Kano Emirs: Ilé ẹjọ́ wọ́gilé ìyànsípò àwọn Emir mẹ́rin tí Ganduje yan

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba ipinlẹ Kano ti fagile idajọ ile ejọ giga to sọ wi pe Gomina ipinlẹ naa ko laṣẹ lati yan Emir tuntun ni ipinlẹ naa.
Eyi ko ṣẹyin idajọ ile ẹjọ to fagilẹ iyansipo awọn Emir tuntun mẹrin miran, ati wi pe ijọba ipinlẹ naa ko tẹle ọfin ipinlẹ naa ki wọn to yan Emir tuntun.
Ninu atẹjade ti Kọmisọnna fun ọrọ iroyin Muhammad Garba buwọlu ni wọn ti gbe ọrọ yii jade.
Garba ni awọn kọ idajọ ile ẹjọ, ati wi pe awọn Emir tuntun mẹrin naa duro gẹgẹ bi ọba ọlọla bii Emir Sanusi.
Ni ibẹrẹ ọdun yii ni Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje da Emirate tuntun mẹrin si agbegbe Bichi, Karaye, Gaya ati Rano pẹlu Emir tuntun wọn.

Bó ṣe ń wáyé ní Oyo, ló tún ń ṣẹlẹ̀ ní Kano, ilé ẹjọ́ júwe ilé fún Emir mẹ́rin tí Ganduje yan
Bo ṣe wa ni liki lo wa ni gbanja lọrọ bi ile ẹjọ nilu Kano ṣe wọgile iyansipo awọn ọba ti Gomina Ganduje yan sipo.
Bi a ko ba gbagbe, laipẹ yi ni irufẹ idajọ bẹẹ waye nilu Ibadan, ti ile ẹjọ gba awọn ọba ti Gomina ana nipinlẹ Ọyọ, Abiola Ajimobi yan sipo nilu Ibadan.
Nilu Kano, igbimọ lọbalọba ipinlẹ naa lo yan awọn ọba mẹrin tuntun yii sipo.
Adajọ Usman Na'abba to lewaju awọn adajọ to gbe idajọ naa kalẹ, fidi ọrọ mulẹ pe wọn ko tẹle iyana to tọ pẹlu iyansipo awọn ọba naa.
Losu Karun ọdun 2019 ni Gomina Abdullahi Ganduje ipinlẹ Kano buwọlu abadofin kan, to faaye gba iyansipo awọn ọba onipo kinni fawọn agbegbe mẹrin nilu ọhun.

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn agbegbe naa ni Rano, Gaya, Karaya ati Bichiin
Igbesẹ yii ti Gomina Ganduje gbe, lawọn eeyan kan woye o wa lati fi ge iyẹ Emir Sanusi Lamido, to si mu ariwisi ọtọọtọ wa nigba naa.
Yatọ si iyansipo awọn Ọba tuntun wọnyii, Gomina Ganduje buwọlu iwe to ni ki Emir Sanusi Lamido fi ipo rẹ silẹ, lẹyin ti igbimọ lọbalọba ṣe iwaadi lori ẹsun ajẹbanu ti wọn fi kan-an.
Iyansipo awọn Ọba yii ko dun mọ awọn afọbajẹ ninu, ti wọn si gba agbẹjọro lati tako iyansipo awọn ọba wọn yii nile ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, Alamy
Abalọ ababọ nile ẹjọ, lo pada wa ja si idajọ to waye to wọgile iyansipo awọn ọba naa.
Awọn Ọba tuntun ti ile ẹjọ paṣẹ pe ki wọn wọgile iyansipo wọn ni Emir Aminu Ado Bayero to jẹ Emir agbegbe Bichi, Ibrahim Abubakar to jẹ Emir agbegbe Karaye; Tafida Abubakar Ila tii se Emir agbegbe Rano ati Ibrahim Abdulkadir to jẹ Emir agbegbe Gaya.

Oríṣun àwòrán, Other
Ile ẹjọ ni ile aṣofin tapa si ofin yiyan ọba nipinlẹ Kano eyi to lodi sofin.














