Ìjà ààlà ilẹ̀ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́ta ní ìlú Ilobu àti Ifon ní Osun

Ènìyàn tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìkọlù náà

Oríṣun àwòrán, Others

Ènìyàn mẹ́ta ti pàdánù ẹ̀mí wọn bí wàhálà tuntun ṣe bẹ́ sílẹ̀ láàárín ìlí Ifon àti Ilobu ní ìpínlẹ̀ Osun.

Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé ní àwọn ìlú méjéèjì ló pàdánù àwọn ènìyàn wọn sínú ìkọlù tuntun náà.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni wàhálà bẹ́ sílẹ̀ ní àwọn ìlú náà àmọ́ wọn kò sọ ohunkóhun lórí iye ènìyàn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.

Láti ọjọ́ pípẹ́ ni ìfaǹfà ti máa ń wáyé láàárín ìlú Ilobu àti Ifon lórí ọ̀rọ̀ ààlà ilẹ̀.

Ní oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 ni ìjọba kéde òfin kónílé-ó-gbélé ni àwọn ìlú méjéèjì yìí lẹ́yìn tí wàhálà ńlá kan tó mú kí àwọn ènìyàn pàdánù ẹ̀mí dùkíà wọn wáyé nígbà náà.

Lẹ́yìn tí ìjọba ri wí pé àláfíà ti ń padà jọba ní agbègbè náà nínú oṣù Kejìlá ni ìjọba mú àyípadà bá òfin náà.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn kan sọ, ní ẹnubodè ìpínlẹ̀ Osun àti Oyo ni ìjà ti bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn ìlú méjéèjì kí wọ́n tó gbé ìjà náà wọ àárín ìlú lọ.

Otun Jagun ti ìlú Ilobu, olóyè Leke Ogunsola nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní àwọn jàǹdùkú kan láti ìlú Ifon ló kọ́kọ́ ṣe ìkọlù sí àwọn àgbẹ̀ Ilobu ní ìlú Ologele àti Aganna tí wọ́n sì pa àgbẹ̀ kan, tí àwọn mìíràn sì farapa.

Àmọ́ akọ̀wé ẹgbẹ́ Ifon Progressive Union Board of Trustees, Ọmọba Jide Akinyooye ní bẹ́ẹ̀kọ́ ni ọ̀rọ̀ rí rárá.

Ó ní àwọn jàǹdùkú ìlú Ilobu ló lọ ṣèkọlù sáwọn ènìyàn Ifon tí wọ́n sì dá ọgbẹ́ síwọn lára.

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ìlú méjéèjì yìí ló ti fi ìlú sílẹ̀ láti sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Osun, Yemisi Opalola ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti da àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò sí agbègbè náà láti mójútó àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.