Iyalode Ibadan: Olubadan jáwé oyè lé Ìyálóde tuntun lórí

Laduntan Oyekanmi, ìyálóde tuntun fún ilẹ̀ Ibadan

Oríṣun àwòrán, Olubadan Palace

Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, Aje Ogungunniso ti jawe oye fun Iyalode tuntun fun ilẹ Ibadan, Agba oye Theresa Laduntan Oyekanmi.

Ayẹyẹ iwuye naa to wa ni aafin Olubadan lọjọ Ẹti lo waye lẹyin ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde fọwọsi igbega iyalode tuntun fun ilẹ Ibadan naa.

Oloye Oyekanmi yii si lo di Iyalode ilẹ Ibadan Kẹrinla, to si ni igbega si ipo naa lẹyin ti Alhaja Aminat Abiọdun, tii se Iyalode ilẹ Ibadan Kẹtala papoda lọdun to kọja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oloye Laduntan Oyekanmi, tii se ẹni ọ̀dun mẹrindinlaadọrun, nii se ọmọbibi agboole Ladapọ ladugbo Abẹbi ati agboole Balogun Ibikunle ladugbo Ayẹyẹ nilu Ibadan.

Akọsẹmọsẹ olutọju alaisan ni Iyalode tuntun yii to si kẹkọ gboye nilẹ Gẹẹsi lọdun 1960, o si se igbeyawo pẹlu Amofin Diti Oyekanmi to wa lati agboole Matanmi nilu Osogbo lọdun 1961.

Laduntan Oyekanmi, ìyálóde tuntun fún ilẹ̀ Ibadan ati Olubadan

Oríṣun àwòrán, Olubadan Palace

Iyalode Ilẹ Ibadan tuntun yii fẹyinti gẹgẹ bii Nọọsi nile iwosan Oritamẹfa (UCH) nilu Ibadan.

BBC wa gbadura pe igba Oloye Laduntan Oyekanmi gẹgẹ bii Iyalode tuntun fun ilẹ Ibadan yoo tu gbogbo olugbe Ibadan lara.