Babcock Sex Video: Ọ̀pọ̀ èèyàn ní kò yẹ kí wọn lé akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ọ̀hún torí kìí ṣe ọmọdé

Oríṣun àwòrán, Babcock University
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n tako igbesẹ fasiti Babcock lori bo se juwe ọna ile fun akẹkọbinrin kan ti wọn n ba lopọ ninu fidio kan to lu ori ayelujara pa.
Bẹẹ ba gbagbe, ni Ọjọru ni fidio kan gba oju opo ikansira ẹni Twitter eyi to n se afihan ọmọbinrin kan ti ọkunrin kan n ba lopọ, ti oju ọmọbinrin naa si han sita fun araye ri.
Lẹyin eyi ni ileekọ fasiti Babcock fi atẹjade kan sita pe akẹkọ ileewe naa ni ọmọbinrin ti wọn n ba lopọ ninu fidio naa, to si jẹ akẹkọ ọlọdun kẹta ni ẹka ẹkọ nipa imọ isiro owo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn iròyin ẹlẹ́jẹ̀ márùn ún tó fẹ́ẹ̀ tú Nàìjíríà ká
- Bó ṣe ń wáyé ní Oyo, ló tún ń ṣẹlẹ̀ ní Kano, ilé ẹjọ́ júwe ilé fún Emir mẹ́rin tí Ganduje yan
- Ẹ wo àwọn ọ̀dọ́mọdé Naijiria tó ń ṣe bẹbẹ nínú isẹ́ aládaní nílé
- Àwọn agbébọn kọlu Kọmísánà fọ́rọ̀ ilẹ̀ àti ilégbèé ní Ọyọ, awakọ̀ dèrò ọ̀run
- Èwo nínú àwọn amóhùnmáwòrán yìí lẹ rántí?
Bakan naa lo fikun pe ọmọkunrin to n ba obinrin naa sun ni fasiti ọhun ti le lori ẹsun oogun oloro, to si tun fikun pe oun ti juwe ọna ile fun akẹkọbinrin ti wọn n ba lopọ naa nitori idojuti to ko ba ile ẹkọ ọhun.

Oríṣun àwòrán, Babcock University
Atẹjade naa fikun pe kii se inu ọgba fasiti naa ni awọn mejeeji ti n se asemase naa to waye losu kẹrin ọdun 2019, bikose ile iwosan St Bridget to wa nilu Abeokuta nibiti ọmọkunrin naa ti n gba itọju lọwọ.
Nigba to n sọ ero rẹ lori igbesẹ fasiti Babcock naa, @Official_ubeets ni niwọn igba ti a ko ri ihooho eyikeyi ninu awọn akẹkọ naa, ti Jesu funra rẹ si sọ pe ẹni ti ko ba da ẹsẹ ri, ni ko kọkọ sọ okuta lu obinrin oni pansaga kan, ko yẹ ki wọn le akẹkọbinrin naa, ti ọga ileekọ fasiti Babcock ko ba si da ẹsẹ ri, ko jade sita.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
@Cherrydoc_urch O n kesi awọn eeyan kan lati gbe igbesẹ lori bi fasiti Babcock se le akẹkọbinrin naa. O ni ọmọbinrin naa nilo igbimọ alagbara ti yoo ja fun lati pada sile ẹkọ rẹ nitori ko nilo lati se alaye kankan fun ileewe rẹ lori bi fidio naa se jẹ. Ẹ dakun, ẹ ran lọwọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Lero tiẹ, @lovedaisy04 naa ni ko yẹ bi fasiti babcock se le akẹkọbinrin naa niwọn igba ti kii se inu ọgba ileewe ọhun ni wọn ti n ba ara wọn lo pọ, obinrin naa si ni ẹts si ibalopọ to ba wu nitori kii se ọmọde rara. O ni o yẹ ka dẹkun iwa lile akẹkọ kuro nile iwe lọna aitọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
@anyasi_emma n tiẹ ni kii se lile akẹkọbinrin naa kuro nile iwe lo kan, ohun si ri asọdun lori ohun to n sẹlẹ yii nitori awọn ibeere kan wa to yẹ ki fasiti Babcock kọkọ wa idahun si.
Akọkọ ni pe ta lo ju fidio naa sita to fi de oju opo Twitter, ati pe nitori ki lo mu ko se bẹẹ, awọn eeyan wo si lo n ba pin fọnran aworan naa kiri?
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
@Zolonye, oun ni ọmọbinrin naa nilo ifẹ ati atilẹyin awọn eeyan lasiko yii ju ki wọn maa bu lọ tabi ki ileewe rẹ le kuro.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5