Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ogun tí kede pe Hon Philip Aivoji, ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Eko ti gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe.
Agbẹnusọ sọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Omolola Odutola lo kede ọrọ ninu atẹjade kan to fi ransẹ si awọn akọroyin lọjọ Aje.
"Owurọ ọjọ Aje ni Aivoji gba itusilẹ lọwọ awọn to jigbe
"O ti wa pẹlu awọn mọlẹbi rẹ bayii ti igbiyanju sì n lọ lati ri pe owo tẹ àwọn ajinigbe naa."
Àwọn ajínigbé ṣọṣẹ́ ní òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan, pa ènìyàn kan, jí alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbé lọ

Oríṣun àwòrán, Others
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti ní àwọn ti dóòlà àwọn ènìyàn mẹ́sàn-án kúrò lọ́wọ́ àwọn ajínigbé.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá Ogun, Omolola Odutola nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní nǹkan bíi aago méje alẹ́ lọ́jọ́bọ̀ ni àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí ajínigbé kan ṣàdédé yawọ òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan.
Odutola ní àwọn afurasí ajínigbé náà dí ojú ọ̀nà tí wọ́n sì dàbọn bolẹ̀ láti dẹ̀rù ba àwọn ènìyàn tó wà nínú ọkọ̀ ní òpópónà yìí.
Ó ní èyí mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn fi ọkọ̀ wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì ń sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn nínú igbó.
Ó ṣàlàyé pé ní kété tí àwọn ọlọ́pàá Isara gbọ́ ni wọ́n bẹ́ síta láti lọ dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn náà, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun kan tí wọ́n ń kọjá lọ.
Ó ní èyí mú kí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò àtàwọn ajínigbé náà kojú ìbọn síra wọn, tí àwọn sì dóòlà ènìyàn mẹ́sàn-án nínú àwọn mẹ́wàá tó wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ó fi kun pé nígbà tí àwọn ri pé kò sí àwọn ajínigbé náà lójú ọ̀nà mọ́ ni àwọn ènìyàn ti àwọn dóòlà yìí tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn.
Bákan náà lọ ṣàlàyé pé ènìyàn mẹ́ta farapa látara ọta ìbọn tó bà wọ́n níbi ìkọlù ọ̀hún àti pé wọ́n wà ní ilé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà tún ṣàlàyé pé obìnrin kan, Biliksu Kazeem pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò tí wọ́n ń gbe lọ sílé ìwòsàn látara ọta ìbọn tó fara gbà nínú ìkọlù ọ̀hún àti pé àwọn ẹbí rẹ̀ ti gba òkú rẹ̀ láti lọ sín.
Ó tẹ̀síwájú pé àwọn ajínigbé náà tún jí ènìyàn kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Philip Aivoji, ẹni tó jẹ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ní ìpínlẹ̀ Eko.
Ó ní àwọn ti ń sa gbogbo ipá àwọn láti ri dájú pé àwọn dóòlà ẹgbẹ́ òṣèlú náà kúrò ní àhámọ́ àwọn ajínigbé náà.
“Lára àwọn nǹkan tí a rí níbi ìkọlù ọ̀hún ni ìbọn AK47, ọta ìbọn 28 tí ìgbàgbọ́ wà pé àwọn ajínigbé náà ló ni í.”
Ó fi kun pé kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Ogun, Alamutu Abiodun ti ní kí àwọn ṣàwárí Philip Aivoji láì farapa , tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ri pé ọwọ́ òfin tẹ àwọn afurasí náà.















