Kí ló dé tí eran ajá jíjẹ fẹ́ di èèwọ̀ ní South Korea?

Àwọn ajàfẹ́ẹ̀tọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọbẹ̀ ajá tí wọ́n ń pè ní boshintang jẹ́ ọbẹ̀ tí àwọn àgbàlagbà ní orílẹ̀ èdè South Korea fẹ́ràn láti máa jẹ.

Àmọ́ ọbẹ̀ yìí yóò di èèwọ̀ nígbà tó bá máa fi tó ọdún díẹ̀ sí àsìkò yìí ní orílẹ̀ èdè náà.

Pípa ajá àti títa ẹran rẹ̀ yóò di ohun tó lòdì sí South Korea bí àwọn aṣòfin ní orílẹ̀ èdè ṣe gbé òfin kan kalẹ̀ láti tí wọ́n sì buwọ́lùú lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun láti fòpin sí pípa ẹranko yìí.

Gẹ́gẹ́ bí àgbékalẹ̀ òfin tuntun yìí, tí wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àmúlò rẹ̀ lọ́dún 2027, jíjẹ ẹran ajá nìkan kọ́ ló lòdì sófin báyìí, títà rẹ̀ náà ti dèèwọ̀.

Ìwádìí Gallup ní ọdún 2023 ṣàfihàn pé ìdá mẹ́jọ àwọn ènìyàn ní South Korea ló jẹ ajá láàárín ọdún náà lòdì sí ìdá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tí wọ́n jẹ ẹ́ ní ọdún 2015.

Boshintang kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́.

Lee Chae-yeon, akẹ́kọ̀ọ́ ẹni ọdún méjìlélógún ní fífi òfin de ajá jíjẹ jẹ́ ohun tó dára lójúnà àti mú ìgbéga bá ẹ̀tọ́ àwọn ẹranko.

Ó sọ fún BBC ní Seoul pé “lóde òní, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ní ẹranko nílé gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀sìn”

“Àwọn ajá ti di ara ẹbí wa àti pé a ò lè máa jẹ ẹbí wa.”

Kí ni òfin náà sọ?

Ajá

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Òfin tuntun ọ̀hún dá lórí títà àti ríra ẹran ajá.

Ẹni tí wọ́n bá fi ṣìnkún òfin gbámú pé ó lọ́wọ́ nínú pípa ajá lè rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta he, tí ẹni tí ó bá ń sin ajá pẹ̀lú èròńgbà láti ta ẹran ajá lè rí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì.

Àwọn tó ń ṣe òwò yìí àtàwọn ilé oúnjẹ tí wọ́n ń fi ẹran ajá ṣòwò ní ọdún mẹ́ta láti fi iṣẹ́ mìíràn tí wọn yóò máa ṣe kí òfin náà tó gbérasọ.

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe fi múlẹ̀, South Korea ní ilé oúnjẹ 1,600 tí wọ́n ti ń ta ajá àti ọgbà 1,150 tí wọ́n ti ń sìn wọ́n fún títa ẹran wọn.

Àwọn tó ni iléeṣẹ́ yìí yóò ní láti ṣàgbékalẹ̀ wọn fún àwọn aláṣẹ tó máa ṣètò bí wọ́n ṣe máa ti àwọn iléeṣẹ́ náà pa kí àsìkò tó tó.

Ìjọba ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ran àwọn tó ń ṣòwò ẹran ajá títà, tí wọn yóò pa iṣẹ́ wọn rẹ́, pẹ̀lú owó gbà mábìnú àmọ́ wọn ò tíì sọ pàtó nǹkan tí wọ́n máa fún wọn.

Kim Seon-ho, ẹni ọdún mẹ́rìndínláàdọ́rin ní fífi òfin de ajá jíjẹ jẹ́ ohun tí òun kò lérò rárá.

“Láti ọdún pípẹ ni a ti ń jẹ ajá, kí ló dé tí wọ́n fẹ́ dáwa lẹ́kun láti máa jẹ oúnjẹ àdáyébá wa? Tí wọ́n bá fi òfin de ajá jíjẹ, ó yẹ kí wọ́n fi òfin de ẹran màálù náà ní jíjẹ.

Ṣíṣe àgbéyẹ̀wò òfin

Ènìyàn tó ń jẹ ajá

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1980 ni ìjọba ti ń gbèrò láti fòfin de ẹran ajá jíjẹ àmọ́ tó ń já sí pàbó.

Ààrẹ South Korea, Yoon Suk-yeol àti ìyàwó rẹ̀, Kim Keon-hee fẹ́ràn ẹranko lọ́pọ̀lọpọ̀. Ajá mẹ́fà ni wọ́n ní.

Láti ọjọ́ pípẹ́ ni Kim ti ń pè fún fífi òpin sí jíjẹ ẹran ajá.

Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹranko, tí wọ́n ti máa ń pè fún òfin yìí ní ìgbésẹ̀ àwọn aṣòfin náà dùn mọ́ àwọn nínú.

Jung Ah Chae, adarí ẹgbẹ́ dídá ààbò bo àwọn ẹranko ní Korea ní òun kò mọ̀ pé òfin náà yóò sí àmúṣẹ nígbà tí òun bá ṣì wà láyé.

Ó ní inú òun dùn pé àwọn fi òpin sí àṣà náà ní orílẹ̀ èdè àwọn.

Àwọn tó ń ta ẹran ajá bu ẹnu àtẹ́ lu òfin náà.

Wọ́n ní pẹ̀lú bí àṣà jíjẹ ajá kò ṣe wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́, ó yẹ kí wọ́n gbà wọ́n láàyè kí àṣà náà kú fúnra rẹ̀ ni.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ta ẹran ajá ló jẹ́ àgbàlagbà, tí wọ́n sì ní yóò ṣòrò fún àwọn láti bẹ̀rẹ̀ sí ni ṣe iṣẹ́ mìíràn pẹ̀lú ọjọ́ orí àwọn.

Joo Yeong-bong, ẹni tó máa ń sin ajá fún títà ní ní àwọn yóò pàdánù okoòwò àwọn ní ọjọ́ orí tí àwọn wà àti pé òfin náà tako ẹ̀tọ̀ ọmọnìyàn nítorí kò gba àwọn láàyè láti jẹ nǹkan tó bá wu àwọn.

Kim ní tirẹ̀ ní nítorí àwọn ènìyàn tọ ń ní ẹranko gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀sìn nílé ni South Korea ni ìjọba ṣe fòfin de ajá jíjẹ.

“Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò fẹ́ ní ìyàwò tàbí ọkọ mọ́, tí wọ́n ń sọ nǹkan ọ̀sìn di ẹbí nítorí náà ni wọn kò fẹ́ kí àwọn jẹ ajá mọ́.

Ó ní tí àwọn orílẹ̀ èdè bíi China àti Vietnam bá ń jẹ ajá, kò yẹ kí àwọn le fòfin de ajá lọ́dọ̀ àwọn.