iya agba naa sọ pe ko si eyikeyi ninu awọn ọmọ mẹta ti oun bi, to yọju soun nile iwosan, bi ko ṣe pe awọn ohun ọsin oun nikan ni wọn duro ti oun.
Gẹgẹ bi iroyin Zonglan News ti The South China Morning Post to gbe iroyin ọhun sita ṣe sọ, wọn ni iya agba yii ti kọkọ ṣe iwe ogun rẹ lọdun diẹ sẹyin fun awọn ọmọ rẹ mẹtẹẹta.
Gbogbo owo ati dukia ti Liu ni lo pin fun awọn ọmọ rẹ patapata, ṣugbọn to tun ti wa yi ipinu rẹ pada wi pe awọn ọmọ naa ko yọju soun lori idubulẹ aisan.
O ni awọn ologbo wọnyi loun n ri lasiko ọjọ ogbo oun, to si ni gbogbo owo oun to jẹ ogun miliọnu Yuan, owo ti wọn n na lorileede China, eyi ti apapọ rẹ jẹ miliọnu mẹtadin diẹ ($2.8 million) owo dọla.
Liu ni gbogbo owo toun ni patapata ni ki wọn fi maa tọju awọn ologbo oun ati awọn ọmọ ti wọn ba tun bi lẹyin toun ba ti fi aye silẹ.
Liu fẹẹ gbe gbogbo ogun naa silẹ fun awọn ohun ọsin rẹ taara, ṣugbọn ipinnu yii ko ba ofin ilẹ China mu, gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ri sọrọ ogun ni China, Will Registration Centre to wa ni Beijing ṣe sọ.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ni Will Registration Centre, Chen Kai sọ pe “Ju gbogbo rẹ lọ, ọna miran wa lati fi yanju ọrọ yii.
“Iwe ogun Liu doju kọ ọna kan ṣoṣo, ṣugbọn a maa gba a nimọran lati yan ẹnikan ṣoṣo ti yoo ṣakoso ile iwosan ti yoo maa ṣakoso awọn ohun ọsin naa daadaa.”
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ yii tun sọ pe awọn ti jẹ ki Liu mọ awọn ipenija ati atubọtan to maa n wa nigba ti wọn ba gbe owo si ikawọ ile iwosan to n tọju awọn ohun ọsin.
“A ti sọ fun Anti Liu pe bi awọn ọmọ rẹ ba yi iwa wọn pada sii, o le tun iwe ogun rẹ ṣe.”
Igbesẹ Liu yii ti da ariyanjiyan silẹ laarin awọn araalu, ti onikaluku si n sọ oriṣiriṣi nipa rẹ.












