Gbogbo àsìkò tí mo lò l'ẹ́wọ̀n ni ara fi ni mí- Tani Olohun

Àkọlé fídíò, Ọjọ́ tó bá ku ọ̀la kí n kírun, ni kí àwọn irúnmọlẹ̀ gba ẹ̀mí mi
Gbogbo àsìkò tí mo lò l'ẹ́wọ̀n ni ara fi ni mí- Tani Olohun

Gbajugbaja Oniṣẹṣe nii, Abdulazeez Adegbola Ifatimileyin, ti ọpọ mọ si Tani Olohun ti salaye ohun ti oju rẹ ri nigba to wa ni ahamọ.

Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC, Tani Olohun tu kẹkẹ ọrọ silẹ nipa ọpọ nkan to ṣẹlẹ si lẹyin to foju wina ofin lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti awọn Alfa ati ọmọ bibi ilu Ilorin kan fi kan an.

Laarin igba ti awọn agbofinro kọkọ fi panpẹ mu u ati igba to gba itusilẹ nipasẹ aṣẹ ileẹjọ, Tani Olohun lo ọpọ oṣu lahamọ.

Lati ahamọ yi ni wọn ti n gbe wa si ile ẹjọ lati wa sọ tẹnu rẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC, o salaye pe ko si igba kankan to rọrun ni ahamọ.

O ni ''gbogbo igba ti mo wa nibẹ lo nira.''

Ko si ominira nibi taa wa ni ahamọ

Tani Olohun sọ pe inu yaara kan ni wọn ko bii ọgọrun eeyan si , ojukan naa si ni awọn jijọ n yagbẹ, tawọn si.

O ni ko si iru igbadun tkankan ti wọn ṣeto si ibẹ lati mu aye rọrun fun eeyan.

''Koda ki wọn fun wa ni adiẹ jẹ nibẹẹ, ki o maa fi itan ewurẹ jẹ ọka ni ahamọ, ,ko le dabi pe ki eeyan ni ominira''

'''Ki Olorun ma fi wa si ahamọ.Gbogbo igba ti eeyan ba wa ni ahamọ lo nira''

Aworan Tani Olohun
Nítorí kí n le di Mùsùlùmí kọ́ ni ilé ẹjọ́ fi da ẹjọ́ tí àwọn Alfa pè mí nù - Tani Ọlọrun
Aworan Tani Olorun

Adegbola Ifatimileyin, Tani Ọlọrun, ti ba BBC sọrọ nipa bi ija ṣe pari, ti ile ẹjọ si tu u silẹ lẹyin ti awọn Alfa kan fi ẹsun kan-an.

Ninu ọrọ to ba BBC sọ lo ti sọ pe inu idile Musulumi ni wọn bi oun si, amọ iṣẹẹṣe ni oun yan laayo.

O ṣalaye pe Alhaji ati Alhaja ni awọn obi oun.

Babalawo naa to jẹ ọmọ bibi ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo, di ilumọọka lẹyin ti awọn Alfa niluu Ilorin nipinlẹ Kwara, gbe e lọ sile ẹjọ lori ẹsun pe o ba Alfa nla kan ni orukọ jẹ pẹlu awọn eto to n ṣe lori ayeluajra.

O ni “ọpọ nnkan ti mo ma n sọ, ni awọn eeyan kan ti sọ ṣaaju, ṣugbọn ti wọn o fi bi wọn”.

Arakunrin Ifatimilẹyin sọ pe ọgbọn ni oun kọ lara nnkan to ṣẹlẹ si oun.

Kini idi ti ile ẹjọ fi da ẹjọ ti Alfa pe Tani Ọlọrun, nu?

Ninu ọrọ to sọ fun BBC, Ọgbẹni Tani Ọlọrun sọ pe kii ṣe nitori ki oun di Musulumi ni ile ẹjọ fi wọgile ẹjọ, o ni bi oun ati awọn to fi ẹsun ibanilorukọ jẹ kan oun ṣe yanju ede aiyede wọn labẹle, lo fa igbesẹ ile ẹjọ.

Ṣaaju ni ile ẹjọ fun igun mejeeji ni aaye lati lọ jiroro pọ, ki wọn si yanju ija to wa laarin wọn.

Nibi ipade naa to waye niluu Ilorin, ni Tani Ọlọrun ti bẹ awọn Alfa naa, ti awọn naa si sọ pe ija ti tan.

Ki lo le mu ọmọ Musulumi di oniṣẹẹṣe?

Adegbola Ifatimilẹyin Tani Olorun, sọ fun BBC pe oun ko ja mọ nnkankan ṣaaju ki oun to o di ẹlẹsin abalaye.

O ni nigba ti oun wọ inu iṣẹẹṣe ni ọrọ aye oun ni itumọ, ti gbogbo aye mọ oun, ti awọn kan si tun n fẹ mọ oun si.

O ni ọjọkọjọ ti oun ba pinnu pe oun ko ṣe ẹbọ mọ, ni ki ẹmi oun bọ.

Bakan naa lo ṣalaye pe iya oun , ati iyawo oun ṣi n ṣe ẹsin Islam.

“Emi ni mo pinnu pe, ẹsin awọn baba wa ni ma a pada si.

“Mo si l’agbara lati sọ pe ki iyawo mi naa pada sinu iṣẹẹṣe, amọ mi o l’agbara lori awọn obi mi pe ki wọn ma ṣe ẹsin Islam mọ.”

O ni jibiti ati aṣilo agbara lo mu ki ọpọ̀ eeyan ma a fi ẹnu tẹnbẹlu Iṣẹẹṣe.

Yatọ si eyi, o ni fifi ẹnu ba ẹsin ẹlomiran jẹ, lo n fa ija ẹsin.

Arakunrin Ifatimilẹyin sọ pe ọjọkọjọ ti oun ba kirun, ni ki awọn iraunmọlẹ gba ẹmi oun.

Báwo ni ọ̀rọ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀?

Abdulazeez Adegbola, ti awọn eeyan mọ si Tani Olohun, to jẹ gbajugbaja oniṣẹṣe lori ayelujara, ni awọn ọlọpaa mu nilu Ibadan, ti wọn si gbe lọ si ilu Ilorin labẹ idari kọmiṣọna fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara.

Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni Tani Olorun, ti wọn si fi ẹsun ibanilorukọjẹ ati sisọ ọrọ abuku si Emir ilu Ilorin, Alhaji Ibrahim Sulu-Gambari atawọn aafaa mii ni ipinlẹ naa, pẹlu awọn ẹsun miran.

Gbogbo awọn ẹsun yii, gẹgẹ bii Ademola Banks to jẹ agbẹjọro olujẹjọ naa ṣe wi, ni wọn lee gba oniduro fun nile-ẹjọ amọ inu galo ni Tani Olohun wa lati ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹjọ.