Ọwọ́ tẹ ìmáàmù mọ́ṣáláàṣí pẹ̀lú orí èèyàn àti àwọn nǹkan míì ní Eko

Lagos

Oríṣun àwòrán, NPF

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti gboriyin fun awọn eeyan agbegbe Adamo, ni Ikorodu, lori bi wọn ṣe fi ṣikun ofin mu ọkunrin kan ti wọn pe ni imaamu mọṣalaṣi kan legbegbe naa lẹyin ti wọn ka ori eeyan mọ lọwọ.

A gbọ pe awọn eeyan naa fa imaamu ọhun, ti wọn pe orukọ rẹ ni Babalola le awọn ọlọpaa lọwọ lẹyin ti wọn mu tan.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, oun atawọn afurasi mẹrin mii ni ọwọ tẹ.

Fidio kan loju opo X ṣafihan awọn olugbe agbegbe naa pẹlu awọn oṣiṣẹ eto abo agbegbe nipinlẹ Eko, Lagos Neighbourhood Safety Corps, ti wọn yi afurasi naa ka.

Wọn mu afurasi ọhun t'oun ti baagi kan ti ori eeyan atawọn nnkan mii ti igbagbọ wa pe wọn jẹ ẹya ara eeyan wa ninu rẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Nigba to n sọrọ lori iṣelẹ naa, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin sọ pe iwadii yoo waye lori iṣẹlẹ ọhun, idajọ ododo yoo si tẹle.

O ni “A gboriyin fun awọn eeyan Ikorodu fun bi wọn ṣe ṣe ohun to yẹ ti wọn ko si ṣe idajọ lọwọ ara wọn lati da seria fun afurasi.

“A o ri dajo pe idajọ ododo waye lori ọrọ yii.”

Ṣaaju ni ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa ti kọkọ sọ fun ileeṣẹ iroyin Punch pe Ọjọbọ ni ọwọ tẹ afurasi naa.

O ni “Ọwọ tẹ Imaamu agba mọṣalaṣi gbogbogbo to wa ni Adamo, ni Ikorodu atawọn mii, wọn ti ko wọn lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si ọrọ ijinigbe ati ẹgbẹ okunkun.”