Àwọn ọmọ Palestine t’ọ́rọ̀ kàn ṣàlàyé bi ogun Israel ṣe ń jẹ Gaza run

Ogun o da bii iyan, bẹẹ ni ko da bii ẹkọ yangan. Ipaya, ebi, idaamu, iku oro, itajẹsilẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ ti ogun maa n mu wa lo n koju awọn eeyan ni Gaza latọdun to kọja.
Eyi lo fa a tawọn ọmọ Palestine ti kinni ọhun kan ṣe fi idaamu ọkan ṣalaye ohun to n ṣe wọn fun ẹka iroyin BBC.
O ti ju ẹgbẹrun mẹrinlelogun (24,000) eeyan lọ ti wọn ti ku ni Gaza latigba ti ogun yii ti bẹrẹ lọjọ keje, oṣu kẹwaa ọdun 2023.
Ila-Oorun Gaza ni ikọlu n ba ju lẹnu lọọlọ yii.
Ikọlu ti Hamas ṣe si Isreal ti gba ẹmi eeyan to to ẹgbẹrun kan ati ọọdunrun (1,300), ojilenigba (240) awọn to wa nigbekun ogun ni wọn si da pada si Gaza.
Ninu eeyan bii miliọnu meji aabọ to n gbe ni Gaza, awọn to ti di alainile lori ko ṣẹe ka.
Ko sounjẹ, ko si omi bẹẹ ni ko soogun fẹni to ba n ṣaarẹ lati lo.
‘’Mo padanu ile, iṣẹ ati ṣọọbu mi. Ebi n pa awọn ọmọ mi lojuu mi mi o si le ṣaanu fun wọn’’
Ọkunrin kan, Mohammed al-Khaldi, to bimọ meji, sọ fun BBC pe oun padanu gbogbo ọna ijẹ oun.
O ni loju oun bayii ni awọn ọmọ meji toun bi ti n kigbe ebi toun ko si ni nnkan kan lati fun wọn jẹ.
Ajọ Hamas to jẹ ti Palestine lo n dari Gaza lati 2007. Ẹka ologun rẹ ti wọn n pe ni Izzedine al-Qassam Brigades, ni to ọmọ ogun ẹgbẹrun lọna ọgbọn (30,000) ko too di pe ogun bẹrẹ lọdun to kọja.
Ilọpo mẹwaa ni afikun owo to gun ori ounjẹ
Khalid fibanujẹ ṣalaye, pe ilọpo mẹwaa ni afikun owo to gori ounjẹ ti awọn n ri ra.
O ni awọn ounjẹ ti Ajọ Iṣọkan Agbaye ni ki wọn pin ni awọn kan ji, ti wọn n sọ di tita lowo nla. Ọlọpaa ko si mu wọn.
‘A fẹẹ ki ogun pari, ka si ri ọna abayọ ọlọdun pipẹ’
Neveen Imadedin, obinrin kan ti ogun le ni Gaza,sọ pe ko s’ile, ko s’owo, ko s’ounjẹ bẹẹ ni ko si alaafia.
‘’A fẹẹ ki ogun yii pari ka si ni ọna abayọ ọlọdun pipẹ. A o fẹe pada si iṣakoso Hamas mọ bi ogun ba pari.’’












