Ọkọ̀ ojú omi tó kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dànù ní India, ọmọdé méjìlá jáde láyé

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọmọ ile ẹkọ mejila ati olukọ meji ni igbagbọ wa pe wọn ti ba omi lọ nipinlẹ Gujarat, ni India, lẹyin ti ọkọ oju omi to gbe wọn danu.
Awọn ọlọpaa ipinlẹ naa ti wọn fidi iroyin ọhun mulẹ fun BBC sọ pe awọn adoola ẹmi ti n ṣiṣẹ nibi iṣẹlẹ naa.
Titi di akoko ti n ko iroyin yii jọ, ko si ẹni to tii le sọ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.
Iroyin ni nnkan bii eeyan mẹtadinlọgbọn lo wa ninu ọkọ oju omi naa ko to danu.
Kọmiṣọna ọlọpaa, Anupam Singh Gehlot sọ fun BBC pe awọn ti yọ eeyan meje jade ninu odo ọhun laaye, wọn si ti n gba itọju lọwọ nile iwosan.
O ni awọn eeyan ti ọrọ naa kan ko wọ aṣọ alefo lori omi ‘life jacket’ lasiko ti wọn wa ninu ọkọ naa.
Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ, olootu ijọba India, Narendra Modi ba mnọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn kẹdun.
Minisita to n bojuto agbegbe Gujarat, Bhupendra Patel sọ pe ijọba yoo pese owo ti iye rẹ to $4,800 fun mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn atawọb ti wọn ṣeṣe nibẹ.

Oríṣun àwòrán, reuters
Ijanba ọkọ omi kii ṣe ohun tuntun ni India latari bi ọpọ ero to pọ ju ọkọ ṣe maa n di ara wọn sinu ọkọ oju omi, ti pupọ ninu awọn eeyan ọhun kii si i wọ ohun idaabobo ninu ọkọ oju omi.
Lọdun to kọja, eeyan mejilelogun lo ku lẹyin ti ọkọ oju omi kan danu lagbegbe ila oorun ipinlẹ Kerala.














