Ọ̀dẹ̀ ni àwọn èèyàn tó ń kú nítorí wọn kò rí oúnjẹ jẹ - Minisita

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Minisita ijọba apapọ kan ni ọpọ ti bẹrẹ si ni bu ẹnu atẹlu lẹyin to sapejuwe awọn eeyan ti wọn n ku nitori pe wọn ko ri ounjẹ jẹ gẹgẹ ọdẹ eeyan.

Henry Okello Oryem lo jẹ minisita fun ijọba orilẹede Uganda.

Ni ọdun 2022, o le ẹgbẹrun meji eeyan to padanu ẹmi wọn nitori pe wọn ko ri ounjẹ jẹ ni apa ariwa orilẹede Uganda.

Oryem salaye pe pẹlu bi Uganda se ni ilẹ to se anfaani fun eto ọgbin, o yẹ ki awọn le ma gbin ounjẹ ti wọn yoo jẹ fun ara wọn.

“Ọdẹ eeyan nikan, ọdẹ ponbele lo ma ku nitori ko ri ounjẹ jẹ ni Uganda,” minisita fun ọrọ oke okun sọ fun ileeṣẹ momaworan NTV.

“To ba sisẹ karakara, ilẹ wa ni Uganda. Oju ọjọ dara pupọ ni orilẹede wa. Ti o ba tẹpa mọ isẹ lati jade laarọ, tun ilẹ rẹ ṣe, gbin ounjẹ, to o si se awọn nnkan mi to yẹ ko ṣe, bawo ni o ko se ni ri ounjẹ jẹ?”

Iwadii kan lati ọwọ ajọ Uganda Human Rights Commission salaye pe airi ounjẹ jẹ ni apa ariwa ti sọ eeyan toto idaji milọnu sinu ebi.”

Ọrọ minisita ni o ti fa ọpọ rogbodiyan, ti awọn kan si ti tu tọ soke f'oju gba a.

Moses Aleper, aṣofin ni ile igbimọ aṣofin fun ẹkun ijọba Ckekwii ni apa Karamoja, sọ fun BBC pe ọrọ ti Oryem sọ yii lo ku diẹ kato, to si seni laanu pe o ti ẹnu minisita orilẹede to mọ bi nnkan se ri jade.

“Mo wa lati ẹkun to ni ilẹ ọlọra julọ ni Karamoja, ti ojo si ma n rọ daadaa fun ipese ounjẹ sugbọn ti ojo ko ba rọ nkọ?

“Eyi lo mi ọpọ ma ri ounjẹ jẹ.”

Aleper tun salaye pe bi ebi se n pa awọn eeyan ni agbegbe naa kọja ọju lasan pẹlu bi oju ọjọ se n yipada.

Gbajugbaja akọroyin, Charles Onyango Obbo na kan Oryam ni abuku, o ni minisita kuna lati ri i pe bi ebi se wa ni orilẹede bi Uganda ko sẹyin kudiẹkudiẹ to ba eto ọrọ aje.

Aworan Henry Okello Oryem

Oríṣun àwòrán, AFP