Amẹ́ríkà buwọ́lu ṣíṣe ìkọlù sáwọn Iran ní Syria àti Iraq

Awọn ọmọ ogun US ní Syria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìjọba Amẹ́ríkà ti buwọ́lu èrò láti ṣe ìkọlù sí àwọn Iran ní orílẹ̀ èdè Syria àti Iraq.

Àwọn aláṣẹ Amẹ́ríkà ló fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún iléeṣẹ́ ìròyìn CBS pé ọjọ́ bíi mélòó kan ni ìkọlù náà yóò fi wáyé àti pé bí ojú ọjọ́ bá ṣe rí ni yóò sọ ìgbà tí àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ ìkọlù náà.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun mẹ́ta Amẹ́ríkà pàdánù ẹ̀mí wọn ní Jordan, ní ẹ̀bá ẹnubodè Syria lọ́jọ́ Àìkú.

Amẹ́ríkà di ẹ̀bi ìkọlù náà ru ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Iran.

Ikọ̀ náà, Islamic Resistance ní Iraq ni ìgbàgbọ́ wà pé ó kó àwọn agbéṣùmọ̀mí sínú èyí tí ikọ̀ Revolutionary Guards force ń ṣe àtìlẹyìn fún.

Wọ́n ní àwọn ni àwọn nídìí ìkọlù tí àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà ti pàdánù ẹ̀mí wọn.

Àmọ́ ìjọba Iran ti jiyàn pé àwọn kò lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà tí èyí mọ́kànlélógójì ti farapa ní Tower 22.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, akọ̀wé iléeṣẹ́ ológun US, Lloyd Austin ní Amẹ́ríkà kò ní fàyè gba ìkọlù sí ikọ̀ ológun Amẹ́ríkà kankan.

“A máa gbé gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ láti dá ààbò bo Amẹ́ríkà àti àwọn ènìyàn inú rẹ̀.

“A máa fèsì nígbà tó bá wù wá, ibi tó bá wù wá àti bó bá ṣe wù wá.”

Àwọn aláṣẹ tó bá iléeṣẹ́ ìròyìn CBS News kò sọ iye ìgbà tí ìkọlù náà fi máa wáyé. Wọ́n ní kò sí ìgbà tí àwọn kò lè ṣèkọlù ọ̀hún àmọ́ àwọn ń fẹ́ àsìkò tí ojú ọjọ́ máa mọ́lẹ̀ kedere láti lè ri pé àwọn kò ṣe ìpalára fún àwọn ará ìlú lásìkò ìkọlù náà.

Pẹ̀lú bí US ṣe ti ń tẹnumọ pé àwọn máa gbẹ̀san ìkọlù náà, ààrẹ Amẹ́ríkà, Joe Biden ní àwọn kò ní gbé ogun kojú orílẹ̀ èdè Iran tàbí tún pọn kún ogun tó ń wáyé ní ẹkùn náà.

Iran jiyàn lílọ́wọ́ nínú ìkọlù tó ṣekúpa ọmọ ogun Amẹ́ríkà mẹ́ta ní ẹnubodè Jordan

Ibi tí ìkọlù náà ti wáyé

Oríṣun àwòrán, PLANET LABS/AP

Orílẹ̀ èdè Iran ti ní àwọn kò lọ́wọ́ nínú ìkọlù tí wọ́n ṣe sí ibùdó orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹnubodè Jordan pẹ̀lú Syria níbi tí àwọn ọmọ ogun US mẹ́ta ti pàdánù ẹ̀mí wọn.

Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti dẹ̀bi ìkọlù ọ̀hún, níbi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti farapa, ru àwọn ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Iran kan.

Ààrẹ Amẹ́ríkà, Joe Biden ti ṣèlérí pé àwọn máa dáhùn sí ìkọlù náà.

Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà yóò máa pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù láti ìgbà tí wàhálà ti bẹ́ sílẹ̀ láàárín Israel àti Gaza láti ọjọ́ Keje oṣù Kẹwàá ọdún 2023.

Iye ìgbà tí wọ́n ti ṣèkọlù sí ibùdó Amẹ́ríkà ní Iraq, Syria àti Jordan

Iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà ni wọ́n ti ń ṣe ìkọlù sí àwọn tẹ́lẹ̀ àmọ́ kò sí èyí tó la ẹ̀mí lọ àyàfi èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé yìí.

Ikọ̀ Islamic Resistance tó wà ní Iraq ní àwọn ni àwọn wà nídìí ìkọlù náà.

Ní bíi ìparí ọdún 2023 ni wọ́n dá ikọ̀ náà sílẹ̀, tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn sì jẹ́ lára àwọn ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Iran tó ń ṣọṣẹ́ ní Iraq.

Wọ́n ti ṣaájú sọ pé àwọn ló wà nídìí àwọn ìkọlù tó ń wáyé sí Amẹ́ríkà lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.

Kini o kọkọ ṣẹlẹ?

Àtẹ̀jáde kan tí ikọ̀ náà fi léde ní àwọn ibùdó Amẹ́ríkà mẹ́ta tó wà ní Syria ìyẹn Shaddadi, Tanf àti Rukban ni àwọn ń gbèrò láti ṣe ìkọlù sí àti pé àwọn tún ń gbèrò láti ṣèkọlù sí ibùdó epo Israel kan.

Wọ́n ní àwọn ọmọ ogún náà wà nínú yàrá tí wọ́n máa ń sùn sí kí ìkọlù náà tó wáyé.

Ìjọba orílẹ̀ èdè Iraq ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà tí wọ́n sì ń pè fún fífi òpin sí ìkọlù àtí wáhàlá tó ń wáyé ní ẹkùn náà.

Agbẹnusọ ìjọba Iraq, Bassem al-Awadi ní orílẹ̀ èdè àwọn ṣetán láti ní àjọṣepọ̀ láti ri pé gbogbo wáhàlá tó ń wáyé ní ẹkùn náà dópin.

Kini America fẹ ṣe bayii?

Ààrẹ Amẹ́ríkà, Biden ní àwọn máa ri pé gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà ni àwọn máa fi jófin lásìkò tó bá wu àwọn.

Agbẹnusọ ètò ààbò ní White House, John Kirby ní US ń wá ọ̀nà tí wọ́n fi máa gbẹ̀san ìkọlù náà ní ọ̀nà tí ogun ńlá kò fi ní wáyé láàárín Amẹ́ríkà àti Iran.

Ìjọba Iran ní àwọn kò lọ́wọ́ nínú ìkọlù tí àwọn agbéṣùmọ̀mí náà ṣe àti pé ẹ̀sùn tí UK àti US fi ń kan àwọn kìí ṣe òótọ́.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèerè, Nasser Kanaani ní àwọn kò lọ́wọ́ nínú ìpinnu àwọn ikọ̀ náà láti gbèjà Palestine.

Olóòtú ìjọba UK, Rishi Sunak bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà, tó sì rọ Iran láti yé dá kún wàhálà tó ti ń lọ lọ́wọ́.