'Mò ń ṣe iṣẹ́ fọga nítorí kí ń má bà má a rìn kiri àdúgbò'

Àkọlé fídíò, Àwọn akẹẹgbẹ́ mi má n fi mí ṣe yẹ̀ẹ̀yẹ́ nítorí iṣẹ́ fọga tí mo n se
'Mò ń ṣe iṣẹ́ fọga nítorí kí ń má bà má a rìn kiri àdúgbò'
Bose Adeleke

Awọn eeyan kan ma n sọ pe ko si iṣẹ ti ọkunrin n ṣe, ti obinrin ko le sẹ.

Bẹẹ gan an ni ọrọ ri fun Ọdọmọbinrin, Adeleke Bose, to yan lati ma a ṣe iṣẹ awọn to n fẹ́ taya ọkọ, iyẹn fọga.

Ni aye ode oni ti ọpọ ọmọ n sa fun iṣẹ kikọ, ni Bose Adeleke ko wo yẹyẹ ti awọn akẹẹgbẹ rẹ fi n ṣe, to si tẹra mọ iṣẹ naa to kọ.

Ninu ọrọ to sọ fun BBC, baba rẹ mu u lọ si idi isẹ afẹtaya, “nitori ko ma ba a ma rin kiri adugbo”.

Bo tilẹ jẹ pe baba Bose lo ni ileeṣẹ naa, baba naa, Ọgbẹni adeleke ni oun kii ṣaba si ni bẹ, to si jẹ pe Bose lo n ṣe isẹ.

Ọdọmọbinrin naa sọ pe ọdun meje sẹyin ni oun ti bẹrẹ iṣẹ fọga. Eyi jẹ asiko to wa ni ipele akọkọ nile ẹkọ girama, JSS 1.

O ni baba oun kii kọkọ gba ki oun ṣiṣẹ ni ibẹrẹ pẹpẹ, nitori o gbagbọ pe iṣẹ ọkunrin ni.

O ni bakan naa ni awọn onibaara naa kii kọkọ fẹ gbe iṣẹ fun oun.

“Amọ ti baba mi ba lọ sibi kan, mo bẹrẹ si ni ṣe e diẹdiẹ titi mo fi mọ.”

Ọmọbinrin naa ṣalaye pe bi oun ṣe darapọ mọ baba oun nidi iṣẹ naa, n mu ki owo to n wọle pọ si.

Eyi ri bẹẹ nitori ọpọ awakọ to ma n gbe iṣẹ wa fun wọn nitori pe Bose jẹ obinrin to n sẹ iṣẹ ọkunrin.

Bakan naa lo ni idunnu awọn onibaara oun lo ma n fun oun ni idunnu.

Ninu ọrọ tiẹ naa, Ọgbẹni Samson Adeleke, to jẹ baba Bose, sọ pe iṣẹ onibaara kankan ko bajẹ ri lọwọ ọmọ naa lati igba to ti n ṣiṣẹ.

O ni ọmọ to n gbọnran ni, to si tun ni itẹriba.

Lootọ ni Bose n ri owo nidi iṣẹ taya fifẹ, o ni eyi ko di oun lọwọ ninu eto ẹkọ.

Bose Adeleke sọ pe imọ nipa amojuto okoowo ni oun n fẹ kọ ni ile ẹkọ giga, ki oun le di oniṣowo.