Wọ́n gé orí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ọmọ Kenya, ọlọ́pàá mú afurasí ọmọ Nàìjíríà méjì

Oríṣun àwòrán, AFP
Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Kenya ti mu ọmọ Naijiria meji lori ẹsun iṣekupa akẹkọọ ọmọ kenya kan, Rita Waeni
Ni ọjọ kẹrinla oṣu Kini ọdun 2024 yii ni wọn ri ara Rita ti wọn ti ge wẹlẹwẹlẹ, ninu ọra ikodọtisi ninu ile kan niluu Nairobi.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ko si ori ọmọbinrin, ẹni ogun ọdun mọ lara rẹ, ati pe foonu rẹ atawọn nkan ini rẹ mii naa di awati.
Awọn afurasi meji ọhun lati Naijiria ti farahan nile ẹjọ amọ ile ẹjọ ko tii sọ ohun kan nipa wọn.
Awọn ọlọpaa rọ adajọ majisireeti ko yọnda awọn afurasi naa kawọn le ko wọn si atimọle titi di ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kini yii, adajọ si gba ẹbẹ naa.
Iku Waeni ti mu ki ọpọ eeyan ke pe ijọba lati pese abo to peye fawọn obinrin.
Ẹwẹ, awọn ọmọ Kenya mẹrin mii naa ti wa ni atimọle lori iṣẹlẹ yii bakan naa, nigba tawọn ọlọpaa tun ti mu ẹlomiran to ti n fi iwe igbeluu orilẹede Mozambique rinrin ajo.
Nigba ti o n gbiyanju lati rinrin ajo kuro ni Kenya ni wọn fi ọwọ ofin mu un.
Ileeṣẹ ọlọpaa Kenya ni William Ovie Opia ati Johnbull Asbor ni orukọ awọn afurasi ọmọ Naijiria naa.
Wọn ni ọjọ ti lọ lori iwe igbeluu Ọgbẹni Opia nigba ti Asbor ti padanu iwe igbeluu tiẹ ni bi ọdun meji sẹyin.
Oriṣiiriṣii nkan bi ọbẹ alapata ati aake lawọn ọlọpaa lawọn ba nile awọn mejeeji.
Ileeṣẹ ọlọpaa gbagbọ pe o ṣeeṣe ko jẹ awọn nkan yii ni wọn lo lati ṣekupa Rita to jẹ akẹkọọ ile ẹkọ giga fasiti.
Ọgbẹni Opia ṣalaye pe oun ra aake ti wọn ba nile oun lati maa fi daabo ara oun ni.
Ilu Ndenderu ti ko jina si Nairobi lawọn ọlọpaa ti mu awọn ọmọ Naijiria naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ibi tawọn ti mu awọn mejeeji ko jina si daamu oni kan nibi ti wọn ti ri ori Rita ati foonu rẹ atawọn nkan rẹ mii to di awati.
Ẹbi Rita ko tii lanfani lati ri ori eeyan tawọn ọlọpaa lawọn ri.
Ọsẹ to kọja ni ẹbi ọmọbinrin to doloogbe naa sọ pe awọn to ji i gbe beere ẹgbẹrun mẹta dọla le lọgọrun owo dọla(($3,100) ki awọn to le fi i silẹ.
Bi wọn ṣe pa Rita ti wọn si kun un welewele jẹ kayeefi fun ọpọ eeyan ni Kenya.
Oniruuru ẹgbẹ ajafẹtọọ atawọn ẹgbẹ ajijagbara fawọn obinrin ti pinnu lati ṣe ifẹhonuhan lori iwa ipa sawọn obinrin to n pọ sii.
Iṣekupa awọn obinrin ti pọ sii lorilẹede Kenya lati ibẹrẹ ọdun 2024 yii.















