Male Contraceptives: Ó ṣeéṣe káwọn ọkùnrin náà ní oogùn ìfètòsọ́mọbíbí tiwọn láàrín oṣù mẹ́fa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ṣeeṣe ki ogun ifetosọmọbibi akọkọ jade fun awọn ọkunrin lagbaye nigba ti a o ba fi ri oṣu mẹfa si asiko yii.
Ikede yii n waye lẹyin tawọn onimọ iṣegun oyinbo lorilẹ-ede India ni ayẹwo ti pari lori rẹ, o si fihan pe o yege.
Ogun ifetosọmọbibi naa ni wọn ni yoo maa ṣiṣẹ lara ọkunrin yoowu to ba lo o fun ọdun mẹtala ki o to bajẹ, wọn si ti mu u lọ sọdọ oluyẹwo agba fun oogun lorilẹ-ede India fun ifọwọsi.
- Andrew Haruna: So-bàtà tó di ọ̀jọ̀gbọ́n fásitì tó tún jẹ́ ọ̀gá àgbà pátá (V.C.)
- Ìtọ́jú ara di ìrọ̀rùn! Wo orúkọ àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ ní èdé Yorùbá
- Ó gbẹnután! Ìyá dú ọmọ rẹ̀, o yíi láta, ó sì tún jòkó jẹ ẹ́
- Èèyàn 2,040 làwọn agbésùnmọ̀mí ti pa ní Nàìjíríà lọ́dún yìí- Ìwádìí
- Kìnìhún nìkan kọ́ ló burú, àwọn ajá mẹ́wàá yìí náà kò fararọ!
Dokita RS Sharma to jẹ agba ọjẹ onimọ Sayẹnsi ni ileeṣẹ iwadii ijinlẹ lorilẹ-ede India ṣalaye ninu iwe iroyin abẹle kan lorilẹ-ede India ni kikun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni bayii, wọn ni ayẹwo oogun ifetosọmọbibi fun awọn ọkunrin naa ti la ipele kẹta ayẹwo oogun oyinbo kọja nibi ti aṣeyọri oogun yii ti ko ida mẹtadinlọgọrun un ninu ọgọrun un (97.3%).

Oríṣun àwòrán, Science Photo library
Abẹrẹ ni oogun naa n gba wọ inu ile aatọ ọmọkunrin to wa nitosi koropọn ọmọ ọkunrin.
Bi wọn ba buwọlu oogun yii, yoo jẹ oogun ifetosọmọbi akọkọ fawọn ọkunrin lagbaye.
Amọṣa, pẹlu awọn ayẹwo ọlọkan-o-jọkan to n la kọja, ko daju pe yoo lee wa fun lilo ṣiwaju oṣu mẹfa si akoko yii.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ki ọkunrin wọ rọba idaabobo tabi ko yọ nkan ọmọkunrin rẹ ṣaaju ko to da atọ sile ọmọ obinrin ni ọna ifetosọmọbibi ti ọkunrin ti n lo tẹlẹ













