Ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mánigbàgbé tó lágbára jù lágbo eré bọ́ọ̀lù Africa

Naijiria ati Cameroon nibi aṣekagba idije Afcon ọdun 2000

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Cameroon ti fẹyin Naijiria nalẹ lẹmẹẹta nibi idije Afcon wins (1984, 1988, 2000).
    • Author, Emmanuel Akindubuwa and Isaiah Akinremi
    • Role, BBC Sport Africa, Lagos

Kete ti wọn fọn fere ipari ifẹsẹwọnsẹ nibi ti Cameroon ti fi goolu mẹta ṣagba meji ti Gambia, lo ti di mimọ pe asiko to fun ifẹsẹwọnsẹ manigbagbe mii lagbo ere bọọlu Africa.

Naijiria ati alamuleti wọn Cameroon wa lara awọn eekan ere bọọlu ni Africa ti wọn si fakọyọ laaye ara wọn.

Laarin awọn mejeeji, a ri ami ẹyẹ goolu meji nibi ere bọọ́lu Olympics ati ami ẹyẹ Afcon mẹjọ.

Mutiu Adepoju,gbajugbaja agbabọọlu Naijiria tẹlẹ ri sọ fun BBC pe ''nipa itan ati ifigagbaga, ko si ifẹsẹwọnsẹ to lamilaaka to ti Naijiria ati Cameroon.''

''Cameroon ti gbegi dina aṣeyọri Naijiria ni aṣekagbagba idije yii nigba mẹta ọtọọtọ, ko si orileede mii to le fọwọ sọya iru rẹ ni Africa''

Ifẹsẹwọnsẹ naa ti yoo waye ni papa isere Stade Felix Houphouet-Boigny ni Abidjan yoo dabi iru eleyi to waye ni ọdun 1984 nibi tawọn eekan ere bọọlu Cameroon bii Roger Milla,Joseph-Antoine Bell ati Theophile Abega ti gbewuro soju ikọ Naijiria ti Stephen Keshi lewaju wọn pẹlu goolu 3-1.

Ifidirẹmi mii tun waye fun Naijiria lọdun 1988 ni Afcon to waye ni Morocco nibi ti goolu kan lati ọwọ balogun ikọ Cameroon Emmanuel Kunde ti dẹkun pa Naijiria nipasẹ pẹnariti.

Ifẹsẹwọnsẹ to kan ni eleyi ti awọn mejeeji ti pade ni ilu Eko lọdun 2002.

Nibi aṣekagba idije naa ti Naijiria ati Cameroon jijọ ṣagbatẹru rẹ, Cameroon naa lo tun fagba han Naijiria.

Ifidirẹmi yii niwaju awọn alatilẹyin wọn dabi ẹni pe o sọ Cameroon di igi wọrọkọ to n dana ru fun Naijiria.

Ogoji ọdun ti kọja, ta ni yoo jawe olubori ni Afcon 2023

Aworan Victor Osimhen ati Andre Onana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Nigeria fi agba han Cameroon pẹlu goolu 3-2 nibi ipade to waye kẹyin ni Egypt
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igbẹsan idanu ati ifigagbaja ni yoo gbode nigba ti Naijiria ba koju ara wọn ni abala komẹsẹoyọ .

Igba ikẹẹdọgbọn ree ti awọn mejeeji yoo koju ara wọn ninu gbogbo idije ti yoo si jẹ igba kẹjọ ti wọn yoo koju nibi idije Afcon.

Naijiria ni yoo dabi pe ọrọ gbe tori igba mejila ni wọn ti fagba han Cameroon ti wọn si jijọ gba ọmi lẹẹmẹjọ.

Amọ ṣa lawọn ifẹsẹwọnsẹ to lagbara, Cameroon lo ṣagba ti wọn si ti gba ami ẹyẹ Afcon lẹmẹẹta ọtọọtọ dipo ẹẹmeji ti Naijiria gba a.

Patrick Suffo to jẹ agbagbọọlu Cameroon tẹlẹ sọ fun BBC pe ''Cameroon ati Naijiria jẹ alamuleti, nitori naa wọn ni ifigagbagba to lamilaaka julọ lati ibẹrẹpẹpẹ. Nibi awọn ifẹsẹwọnsẹ to lagbara ni Cameroon ti maa n fakọyọ julọ''

Nkan ko fẹ ṣẹnu re fawọn ikọ mejeeji lati ibẹrẹ idije yi .

Ẹẹkan pere ni Naijiria fi ẹsẹ arawọn gba bọọlu sawọn toun ti pe wọn ko awọn gbajugbaja atamatase bii Victor Osimhen,to jẹ agbabọọlu ọkunrin to fakọyọ julọ ni Africa wa si idije Afcon.

Benedict Akwuegbu agbabọọlu tẹlẹ ri Naijiria sọ pe ''Akọnimọọgba wọn, Peseiro nilo atamataṣe mii ti yoo kun Osimhen niwaju.Goolu yoo wa ti a ba lo ilana 4-4-2 "

Mutiu Adepoju ṣafikun pe ''ko saaye fun aṣiṣe kankan paapa bayii taa n koju ikọ bi Cameroon, gbogbo anfaani to ba tẹwa lọwọ la gbọdọ ṣamulo rẹ nitori wọn le ma pada wa mọ“

Abala komẹsẹoyọ bi ti eyi to fẹ waye yii ni igba ikẹhin ti Naijiria ati Cameroon foju kan ara wọn ni Egypt lọdun 2019.

Nibẹ, agbabọọlu Manchester United tẹlẹ, Odion Ighalo, jẹ goolu meji ninu mẹta ti Naijiria fi fagba han Cameroon to ṣe pe awọn ni wọn dade ife ẹyẹ fun wa sibi idije ọdun naa.

Ki lawọn ololufẹ ere bọọlu n sọ ni ilu Eko?

"Ifẹsẹwọnsẹ to lamilaaka julọ lo jẹ lagbo ere bọọlu Africa.

Aya mi maa n ja nigbakugba ti Naijiria ba koju Cameroon.Mo wo aṣekagba idije ọdun 2000 nigba ti mo ṣi wa lọdọ.Ko tan lọkan mi pe Naijiria fidirẹmi.Mo lero pe Naijiria yoo jawe olubori lọjọ Abamẹta''-Lanre Vigo

Mo wo a'sekagba Afcon ọdun 1984 nibi ti ikọ Naijiria ti fidi rẹmi lọwọ Cameroon. Ikọ wa toni gbona ju ti awọn alatako wa lọ.A kan nilo lati ṣatunṣe ba o ṣe koju wọn ni ka si fọkan si pe a gbọdọ jaweolubori ''-Anthony Adeboye,Akọnimọọgba.

''Bi ogun lo maa n ri o nigbakugba ti Naijiria ba n koju Cameroon.Gbogbo eeyan lo mọ pataki ifẹsẹwọnsẹ yi nibi ti iyi orileede wa ti wa loju ọpọn.A ko le gbagbe awọn ifidirẹmi mẹta yoku to waye sẹyin tori naa bi igba pe a gbọdọ gbẹsan ni eleyi ri'' -Seun Savage, Akọnimọọgba.