Mo ti kú tán, kí áwọn dókìtà tó ó rí ẹ̀mí mi dù padà - Kollington Ayinla

Agba akọrin Fuji, Kolawole Rasaq Ilori, ti ọpọ mọ si Kollington Ayinla, ti kede sita pe aaye ni oun wa o.
Eyi waye lẹyin ti iroyin jade ni opin ọsẹ to kọja pe ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni ẹni ọdun marundinlọgọrin naa wa.
Iroyin naa sọ pe aisan gbẹmigbẹmi lo da agba ọjẹ naa gunlẹ, to si jẹ pe afẹfẹ oxygen lo fi n mi.
A gbọ pe digbadigba ni wọn sare gbe e lọ si ileewosan aladani kan ni agbegbe Alagbado nipinlẹ Eko, ko o di pe wọn dari rẹ si ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo to jẹ ti fasiti ipinlẹ Eko, LASUTH, ni agbegbe Ikeja.
Amọ nigba ti yoo fi di alẹ ọjọ Isẹgun, ara rẹ ti n ya.
Botilẹ jẹ pe ko sọ iru aisan to fẹ ẹ gba ẹmi lẹnu rẹ, awọn iroyin kan ti BBC ko le fidi mulẹ sọ pe aisan itọ ṣuga to ti n ba a finra lati ọjọ pipẹ lo fa sababi.
Ninu fidio kan ti akọwe ikede ati iroyin fun gomina ipinlẹ Eko, Gboyega Akosile, fi sita lori ayelujara, o jọ pe ara Kollington ti n ya.
Ninu fidio naa ni Kollington ti ṣalaye pe ọpẹlọpẹ awọn oṣiṣẹ ileewosan to gbiyanju fun oun, bi bẹẹkọ oun i ba ti jẹ ọlọrun ni pe.
“Gbogbo eeyan ro pe mo ti ku ni, amọ emi naa re e ti mo n sọrọ.
“Mo wa laye lonii nitori atilẹyin Ọlọrun, gomina ipinlẹ Eko, ati awọn oṣiṣẹ ileewosan Lasuth.”
Nnkan to yẹ ki o mọ nipa Kollington Ayinla
Ogunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 1949 ni wọn bi Abdulrasaq Kolawole Ilori 'Kollington Ayinla' niluu Ilota, nipinlẹ Kwara.
Alhaji Kolllington jẹ ọkan gboogi lara awọn to pilẹ orin Fuji ni Naijiria.
Lati nnkan bi ọdun 1962 ni iroyin sọ pe o bẹrẹ si kọ orin.
Bi orin Fuji ṣe n gbajumọ si i, ni ede aiyede n waye laarin oun ati agba olorin miran to ti di oloogbe, Alhaji Sikiru Ayinde Barrister, lori ẹni to jẹ olori Fuji.
Ọpọlọpọ awo orin ni Kollington ti ṣe jade. Lara wọn ni
Ironu Ko Papo
Fuji Ropopo
Fuji '78 Organisation
Oro Idigo
Omo Mi Gbo Temi
Lagos All Routes
Lakukulala
Ogun Onire
Emi Ni Ojo
B'Aoku Ise O Tan
Emi Ni Ojo
Omu Iya Dun
Kollington Ayinla sọ ẹni tó dá orin Fuji sílẹ̀ gan an ní Nàiìjíríà
Ọjọ ti pẹ ti ariyanjiyan ti ma n waye lori ẹni to da orin Fuji kikọ silẹ ni pato, paapaa laarin oun ati sikiru ayinde Barrister.
Eyi jẹ ọkan lara nnkan to n fa orogun owo laarin awọn agba oni Fuji.
Amọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC Yoruba lọdun 2020, Alhaji Kollington Ayinla sọrọ lori bi Fuji ṣe bẹrẹ.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu ileeṣẹ FUJI: A Opera, Kollington gba pe oloogbe Ayinde Barrister lo da ere Fuji silẹ nigba ti oun tẹ le e ninu iṣẹ orin Fuji.
Nibi akanṣe eto naa to waye ni Alliance Francaise de Lagos/The Mike Adenuga Center, Ikoyi, Kollington sọ pe orin Fuji ti kọja bẹẹ lasiko yii.
Kollington ṣalaye pe oun ko lero pe orin Fuji le di gbajugbaja orin bi o ti da lonii.
''Orin gidi ni orin Fuji, o ti kan kaakiri gbogbo agbaaye bayii, gbogbo eeyan ni Naijiria lo fẹ kọ orin Fuji bayii,'' Kollington lo sọ bẹẹ.
Alhaji Kollington fikun ọrọ rẹ pe ijinlẹ ede Yoruba lawọn maa n fi kọ orin Fuji ṣugbọn laye ode oni ''awọn ọmọ wa ti fi ede oyinbo si orin Fuji lati le jẹ ko jẹ itẹwọgba sii kaakiri agbaaye.












