Kano: Ọkùnrin mẹrin wọ gàù 'torí ìgbéyàwó orí Facebook

Awọn ọlọpaa ẹsin

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ni kia ti iroyin naa jade ni awọn ọlọpaa sharia ti n wa Sanusi Abdullahi

Awọn ọkunrin mẹẹrin ti 'wọ wahala' nilu Kano nitori pe wọn ṣe ayederu eto igbeyawo lori opo ibaraẹnidọrẹ Facebook.

Awọn to fi ẹsun kan wọn sọ pe ihuwasi wọn tako ẹsin Islam.

Ọkọ iyawo ọhun, Sanusi Abdullahi, jẹwọ pe 'awada' ni oun fi ba ọrẹ oun kan lori Facebook sọrọ pe oun yoo san owo ori rẹ pẹlu Dọla mẹrinlelaadọta lasiko 'eto igbeyawo ori ayelujara' naa.

Awọn olori ẹsin sọ pe yiyẹpẹrẹ eto igbeyawo ni ihuwasi wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ipinlẹ Kano jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ mejila ni ẹkùn Ariwa Naijiria to n lo ofin ẹsin Islam, ti a tun mọ si Sharia. Awọn ọlọpaa ẹsìn si maa n mojuto bi awọn eniyan ṣe n pa awọn ofin yii mọ si.

Ọgbẹni Abdullahi sọ fun BBC pe awada ni ọrọ ti oun ati obinrin naa jọ sọ nipa igbeyawo lori Facebook.

Lori Facebook yii kan naa ni ọkan lara awọn ọrẹ ọkunrin naa lori Facebook ti ṣe bi baba to fi iyawo fun ọkọ, awọn ọrẹ wọn meji to ku si ṣe 'ẹlẹri' igbeyawo naa.

Àkọlé fídíò, Badagry ní ogún àjogúnbá tó pọ̀ yàtọ̀ sí òwò ẹrú

Ọrọ yii sare tan kaakiri ori Facebook, eyi to mu ki awọn olori ẹsin o bu ẹnu ẹtẹ lu u, ti wọn si n kede pe ki wọn fi ofin mu wọn.

Gbaju-gbaja olori ẹsin Islam nilu Kano, Sheik Nazifi Inuwa sọ fun BBC pe iṣẹlẹ naa ko ba ẹsin Islam mu.

'Ninu ẹsin Islam, awọn ọmọbinrin to jẹ onirinkurin tabi oniṣekuṣe lo maa n fi ara wọn fun ọkọ lai jẹ pe awọn obi tabi alagbatọ wọn fi ọwọ si i. Nkan ti Sanusi ati awọn ọrẹ rẹ ṣe jẹ iwa yẹyẹ'... a ki i ṣe igbeyawo bẹ ẹ ninu ẹsin Islam.''

Àkọlé fídíò, Fulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀

Abdullahi ati awọn ọrẹ rẹ ti ṣa asala fun ẹmi wsn bayii lẹyin ti awọn kan bẹrẹ si ni i fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si wọn lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ pe awọn yoo pa wọn.

Ẹni kan ṣe ikọlu si i lọjọ Aje; iṣẹlẹ naa lo si mu ki oun ati awọn ọrẹ rẹ o jade nibi ti wọn fi ara pamọ si, ti wọn si fi ẹjọ sun awọn ọlọpaa ẹsin (Hisbah).

Wọn si ti tọrọ aforiji fun igbesẹ wọn.

Àkọlé fídíò, 'Á rọ̀ wá lọ́rún tí wọ́n bá lè ṣí ibodè Lekki lọ̀fẹ̀ẹ́ láàrọ̀'

Olori Hisbah ni Kano, Abaa Sufi sọ fun BBC pe oun ti gba ẹbẹ awọn ọkunrin naa, oun si ti kilọ fun wọn ki wọn o ma ṣe bẹ ẹ mọ.

Ipinlẹ Borno ni obinrin ti ọrọ kan n gbe, wọn si ti ba oun naa wi. Ṣugbọn, ọrẹkunrin rẹ gan n gan ni iroyin sọ pe o ti fi silẹ bayi nitori iṣẹlẹ naa.