Adití àti odi ni mí, àmọ́ mo ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ oríṣiríṣi nínú ijó jíjó

Àkọlé fídíò,
Adití àti odi ni mí, àmọ́ mo ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ oríṣiríṣi nínú ijó jíjó
Toluwalase Aleriwon

Wọn bi Toluwalase Aleriwon ni aditi ati odi, ṣugbọn eyi ko di i lọwọ lati lo ẹbun ijojijo to ni.

Ọgbẹni Toluwalase to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun sọ fun BBC pe oun tun ni aburo kan to ni ipenija bi t’oun.

Lati kekere ti Toluwalase ti wa ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ lo ti bẹrẹ ijo, to si gba oriṣiriṣi ami ẹyẹ ati ẹbun nitori bo ṣe tayọ.

Ilu Ilorin nipinlẹ Kwara ni wọn ti bi i, nibẹ si lo ti pada obinrin kan to ma n mu lọ si idije ijo.

Lati ibẹ lo ti pade Ọgbẹni Samuel James, to jẹ olukọ ede awọn aditi ati odi.

Iṣẹ ti oun tun ma n ṣe ni pe o ma n ṣe ipatẹ ijo nibi ti awọn eeyan ti ko gbọrọ ti ma n fi ẹbun wọn ninu ijo jijo han.

Toluwalase kopa nibi eto naa, nibi to gba di ilumọọka aditi onijo.

O sọ pe oun ma n ni imọ lara ilu to wa ninu orin ti oun ba fẹ jo si, nipa fifi ọwọ kan ẹrọ gbohungbohun, speaker.

Amọ ọpọ igba lo ma n ṣe igbaradi ko to o le jo si orin kan.

Ọgbẹni toluwalase Aleriwon sọ pe oun ni ireti lati di ogbontarigi onijo, lati le ṣe iwuri fun awọn akanda ẹda yooku nipasẹ ijo.