Fásitì Ibadan: Kò sí àkẹ́kọ̀ọ́ obìnrin tí wọ́n fipá bá lòpọ̀

Awọn akẹkọ fasiti Ibadan

Oríṣun àwòrán, University of Ibadan

Eemọ nla lo wọ ileekọ fasiti Ibadan mọjumọ ọjọ Ẹti nigba ti awọn adigunjale to to mẹwa niye ba ibugbe awọn obinrin, Obafemi Awolowo, to wa ninu ọgba ileekọ naa lalejo.

Niwọn igba to jẹ pe ole kii wa, bikose lati jale, lati pa ati lati parun, awọn adigunjale yii se akẹkọ meji lese, ko to di pe wọn na papa bora.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori isẹlẹ yii, osisẹ alarina fun ileekọ fasiti Ibadan, Ọgbẹni Tunji Ọladẹjọ fi idi isẹlẹ naa mulẹ pẹlu afikun pe awọn adigunjale naa gba ọpọ ẹrọ ilewọ alagbeka lọwọ awọn akẹkọbinrin naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọladẹjọ salaye pe, irọ to jinna sootọ ni ahesọ ti awọn eeyan kan n gbe kiri pe awọn adigunjale naa fi tipa awọn awọn akẹkọbinrin ọhun lo pọ.

Osisẹ alarina fun ọgba fasiti Ibadan ni ni kete ti iroyin kan awọn osisẹ alaabo to wa lọgba ileeẹkọ naa, ni wọn ti ta mọra, ti wọn si kesi awọn ọlspa lati wa kun wọn lọwọ.

Awọn akẹkọ fasiti Ibadan

Oríṣun àwòrán, Olamide

O fikun pe, ni kete ti awọn ọlọpa naa de pẹlu ọga agba ọlọpa to n dari agọ ọlọpa to wa ni Sango nilu Ibadan, ni awọn adigunjale ọhun fẹsẹ fẹ.

Ilegbe awọn akẹkọ kan ni fasiti Ibadan

Oríṣun àwòrán, University of Ibadan

Ọladẹjọ wa mu da awọn akẹkọ to wa lọgba fasiti Ibadan, awọn obi wọn ati gbogbo awujọ lapapọ pe, ko si ewu kankan loko nipa eto aabo ile ẹkọ naa, nitori awọn alasẹ ileekọ ọhun ti setan lati mu agbega ba eto aabo rẹ, ki iru isẹlẹ yii ma baa waye mọ.