Akeredolu, Bola Ige, Akintola àtàwọn èèkàn ìlú tó pàdánù dúkìá sínú ìbúgbàmù tó wáyé ní Ibadan

Oríṣun àwòrán, Oluwarotimi akeredolu/bbc/others
Bí àwọn ènìyàn ṣe pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìbúgbàmù tó wáyé ní ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo lálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Kìíní ni àwọn ọ̀pọ̀ dúkìá náà run sínú ìṣẹ̀lẹ̀.
Àwọn dúkìá ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ni ó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.
Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Nàìjíríà ní àwọn ilé tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí lọ jẹ́ méjìdínlọ́gọ́ta.
Gẹ́gẹ́ bí agbègbè tí ìbúgbàmù náà ti wáyé ṣe jẹ́ àdúgbò tí a lè pè ní àdúgbò tí àwọn tórí bẹ́gi ọ̀là fún, ọ̀pọ̀ àwọn èèkàn ìlú lọ pàdánù dúkìá wọn sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Lára àwọn tó pàdánù dúkìá wọn sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni a ti rí gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ondo Rotimi Akeredolu àti igbákejì gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Oyo, Iyiola Oladokun.
Ilé ìtura tó jẹ́ ti Rotimi Akeredolu ni ó run sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí Iyiola Oladokun sì pàdánù ilké ìgbé rẹ̀ sínú ìbúgbàmù náà.
Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Oluwarotimi Akeredolu/x
Ileegbe rẹ to wa lagbegbe naa ni gbajugba amofin ati gomina ipinlẹ Ondo to jade laye laipẹ yii naa padanu sinu ibugbamu naa.
Oloye Bola Ige

Oríṣun àwòrán, others
Ileegbe oloogbe agba amofin ajafẹtọ ati gomina tẹlẹri naa wa lara awọn dukia to ba iṣẹlẹ naa rin.
Amofin Adeniyi Akintọla SAN

Oríṣun àwòrán, Adeniyi Akintola
Ile itura meji to jẹ ti agba amofin yii lo ba iṣẹlẹ naa lọ.
Orukọ ọkan lara awọn ile itura naa ni 'House 40'
Oloye Iyiọla Ọladokun

Oríṣun àwòrán, others
Ile Oloye Ọladaokun, ẹni to ti fi igba kan ri jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ gomina Alao Akala, pẹlu fara gba ninu iṣẹlẹ ibugbamu naa.
Oloye Ọladokun sọ ọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe oun ati idile oun n wo ifẹsẹwọnsẹ bọọlu kan lọwọ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ eyi to ba awọn dukia ati ara ile naa jẹ.

Awọn eekan miran ti iṣẹlẹ ibugbamu naa kan dukia wọn
Alhaja Amdalat Ololade Agboola

Oríṣun àwòrán, Alhaja Amdalat Ololade Agboola
Sẹnetọ Hosea Ayoola Agboola (Halleluya)

Oríṣun àwòrán, others
Amofin Bamidele Aiku, SAN

Oríṣun àwòrán, others
Yàtọ̀ sí àwọn yìí àwọn èèkàn tó tún pàdánù dúkìá wọn sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà nìwọ̀nyí:
- Yanju Adegbite - Ilé ìgbé
- Barrister Wole Iyamu SAN - Ilé ìgbé
Àrànkáyé ni ìbúgbàmù tó wáyé ní Ibadan, wo àwọn agbègbè tí ìrọ́kẹ̀kẹ̀ rẹ̀ ràn dé

Oríṣun àwòrán, James Igbasan/bbc
Níṣe ni ọ̀rọ̀ di bóo lọ kò yà fún mi fún àwọn olùgbé ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo látàrí ìbúgbàmù ńlá kan tó wáyé níbẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun.
Ní agbègbè Adeyi Avenue, Bodija ni ìbúgbàmù tó mi gbogbo ìlú Ibadan tìtì náà wáyé ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́.
Ìbúgbàmù náà lágbára débi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló farapa, tí àwọn ilé sì dàwò.
Àwọn ilé tí kò jìnà púpọ̀ sí àdúgbò náà tún fara kásá ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún bí òrùlé àtàwọn fèrèsé wọn ṣe ya lulẹ̀.
Àmọ́ kò fẹ́ẹ̀ sí àdúgbò nínú Ibadan tí wọn kò tí gbọ́ nípa ìbúgbàmù ọ̀hún èyí tó mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ máa fún ní ìtumọ̀ oríṣiríṣi kí àwọn aláṣẹ tó fìdí ohun tó wáyé gan múlẹ̀.
Lára àwọn ibi tí wọ́n ti gbúròó ìbúgbàmù náà ni àwọn kàn dédé gbọ́ tí nǹkan dún tí gbogbo ilé àwọn mì tìtì.
Àwọn àdúgbò bí Ologuneru, Eleyele, Sango, Yemetu, UI, Agbowo, Ojo tó fi mọ́ Iwo road àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìró ìbúgbàmù náà.

Oríṣun àwòrán, Google Earth/James Igbasan
"Ilé wa gbọ̀n rìrì, a sá jáde láti sá àsálà fún ẹ̀mí wa"

Nígbà tí akọ̀ròyìn BBC News Yorùbá bá àwọn olùgbé Ibadan sọ̀rọ̀, wọ́n ṣàlàyé bí ìbúgbàmù náà ṣe náà rinlẹ̀ tó ní agbègbè ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.
Olùgbé Ibadan kan tó ń gbé ní agbègbè Ologuneru sọ wí pé ṣàdédé ni òun gbọ́ tí nǹkankan dún nígbà tí òun wà nínú yàrá òun.
Ó ní bí nǹkan náà ṣe dún ni gbogbo ilé àwọn mì tìtì tí àyà sì pá àwọn nítorí àwọn kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní pàtó.
Ó ṣàlàyé pé àwọn ti ẹ̀ rò pé ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì ló wáyé ni nítorí bí ìbágbàmù náà ṣe dún lágbára púpọ̀.
Ẹlòmíràn tó ń gbé ní agbègbè Yemetu, Adewuni sọ fún BBC News Yorùbá níṣe ni àwọn sá jáde kúrò nínú ilé àwọn láti sá àsálà fún ẹ̀mí àwọn nígbà tí ìbúgbàmù náà dún.
Adewunmi ní ó dàbí pé ilé àwọn ni ìbúgbàmù náà ti wáyé nítorí òun kò gbọ́ ariwo bẹ́ẹ̀ rí láti ìgbà tí àwọn ti ń gbé ibẹ̀.
“A ò mọ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní pàtó, a ò mọ ibi tí à ń sá lọ, a kàn sá jáde nílé ni nítorí a ò mọ ohun tó fa nǹkan tó dún náà.”
Bákan náà ni Faoziah Bankole tó ń gbé ní agbègbè Iwo road ní ṣàdédé ní ilẹ̀kùn tó wọ ilé ìdáná àwọn ṣí lójijì láì sí ẹnikẹ́ni tó débẹ̀.

Ó ní bí ilẹ̀kùn náà ṣe ṣí ni àwọn gbọ́ ohun tí nǹkan dún ṣùgbọ́n ò mọ ohun tó jẹ́ tí àwọn sì padà sínú yàrá àwọn.
Ó ní kò pẹ́ ni àwọn bẹ̀rẹ̀ sí ní ka ìròyìn lórí ayélujára pé ìbúgbàmù alágbára kan ti wáyé ní àdúgbò Bodija àti pé àwọn ènìyàn ti farapa yánnayànna.
Ṣáájú ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ibadan tó ń gbé nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún ti fi sórí ayélujára bí ìró ìbúgbàmù náà ṣe lágbára tó lọ́dọ̀.
Ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé Ibadan ló fi ìrírí wọn sórí ayélujára láti alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Gómìnà Seyi Makinde nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́rú ṣàlàyé pé àwọn tó ń wakùsà ló kó àwọn àdó olóró kan pamọ́ sí ilé kan ní agbègbè náà ló bú gbàmù.
Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ́, àwọn òṣìṣẹ́ tó ń dóòlà ẹ̀mí ṣì wà ní ibùdó tí ìbúgbàmù náà ti wáyé láti dóòlà àwọn ènìyàn tó hà sí abẹ́ àwọn ilé tó dàwó.
Bí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ‘Ìbúgbàmù Gbankọgbì’ tó wàyé ní Ibadan ṣe jẹ́ nìyí

Oríṣun àwòrán, Other
Iṣẹlẹ ibugbamu kan ti waye ni aṣalẹ ọjọ Iṣẹgun ni ilu Ibadan.
Gẹgẹ bi awọn kan to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣe sọ iro ibugbamu naa rinlẹ de awon agbegbe kaakiri ilu Ibadan ni nnkan bii agogo mẹjọ alẹ to waye.
Ki ni awọn eeyan n sọ pe o ṣẹlẹ gan?
Ṣe ni igboro daru ti ipaya si ba ọpọlọpọ awọn olugbe ibadan ni kete ti iro ibugbamu naa waye eyi to mi ọpọlọpọ agbegbe ilu nla naa lalẹ ọjọ Iṣẹgun
Lara awọn agbegbe ti irọkẹkẹ ibugbamu naa de ni Bodija, Agbowo, Ẹlẹyẹle, Orogun, ati General Gas .
Bakan naa lawon eeyan to wa lagbegbe bii Iwo road, Gate, Bẹrẹ Mokola ati bẹẹbẹ lọ pẹlu ni awọn pẹlu gbọ jinijini irọkẹkẹ ibugbamu ọhun.
Awọn fidio ati aworan to n jẹyọ lori ayelujara n se afihan awọn oku ti wọn gbe kuro lagbegbe naa .
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Nibo gan ni ibugbamu ọhun ti waye?
Ninu ọrọ to ba akoroyin ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ Channels sọ, adari ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria (NEMA) lẹkun iwọ oorun gusu Naijiria, Saheed Akiode ṣalaye pegbogbo awọn oṣiṣẹ alamojuto iṣẹlẹ pajawiri titi kan awọn panapan lo ti dari si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ni Adeyi Avenue ni opopona Awolọwọ lagbegbe Bodija .
Ki ni ijọba ipinlẹ Ọyọ n sọ?
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ninu atẹjade kan ti ijọba ipinlẹ Oyo fi sita, ko tii si ẹni le sọ pato ohun gan to fa ibugbamu naa
Kọmiṣọna feto iroyin, Dọtun Oyelade ṣalaye pe ijoba ti bẹrẹ igbesẹ gbotbo to yẹ lori rẹ.
Bẹẹni Gomina Seyi Makinde ti ke s’awọn adari ẹka alaabo gbogbo lati tete gbe igbesẹ to yẹ.














