Lásìkò tí Pásítọ̀ ń kìlọ̀ fáwọn darandaran tó d'ẹran jẹ oko rẹ̀ l'Ogbomoso ni wọ́n gún un lọ́bẹ pa - Ẹ̀gbọ́n olóògbé

Pasito ti wọn pa ni Ogbomoso ati oko rẹ

Taiwo Jacob to jẹ ẹgbọn pasitọ Segun Adegboyega tawọn afurasi Fulani darandaran ṣeku pa loko rẹ ni agbegbe Gege to wa ni opopona Ogbomoso si ilu Iseyin ti sọ pe lasiko ti o n kilọ fawọn darandaran to da ẹran jẹ oko rẹ ni wọn gun un lọbẹ pa.

Awọn darandaran naa ni won ko ẹran wọn jẹ oko Pasitọ Adegboye lọjọ Ajẹ ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kinni ọdun yii ti oloogbe naa si koju wọn lati dẹkun iwa ibi wọn.

Ẹ̀gbọ́n oloogbe naa sọ fun BBC Yoruba pe "ile ẹkọ ni pasito Segun wa nigba ti iyawo rẹ pe e lati wa ba awọn darandaran to da ẹran wọn gba inu oko iṣu rẹ.

Igba akọkọ ko niyi ti pasito ti n pe akiyesi awọn darandaran naa lati mu awọn ẹran wọn gba ibomiran ti wọn ko si da pasitọ Adegboyega lohun.

Ọgbẹni Jacob ni gbogbo oko oloogbe ọhun ko ju ebe iṣu diẹ lọ yatọ si ibi ti o gbin ẹ̀fọ́ ati ewedu si lọ.

Leyin ariyanjiyan to waye laarin oloogbe naa ati awọn Fulani darandaran, ọkan ninu awọn Fulani ọhun gun Pasito Adegboyega lọbẹ latẹyin kí wọn to salọ.

Okada ni a fi gbe oloogbe lọ sílè ìwòsàn kò tó gbẹmi mi.''

Lara awọn ọdọ agbegbe Gege nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ṣalaye wi pe,"Pasitọ Adegboyega ti ṣaaju akoko yii ni ariyanjiyan ranpẹ pẹlu awọn Fulani ọhun, nitori gaa wọn kò jinna si ile pasitọ Adegboyega.

“Lọjọ ti pasitọ Adegboyega ku, iyawo mi pe mi ki n maa bọ wa si ile nitori wọn ti gun pasitọ lọbẹ.

Loju ọna ni mo ti pade awọn to n gbe wọn lọ si ile iwosan, koda ọkada la lo láti gbe wọn.

O ku diẹ ka de ile iwosan ni wọn padanu ẹmi wọn, oju ẹsẹ ti a de ile iwosan awọn dokita tiraka lati doola ẹmi wọn ṣugbọn epa ko boro mọ.

Lẹsẹkẹsẹ ni a ko ara wa jọ lati wa awọn Fulani naa, wakati diẹ lẹyin ti a n wa wọn kaakiri inu igbo là bawọn pade ṣugbọn a o rí ẹni ti o ṣiṣẹ ibi naa.

Ṣugbọn atẹni to ni agbo maalu àti awọn to ba n da a la ko lọ si aafin Soun Ọba Ghandi Olaoye.

Soun ti ile Ogbomoso nigba ti o n ba awọn ara ilu sọrọ ṣeleri wi pe awọn to lọwọ si iku Pasitọ Adegboye yoo foju wina ofin.

Oba Olaoye ni oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbofinro lati ri daju wi pe idajọ ododo waye tí opin yoo si de ba iru iṣẹlẹ naa nilu Ogbomoso.

Afurasí darandaran ṣekúpa Pásítọ̀ nínú oko rẹ̀ l’Ogbomoso, Soun ní wọ́n á fojú winá òfin

Aworan pasitọ atawọn afurasi darandaran

Oríṣun àwòrán, Other

Pasitọ ijọ aladani ni kan, Adegbouega to tun n ṣiṣẹ agbẹ ni a gbọ pe awọn afurasi Fulani darandaran ti ṣekupa ninu oko rẹ ni agbegbe Gege to wa ni opopona Ogbomoso si ilu Iseyin ni ipinlẹ Oyo.

Awọn afurasi darandaran naa ni a gbọ pe wọn da jẹ ẹran jẹ oko Pasitọ Adegboye lọjọ Ajẹ ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kinni ọdun yii ti oloogbe naa si kọju wọn lati ko ẹran wọn kuro ninu oko rẹ.

Iroyin fìdi rẹ mulẹ wi pe niṣe lawọn darandaran fulani naa kọju ija si pasitọ yii ti wọn si gun un lọbẹ titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.

Lẹyin isẹlẹ naa lawọn araalu mu awọn afurasi darandaran mẹta ti wọn sọ pe wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ ọhun.

Lẹsẹkẹsẹ ni wọn si gbe wọn lọ si aafin Soun ilu Ogbomoso, Oba Ghandi Olaoye Orumogege 111.

Aworan Soun atawọn araalu Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Other

Kabiyesi ko beṣu bẹgba lati paṣẹ pe ki wọn gbe wọn lo si ahamo ọgba awon olopaa to wa ni agbegbe Owode niluu Ogbomoso.

Soun ti ile Ogbomoso nigba ti o n ba awọn ara ilu sọrọ ṣeleri wi pe awọn to lọwọ si iku Pasitọ Adegboye yoo foju wina ofin.

Oba Olaoye ni oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbofinro lati rii daju wi pe idajọ ododo fìdi waye kí opin si deba iru iṣẹlẹ naa niluu Ogbomoso.

Awọn afurasi mẹta naa ni a gbọ pe wọn ti wa ni ahamọ ọlọpaa niluu Ibadan bayii.