Low Sperm count: Àwọn nkan tí o le ṣe rèé láti mú kí àtọ̀ rẹ ní agbára láti di ọmọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipa to ṣe koko ninu irinajo ọmọ bibi ni atọ ọkunrin jẹ, idi si ni pe bi atọ naa ba ṣe kun oju oṣuwọn to, ni yoo sọ boya o le sọ ẹyin obinrin di ọmọ.
Oligozoospermia si ni orukọ ti awọn onimọ iṣegun oyinbo ma n pe atọ ọkunrin ti ko pè é to lati di ọmọ.
Onka atọ ọkunrin to poju owo gbọdọ pe milimita miliọnu mẹẹdogun.
- Wo ànfàní ‘Masturbation’, fífún ara rẹ̀ ní adùn ìbálòpọ̀
- Wo àwọn oúnjẹ márùn ún tó ń mú kí àtọ̀ ọkùnrin dára síi
- Ṣé ǹkan ọmọkùnrín rẹ ò ní padà kéré báyìí? Wo tuntun tí onímọ̀ Sáyẹ̀nsì gbéjáde
- Ojú wa rí, a ṣe IVF, oyún ìbeji bàjẹ́ kí á tó di ọlọ́mọ láyé - Adesua àti Banky W
- Wo oríṣiríṣi ìgbádun ibálòpọ̀ láwọn orílẹ̀èdè mìíràn
- Ṣé irúfẹ́ oúnjẹ tí ò ń jẹ́ lè jẹ́ kí o gbádùn ìbálòpọ̀ rẹ síi?
Ọkunrin le ma a da atọ si ara obinrin lasiko ibalopọ, ṣugbọn eyi ko sọ pe atọ naa le di ọmọ.
Iyalẹnu to si wa nibẹ ni pe, ọkunrin ti atọ rẹ ko le di ọmọ ko le mọ, ayafi to ba ṣe ayẹwo nileewosan, ti ayẹwo si fihan pe lootọ ni atọ ko kunju iwọn to.
Oriṣiriṣi nkan si lo le mu ki atọ ọmọkunrin mase di ọmọ. Gẹgẹ bi ileeṣẹ eto ilera orilẹ-ede United Kingdom, NHS ṣe sọ, lara awọn nkan naa ni:
- Ajogunba
- Koropọn ọmọkunrin ti ko sọkalẹ nigba ti ọmọkunrin wa ni ìkókó
- Ti ọpa to gbe atọ ba bajẹ tabi to di pa nitori aisan, ifarapa, tabi ko ma si rara nigba ti wọn bi ọmọkunrin naa
- Aarun bi chlamydia, gonorrhoea, tabi prostatitis
- Ki iṣan to wa lara koropọn tobi ju
- Iṣẹ abẹ si koropọn tabi hernia
- Ti koropọn ba gbona ju boṣe yẹ lọ
- Ọti amuju, siga mimu ati lilo oogun oloro bi igbo ati cocaine
- Ara sisan ju
- Awọn nkan ti o le ṣe lati fun atọ rẹ ni agbara
Bo tilẹ jẹ pe lilọ si ileewosan fun ayẹwo ati itọju to peye ni ọna abayọ gboogi si iṣoro yii, awọn igbesẹ kan wa ti o le ṣe lati ran ara rẹ lọwọ, ko le bọ ninu aisan naa.
1. Nini ibalopọ loore-koore
2. Ti o ba fi kun iye igba ti o n ni ibalopọ le ṣe iranlọwọ fun ọ. Nini ibalopọ lojoojumọ, tabi bi ọjọ mẹẹrin laarin ṣaaju ki obinrin rẹ to o ye ẹyin (ovulation) yoo ran ọ lọwọ lati fun loyun.
3. Yago fun lilo awọn ipara ibalopọ
4. Awọn ipara ti eeyan fi n pa nkan ọmọkunrin tabi oju ara obinrin lati mu ki ibalopọ rọrun, le ṣe akoba fun ipese atọ.
Nitori naa lo se ṣe pataki lati ba dokita rẹ sọrọ, ki o le mọ eyi to yẹ lati lo.
Awọn nkan ti o le ṣe lati dena atọ ti ko lagbara tabi le di ọmọ
Siga/igbo mimu:
Mimu adinku ba siga ati ọti mimu naa ni ipa pataki to n ko ninu ilera atọ ọkunrin.
Idi ni pe ọti amuju ati siga ma n ṣe idiwọ fun bi atọ yoo ṣe pọ to o, ati bi yoo ṣe yára lati kọlu ẹyin obinrin
Ounjẹ ọlọra:
Iwadii kan ti iwe atigba-degba Human Reproduction Journal, ni orilẹ-ede United Kingdom gbe jade ni ọdun 2012 fihan pe, jijẹ awọn ounjẹ to kun fun ọra ma n din agbara atọ ọkunrin ku.
Bakan naa ni aito eroja Omega-3 fatty acids ninu ara naa ma n ṣe akoba fun un.
Ere idaraya ati oorun sisun:
Yatọ si pe ere idaraya ati oorun sisun dara fun ilera ara, ṣiṣe ere idaraya ma n fun eroja testosterone ni agbara, eyi to ma n mu ki irinajo ọmọbibi rọrun.
Ọpọlọpọ iwadii ijinlẹ fihan pe ọkunrin to ba sanra ju boṣe yẹ lọ, wa ninu ewu pe ki atọ rẹ ma le di ọmọ.
Wahala aṣeju tabi ipaya:
Ṣiṣe wahala lai fun ara ni isinmi le din ifẹ rẹ si ibalopọ ku, eyi to le ni ipa ti ko dara lara irinajo ọmọ bibi.
Idi ni pe ti o ba rẹ ara, o ma n tọju iwọnba okun to ni lati fun ara ni alaafia, kii si pese okun miran ni asiko yii.
Okun inu si ṣe pataki fun ibalopọ. Nitori naa, ẹni to ba n wa ọmọ nilo lati din wahala ati ipaya ku.
Iwẹ pẹlu omi gbigbona:
Wiwẹ iwẹ faaji sauna, jacizzi, ati bẹẹ bẹẹ lọ ni gbogbo igba ma n ṣe akoba fun irinajo ọmọ bibi. Awọn nkan yii tabi wiwọ ṣokoto penpe (boxers) to fún ma n fa ooru. Ooru si ma n ba atọ ọkunrin jẹ.
Eroja Zinc:
Eroja Zinc jẹ pataki ninu ara. Ninu awọn ounjẹ bi ẹran, ẹja, ẹyin si lo wa. Eroja yii ma n ṣe iranlọwọ fun ilera atọ ọkunrin, to fi mọ bo ṣe le di ọmọ.
Lilo afikun eroja Zinc (supplement) le mu ki eroja testosterone pọ si ninu ara awọn ti atọ wọn ba kere.

















