Pneumonia: Dókítà ní kòkòrò àìfojúrí ló ń fàá òtútù àyà
Ọpọ asọdun lo maa n waye nipa aisan kan ta n pe ni otutu aya eyi ti oloyinbo n pe ni Pneumonia.
Koda, aisan yii wọpọ ni Naijiria, paapa laarin awọn ọmọde, ti ajọ Unicef si ti kede pe orilẹede Naijiria wa lara awọn ti aisan naa ti wọpọ lagbaye.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Onisegun oyinbo kan, Dokita Afeez Oladele ni aisan otutu aya ko ni ohunkohun se pẹlu otutu rara nitori eeyan lee sun si ori ilẹ lasan tabi si aya si ẹrọ amuletutu lai wọ asọ, ti onitọun ko si ni ni otutu aya rara.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn ti Ààrẹ Tinubu fẹ́ yàn sípò Mínísítà
- Àwọn iròyin ẹlẹ́jẹ̀ márùn ún tó fẹ́ẹ̀ tú Nàìjíríà ká
- Bó ṣe ń wáyé ní Oyo, ló tún ń ṣẹlẹ̀ ní Kano, ilé ẹjọ́ júwe ilé fún Emir mẹ́rin tí Ganduje yan
- Ẹ wo àwọn ọ̀dọ́mọdé Naijiria tó ń ṣe bẹbẹ nínú isẹ́ aládaní nílé
- Mọ̀ síi nípa ewu tó rọ̀ mọ́ níní ìbálòpọ̀ lásìkò ìlóyún lórí ètò Sé lóòtọ́ ní BBC
- Èwo nínú àwọn amóhùnmáwòrán yìí lẹ rántí?
O ni awọn kokoro kan ti a ko lee fi oju ri lo n fa aisan naa, ti a si lee ko awọn kokoro kekeke naa latinu afẹfẹ buruku, eefin, eedu, tabi ka lo ife ati ifọyin ẹni to ba ni aisan naa.
O wa gba awọn obi nimọran lati maa tete gbe awọn ọmọde ti wọn ba kẹẹfin pe o n hu ikọ lọ sile iwosan fun itọju, ki aisan naa to bọwọ sori.