Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kwara Poly, agbófinró àti àjọ NYSC kojú ara wọn nítorí ibùgbé

Awọn akẹkọọ ninu ọgba Kwara Poly
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn akẹkọọ ile ẹkọ Gbogbonise ipinlẹ Kwara ti a mọ si 'Kwara Poly' ti ke si ijọba ipinlẹ Kwara lati da owo yara ti wọn n gbe nile ẹkọ naa (hostel) ti wọn san pada.

Ọrọ yii ko sẹyin bi ajọ Agunbanirọ, NYSC, ṣe ti fi ile ẹkọ naa se ibudo Agunbanirọ ti wọn si n lo si awọn yara to jẹ ti awọn akẹkọọ naa.

Tẹ o ba gbagbe, lọdun to kọja ni ijọba Kwara gbe ibudo awọn Agunbanirọ yii wa si ile ẹkọ naa lati ilu Yikpata, ni ijọba ibilẹ Patigi, nitori aabo..

Lati igba naa ni ajọ Agunbanirọ, ẹka ti ipinlẹ Kwara ti n lo ile ẹkọ naa gẹgẹ bii ibudọ igbaradi fun awọn Agunbanirọ tuntun, ki wọn too pin wọn si awọn ibi isẹ ọtọọtọ wọn.

Ṣugbọn Iogunjọ osu Kin-in-ni ọdun 2026 yii ni iroyin gbode, pe awọn akẹkọọ Kwara Poly ti ilẹkun abawọle ti wọn o si jẹ kawọn olukọ, awọn Agunbanirọ tuntun to fi mọ awọn ọga wọn wole sinu ọgba.

Nigba to si di Ọjọruu ti i ṣe ọjọ keji igbesẹ awọn akẹkọọ yii, iroyin gbode pe ijọba ti ti Kwara Poly pa fun igba diẹ.

Àlàyé àwọn akẹ́kọ̀ọ́

Aarẹ ẹgbẹ akẹkọọ Kwara, (NAKSS), Ahmad Ishowo Abdulkabir
Àkọlé àwòrán, Aarẹ ẹgbẹ akẹkọọ Kwara, (NAKSS), Ahmad Ishowo Abdulkabir

Nigba to n ba BBC NEWS Yoruba sọrọ, Aarẹ awọn akẹkọọ ipinlẹ Kwara (National Association of Kwara State Students) (NAKSS), Ahmad Ishowo Abdulkabir, sọ pe ki ijọba da owo yara tawọn san pada, nitori awọn ko ri i lo, awọn ko si rowo gba ile sita.

Abdulkabir ni awọn o ti mura fun ohun ti ijọba gbe ka awọn laya yii, nitori ọsẹ meji akọkọ ni ijọba beere fun, awọn ko mọ pe wọn yoo maa lo o lọ ni.

Ishowo sọ pe:

"Ni bii osu mẹta sẹyin ni mo gba ipe, pe awọn Agunbanirọ fẹ wa lo ile ẹkọ wa fun ọsẹ meji, apa ibi ti wọn si fẹ lo si ni ofiisi NAKSS wa.

"A sọ pe ko si wahala, ka ni a mọ pe yoo ju bẹẹ lọ ni, a o ba ti beere fun nnkan ti a fẹ.

"Wọn lo o nigba yẹn, wọn si lọ, o tun di osu to kọja ti awọn akẹkọọ ti wọle, wọn tun de.

"Apa ibi ti wọn si n lo yii ni awọn yara awọn akẹkọọ ọkunrin.

A lọ parọwa sawọn akẹkọọ yii, a si ko wọn pọ mọ awọn akẹkọọ obinrin ni yara igbe tiwọn.

"Ẹ si mọ pe ko si bi a ṣe maa da ọkunrin ati obinrin pọ ti awọn nnkan kan ko ni i maa sẹlẹ."

Aarẹ NAKSS to ṣalaye yii sọ pe idi ti awon ṣe n beere ẹtọ awọn niyẹn.

''Kwara Poly ló kọ̀wé sí NYSC pé ki wọn maa pada bọ''

Aworan akede agọ Agunbanirọ ni Kwara
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni itẹsiwaju Aarẹ NAKSS, o ni awọn alaṣẹ Kwara Poly lo kọwe si ajọ Agunbanirọ pe ki wọn maa pada bọ, lẹyin ti wọn ti paṣẹ pe gbogbo akẹkọọ lo gbọdọ maa gbe ninu ọgba, paapaa awọn to wa ni ipele kin-in-ni. (ND 1).

"Awọn yara ti wọn kan nipa fawọn ọmọ ti wọn si ti sanwo rẹ ni wọn ko tun jẹ ki wọn wọ.

" Iyẹn la ṣe sọ pe kijọba dawo awọn akẹkọọ pada, ki wọn le rowo gbale sita.

"Ishowo tẹsiwaju pe niṣe ni ijọba ni awọn fun awọn akẹkọọ ni isinmi ọsẹ mẹta, leyi to jẹ pe idanwo yoo ku ọjọ meji nigba ti awọn yoo ba fi wọle pada.

"Bawo la ṣe fẹ kẹkọọ, bẹẹ si ni kalenda wa ko see yi pada.

"Awọn ọmọ waa n sun kaakiri ita ati awọn yara ikawe pẹlu awọn ẹru wọn.

"Ọrọ tiwa ko wa jọ ijọba loju, nitori wọn fẹ ko awọn Agunbanirọ wọle. Eyi lo fa a ti a fi ni ẹni kankan ko tiẹ ni i wọnu ọgba.

"Tori eyi la ṣe ti geeti pa, a si duro si bẹ fun wakati mẹta."

Aarẹ NAKSS ni lẹyin naa ni awọn alaṣẹ ọgba naa lọ ko awọn sọja, ọlọpaa atawọn ologun mi-in wa.

Wọn fi "Amour Tank" ja geeti, wọn si bẹrẹ si i yin taju-taju si gbogbo awọn akẹkọọ ti wọn ri.

"Koda, wọn lọ ba awọn akẹkọọ to wa ninu yara, wọn si fi taju-taju le wọn jade.

Lẹyin iṣẹlẹ naa, Aarẹ NAKSS sọ pe awọn akẹkọọ to farapa le ni ọgọrun-un (100), o ni wọn n gba itọju nileewosan.

Ki ni àjọ NYSC sọ?

BBC kan si adari agba fún NYSC ni Kwara, Onifade Olaoluwa Joshua, lati gbọ tẹnu rẹ.

Onifade sọ pe ọwọ ijọba Kwara ati ile ẹkọ Kwara Poly ni ọrọ wa.

O fi kun un pe Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulramon Abdulrazak lo dari awọn wa si Kwara Poly, oun nikan naa lo si le sọ igba ti awọn yoo kuro nibẹ.

Adari NYSC ni Kwara naa sọ pe awọn o ni wahala kankan pẹlu awọn akẹkọọ Kwara Poly, o ni awọn akẹkọọ ati awọn alasẹ ile ẹkọ wọn ni ẹlẹjọ.

Ǹjẹ́ awọn aláṣẹ Kwara Poly mọ̀ sí rògbòdìyàn yìí?

BBC News Yoruba tun gbera lọ si ofiisi ọga agba ile ẹkọ Kwara Poly, Jimoh Abdul, sugbọn a ko ba a nibẹ.

A pe e lori aago lọpọ igba sugbọn ko gbe ipe naa.

A tun kan si Alukoro ile ẹkọ naa, Arabinrin Ummuh Abdullah, sugbọn ọun naa ko gbe ipe wa.