Ǹjẹ́ o ti gbọ́ nípa omi aládùn tí wọ́n ń ta ìgò rẹ̀ kan ní ₦86,000?

Oríṣun àwòrán, Milin Patel
- Author, Suneth Perera
- Role, BBC World Service
Njẹ o ti de ile ounjẹ ri, to si jẹ pe oun ti wọn n ta nibẹ ni omi to mọ geere dipo ọti waini olowo iyebiye?
Irufẹ omi naa jẹ eyi to dara ju omi inu igo tabi ike lọ, eyii ti iye ti wọn n ta a le ni ọgọrun un dọla.
Gẹgẹ bii ohun ti a mọ, wọn le ta omi olowo iyebiye naa pẹlu ounjẹ gẹgẹ bi wọn ṣe n ta ọti waini pẹlu ounjẹ.
Awọn omi naa, ti wọn n pe ni ‘fine water’ lo wa lati inu apata, awọn yinyin to di sori alagbalugbu omi, omi iri to n ṣe, bẹẹ ni wọn tun n ri omi naa taara lati oju ofururufu.
Irufẹ omi olowo iyebiye bayii lo pọ kaakiri agbaye.
Ṣe eeyan le mọ adun omi lẹnu?

Oríṣun àwòrán, Milin Patel
Gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe maa n tọ adun ọti waini wo, awọn kan wa to jẹ pe iṣẹ ti wọn yan laayo ni ki wọn maa tọ adun omi wo.
Millin Patel, to jẹ onimọ nipa omi niluu London sọ pe “omi ko kan wa lasan, gbogbo omi to wa lagbaye lo ni adun tirẹ.”
Ọkunrin naa maa n ko awọn eeyan to nifẹ si omi jọ lati maa tọ adun rẹ wo, lara eyii ti omi ẹrọ ati omi inu ike wa.
Patel sọ fun BBC pe afojusun oun ni lati kọ awọn ọdọ nipa oniruuru omi to wa ati adun ọtọọtọ ti awọn omi naa ni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn omi bii eyii ti wọn ri lara yinyin to di sori omi okun tabi omi ojo ti ko tii gba inu ilẹ kọja yatọ si omi inu kọnga.
Patel ni agbajọpọ omi lati oriṣiriṣi orisun kaakiri agbaye bẹrẹ lati omi ẹrọ titi de omi olowo iyebiye ti iye ti wọn n ta igo kan re jẹ $318.
Ti awọn eeyan ba tọ awọn omi naa wo, wọn maa n sọ bo ṣe ri lẹnu.
Orukọ ti Patel pe adun omi lẹnu ni “aquatasteology."
idije titọ adun omi wo
Ajọ Fine Water Society maa n ko ara wọn jọ lọdọdun lati ṣe idije titọ adun omi wo.
Awọn eeyan naa maa n korajọ kaakiri agbaye bẹrẹ lati Bhutan titi de Ecuador.
Pupọ ninu awọn to maa n kopa ninu idije naa jẹ awọn ti wọn n ṣowo omi ni idile wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkan lara awọn to da ajọ Ajọ Fine Water Society naa silẹ, Michael Mascha sọ pe awọn eeyan kọkọ ri idije naa gẹgẹ bii fifi akoko ṣofo ṣaaju.
Amọ lẹyinorẹyin, o ni awọn ti mọ iyi ajọ ati idije naa bayii.
Omi ati ounjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ile ounjẹ kan nilẹ Amẹrika ati Spain ti n ta omi aladun papọ mọ ounjẹ bayii.
Mascha sọ pe “a n mura lati ṣagbekalẹ omi aladun bii mejila si mẹẹdogun ti awọn eeyan yoo maa ra pẹlu ounjẹ.
‘Ti eeyan ba jẹ ẹja, yoo mu omi aladun to yatọ le lori, ti eeyan ba jẹ ẹran, yoo mu omi to tun yatọ.”
Omi aladun ti wọn pe ni ‘fine water’ yii tun wọ pọ lawọn awujọ ti wọn ti n yago fun ọti lile latari ẹsin wọn.
Ọmọwe Mascha ni omi aladun naa dara, o si wulo lati paarọ awọn ọti olowo iyebiye.
Amọ ṣa, kii ṣe gbogbo eeyan lo fọwọ si aba ati erongba idasilẹ omi aladun ọhun.
'Kii ṣe ohun to bojumu'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ eeyan kaakiri agbaye ni ko ri omi to mọ geere mu, eyii to mu ki ọpọ eeyan koro oju si aba omi aladun yii, eyii ti wọn ri gẹgẹ bi ọna lati maa pa owo wọle fun awọn eeyan kan.
Gẹgẹ bi atẹjade ajọ UN, nnkan bii 2.2 biliọnu eeyan ni ko ri omi to mọ gere mu lagbaye.
Awọn miran ti wọn tun n bu ẹnu atẹ lu omi aladun ọhun sọ pe jibiti lasan ni, nitori omi ni omi n njẹ.
Wọn ni ko si iyatọ kankan to wa laarin omi ẹrọ, omi inu igo ati omi ti wọn pe omi aladun naa.
Carolyn Roberts, to jẹ ọjọgbọn nipa ọrọ ayika nile ẹkọ Gresham College, niluu London ni ko tọ ki awọn eeyan maa na ẹgbẹlẹgbẹ owo lori igo omi kan ṣoṣo, nigba ti awọn onimọ nipa ọrọ ayika sọ pe igo omi n ṣakoba fun ayika paapaa.
O ni “Kii ṣe nipa ọrọ owo nikan, o tun n ṣakoba fun ayika wa."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọ Ọmọwe Mascha ti fesi pe kii ṣe awọn ọlọla nikan ni omi aladun naa wa fun, nitori omi aladun ti iye owo rẹ ko ju $2 lọ wa.
O wa gba awọn eeyan nimọran lati maa lo omi ẹrọ dipo omi inu igo lati le dẹkun akoba ti ike n ṣe fun ayika.












