Olayide Adelami di igbákejì gómìnà Ondo

Oni ni eto ibura fun igbakeji gmina ipinlẹ Ondo, Ọlayide Adelami waye niluu Akure.
Ọjọ kẹtalelogun ni gomina Lucky Aiyedatiwa kede Adelami yan Adelami lati ṣe igbakeji ti o si fi orukọ ranṣẹ si ile igbimọ aṣofin fun ibuwọlu.
Aiyedatiwa ṣe ikede yii lẹyin wakati diẹ ti o tu igbimọ alaṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo ka.
Lẹyin gomina fi orukọ Adelami ransẹ sile igbimọ aṣofin naa ni ile buwọlu iyansipo rẹ lẹyin ti wọn ti ṣe abẹwo fun un tan.
Ninu ọrọ rẹ, Adelami dupẹ lọwọ gomina Aiyedatiwa fun bi o ti yan an ni igbakeji rẹ.
O ṣeleri pe oun ko ni da a, oun ko si ni ja a kulẹ pẹlu igboya ti o ni ninu oun.
Awọn aworan lati ibi ayẹyẹ naa niyi:



Ta ni Olayide Adelami igbákejì gómìnà tuntun ní ìpínlẹ̀ Ondo?
Oloye Olayide Adelami jẹ ọmọbibi ilu Owo ni ipinlẹ Ondo.
A bi Oloye Adelami si idile Pa ati Iyaafin Amos AdelamI ni ọjọ kẹta oṣu Kẹrin ọdun 1958, eyi to tumọ si pe ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin ni i ṣe.
Adelami lọ si gbajugbaja ile ẹkọ Imade College niluu Owo.
Lẹyin naa ni o ṣe idanwo girama GCE nile ẹkọ gbogbonṣe ti ilu Ibadan ki o to kẹkọọ gboye ni fasiti UNILAG nibi ti o ti kẹkọọ nipa owo ṣiṣe.
Adelami tun tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ nigba to gba oye fasiti keji MBA ni ile ẹkọ fasiti ipinlẹ Ogun.
Lẹyin ti o kopa tan ninu eto agunbanirọ ọlọdun kan loṣu kẹfa ọdun 1983, Adelami bẹrẹ iṣẹ ijọba gẹgẹ bi oluṣiro owo ni ọgagba oluṣiro owo lorilẹede Naijiria.
Ni ọdun 1988 ni wọn gbe lọ si ọfiisi ile igbimọ aṣofin agba nilu Abuja.
O si wa lara awọn to kọkọ ṣiṣẹ ni ọfiisi ile igbimọ aṣofin l'Abuja ti o di eyi tawọn sẹnẹtọ ati aṣoju-ṣofin n lo lonii.
Adelami lo ṣe idasilẹ ẹka eto inawo ati apo ikowosi nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja.
Bayii ni wọn ranṣẹ pe Adelami pe ki o wa ṣe idasilẹ ẹka eto inawo ati apo ikowosi fun ajọ to n ri si ere ori owo epo.
Lẹyin ti o ṣe iyẹn tan ni o tun lọ ṣe idasilẹ ẹka eto inawo fun ajọ to n ri si iranwọ fun idile.
Adelami ṣe olori oniruuru ẹka laarin ọdun 1996 si 2000.
Lasiko ti o n ṣiṣẹ yii gan an ni ijọba da ile iwosan ijọba apapọ ilu Abuja silẹ.

Oríṣun àwòrán, Olayide Adelami/Facebook
Adelami wọ agbo oṣelu lẹyin to fẹyinti lẹni iṣẹ ọba
Kete ti o fẹyinti lẹnu iṣẹ ọba ni Adelami kanlu agbami oṣelu.
Ileeṣẹ yan an gẹgẹ bi oludari igbimọ to n ṣatilẹyin fun aarẹ nipinlẹ Ondo.
Iṣẹ ti wọn gbe le e lọwọ ni lati pẹtu si aawọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn n ba ara wọn ja.
Lara iṣẹ ti wọn tun gbe fun un ni pe ki sẹ agbatẹru bi oniruuru ajọ yoo ṣe ṣatilẹyin fun aarẹ Muhammadu Buhari ki o le wọle ibo fun saa keji.
Adelami 'siṣẹ takuntakun fun ẹgbẹ oṣelu APC, o ṣi rii pe sẹnẹtọ kan ṣoṣo ti APC ni nipinlẹ to wa lati ẹkun oṣelu rẹ.
Adelami jẹ ọjulowo ọmọ ẹgbẹ oriṣiiriṣii ẹgbẹ akọmọṣẹmọṣẹ bii FCNA, FNIM, FCTI ati FCMA















