Gómìnà Zamfara ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìpínlẹ̀, ó gba 2,645 èèyàn síṣẹ́ láti kojú ìpèníjà ètò aàbò

Oríṣun àwòrán, Dauda Lawal/Facebook
Gomina ipinlẹ Zamfara, Dauda Lawal ti da ẹṣọ eleto abo ipinlẹ silẹ lati le tubọ koju eto abo to mẹhẹ ni ipinlẹ naa.
Gomina Lawal to pe orukọ ẹṣọ naa ni Askarawa Zamfara, sọ pe awọn ẹṣọ naa yoo maa ṣe iranwọ fawọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ eleto abo to wa tẹlẹ.
Ni oṣu kọkanla ọdun 2023 nikan, iroyin sọ pe ọgọrun un eeyan tawọn ọmọde atawọn obinrin pọ ninu wọn lawọn ajinigbe gbe lọ ni ijọba ibilẹ Maru ni Zamfara.
Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ọsẹ kan tawọn eeyan mẹẹdogun mii ti kọkọ bọ sọwọ awọn ajinigbe agbegbe Ruwandoruwa ni ijọba ibilẹ kan naa.
Nigba ti o n sọrọ nibi ifilọlẹ ẹṣọ alaabo naa, Gomina Lawal ni oun ṣetan lati fopin si awọn janduku to n ṣọṣẹ ni ipinlẹ naa.
O rọ awọn ẹṣọ naa lati ṣiṣẹ takuntakun ki eto abo le kẹsẹ jari nipinlẹ Zamfara.
Gomina Lawal ni ijọba oun ṣetan lati pese ohun gbogbo ti wọn nilo lati ṣiṣẹ to wa niwaju wọn.
''Awọn eto ti a fi ṣe fun araalu ko le wa si imuṣẹ niwọn igba ti iṣoro eto to ẹhẹ ba si wa nibẹ.
Idi abajọ gan an niyii ti a fi ṣe ifilọlẹ ẹṣọ alaabo ipinlẹ ti a pe ni Askarawa Zamfara.
Igbimọ to ṣagbatẹru Askarawa Zamfara kaakiri ijọba ibilẹ mẹrinla lati wa gbogbo awọn eeyan ti wọn gba si ẹṣọ naa.
Isọri akọkọ ninu awọn ẹṣọ Askarawa Zamfara to ti pari idanilẹkọ ati igbaradi wọn tan ni awọn 2,645 ti a ṣe afihan bayii.
Awọn gomina lati awọn ipinlẹ ẹkun guusu ariwa bii of Jigawa, Kebbi, Kaduna, Kano, Katsina ati Sokoto lo wa nibi ifilọlẹ naa niluu Gusau.
Ẹṣọ alaabo ipinlẹ ti gomina Zamfara ṣe ifilọlẹ yii dabi ẹṣọ Amotekun tawọn gomina ipinlẹ ti ṣaaju ṣe ifilọlẹ rẹ kaakiri awọn ipinlẹ iwọ oorun guusu Naijiria.















