Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti rí okú àwọn èèyàn míì níbi ìbùgbàmù Ibadan

Oríṣun àwòrán, bbc
Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe iye eeyan to ku nibi ibugbamu to waye niluu Ibadan lọjọ Iṣẹgun ti pe marun un bayii.
Ṣaaju ni gomina Seyi Makinde ti kọkọ sọ pe eeyan meji lo jade laye nibẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun, ko to fi kun pe ẹni kẹta ti jẹ Ọlọrun nipe.
Wayi o, ninu atẹjade kan ti alubadamọran si Malinde lori eto abo, Fatai Owoseni fi lede, o ni awọn tun ti ri oku eeyan meji mii nibẹ.
Owoseni sọ pe “iṣẹ ṣi n lọ lọwọ nibẹ, lana, eeyan mẹta lo padanu ẹmi wọn ṣugbọn laarọ oni, mo gbọ lati ọdọ awọn agbofinro n ran awọ oṣiṣẹ eto ilera lọwọ pe awọn tun ti ri oku eeyan meji mii.”
Awọn olugbe Adeyi Avenue, ni Bodija ti iṣẹlẹ naa ti waye ti di ẹbi iṣẹlẹ naa le awọn awakusa lai gba aṣẹ ijọba lori.
Ẹwẹ, Aarẹ Bola Tinubu ti sọ pe awọn agbofinro gbọdọ ṣawari gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.
Wo àwọn ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ tó gbòde nípa ìbúgbàmù Ibadan àti òkodoro

Oríṣun àwòrán, bbc
Oniruru iroyin ẹlẹjẹ ni awọn eeyan ti gbe kiri ori ayeljara nipa ibugbamu to waye niluu Ibadan lalẹ ọjọ Iṣẹgun.
Lọpọ igba ti irufẹ iṣẹlẹ bayii ba waye lawọn eeyan maa n gbe iroyin ẹlẹjẹ nipa irufẹ iṣelẹ bẹẹ fun idi kan tabi omiran
Lara awọn iroyin ẹlẹjẹ to gbode ipa ibugbamu iklu Ibadan yii ni eyii to sọ pe ile itaja igbalode, Ace Mall ti dawo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ṣugbọn awọn fidio ti a ri lẹyin atẹjde naa fi han pe digbi ni ile itaja ọhun ṣi duro.
Arakunrin kan to n jẹ @MayorLadseriki_ ṣe afihan apakan orule ile itaja naa ti ibugbamu ọhun pa lara, o si sọ pe oun wa nibẹ lasiko iṣẹlẹ ọhun.
Ẹlomiran loju opo X, David Fatunmbi, ṣafihan ile itaja naa, to ṣi duri digbi, bo tilẹ jẹ pe apakan awọn gilaasi rẹ ti fọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Yatọ si ile itaja Ace Mall yii, oniruru ọrọ lawọn eeyan tun sọ loju opo X nipa iṣẹlẹ ọhun.
Lara awọn nnkan ti awọn eeyan n sọ ni pe iṣẹ ọwọ awọn agbesumọmi ni ibugbamu naa, ati pe awọn araalu ni lati maa ṣọ ara wọn lasiko yii.
Ṣugbọn nigba to n gba awọn akọroyin sọrọ, gomina ipinlẹ naa, Seyi Makinde sọ pe iwadii ti awọn kọkọ ṣe ti fidi rẹ mulẹ pe ado oloro ti awọn to n wakusa lai gba aṣẹ ijọba ko sile lo ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.
Wayi o, eeyan mẹta lo jade laye latari iṣẹlẹ naa, nigba ti awọn 77 farapa.
'Ọ́gá mi ṣì wà lábẹ̀ ilé tó dàwó nítorí ìbúgbàmù tó wáyé'

Ijọba ipinlẹ Oyo ti ke si awọn olugbe agbegbe Adeyi, ni Bodija, niluu Ibadan lati fi agbegbe naa silẹ latari ibugbamu nla to waye nibẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun.
O tun ke si awọn ile iwosan lagbegbe ọhun lati maa ṣetọju awọn eeyan to farapa ti wọn ba gbe wa si ọdọ wọn lai jafara.
Ṣaaju ni ibugbamu naa ti kọkọ sọ ọpọ olugbe ilu Ibadan sinu ibẹrubojo lalẹ ọjọ Abamẹta, eyii ti iroyin ni o waye lẹyin ti awọn kan to n ṣiṣẹ iwakusa ko ohun ibugbamu sile.
Oniruru fidio lo ṣafihan awọn ile to wo ati awọn eeyan to farapa lẹyin ibugbamu naa.
Akọroyin BBC foju ganni bi wọn ṣe doola ọkunrin agbalagba kan labẹ ile to dawo laarọ Ọjọru.
Pupọ ninu awọn eeyan agbegbe naa lo wa n ẹkun mu pẹlu ireti pe awọn ololufẹ wọn ko faragba ninu iṣẹlẹ ọhun.
Ọkan ninu awọn eeyan naa to n ṣiṣẹ ile kikun sọ fun BBC pe “ana ode yii ni mo ṣi n kun ọkan lara awọn ile to dawo ti mo si sọ pe mo maa tẹsiwaju lonii lẹyin ti mo gba ibẹ lọ sile ijọsin.
“Mo ti n pe ẹni to ni ile naa amọ ẹrọ ipe rẹ ko wọle, mo si ri pe ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ti ba iṣẹlẹ naa lọ.

'Ibugbamu naa pa ẹrọ ilewọ mi ku lẹsẹkẹsẹ'
Ẹlomiran, Aarinola ṣalaye fun BBC pe ori ẹrọ ilewọ loun ti n ba ẹnikan sọrọ ki ibugbamu nla naa to ṣẹlẹ, eyii to mu ki ẹrọ ilewọ oun ku lẹsẹ kan naa.
O ni “Awọn ọmọ mi sare jade lati inu yara lati bere ohun to ṣẹlẹ lọwọ mi, a sare jade amọ a ko ri ohunkohun, lẹyin naa ni a bẹrẹ si n sare fun bii wakati mẹta nitori ko si ẹni to le duro sinu ile pẹlu oorun kẹmika ati ilẹkun pẹlu ferese to ti wo.
Aarinola fi kun pe awọn ọmọ oun ko tii pada sinu ile naa lati igba ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Lara awọn olugbe agbegbe naa miran sọ pe awọn ṣi n wa awọn eeyan wọn, wọn ni igbagbọ wa pe lara awọn eeyan naa ṣi wa labẹ awọn ile to dawo.
Ọkunrin kan ti ko fẹ fi orukẹ rẹ lede sọ pe ori lo ko oun yọ lọwọ iku ojiji nitori lẹyin iṣẹju mẹwaa ti oun fi ile ọga oun silẹ ni iṣẹlẹ ọhun waye.
Ọkunrin naa bẹ awọn agbofinro pẹlu onije loju pe ki wọn ba oun yọ ọga oun ti igbagbọ wa pe o ṣi wa labẹ ile to dawo.

Wo ohun tó ṣokùnfà ìbúgbàmù tó mi ìlú Ibadan tìtì lálẹ́ àná

Oriṣiiriṣii nkan lawọn eeyan ti n sọ pe o ṣe okunfa ibugbamu to rinlẹ eleyii to waye lalẹ ana ọjọ Iṣẹgun lopopona Dejo Oyelese lagbegbe Bodija niluu Ibadan.
Ọpọ eeyan niluu Ibadan ni wọn sọ pe awọn gbọ iro ati didun ibugbamu naa bo tilẹ jẹ pe ọpọ ninu wọn lo n gbe ni adugbo to jina si ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Awọn kan tiẹ sọ pe ilẹ riri lo ṣẹlẹ niluu Ibadan pẹlu bi ọpọ ile ti mi titi kaakiri ilu Ibadan nigba ti ibugbamu ọhun ṣẹlẹ.
Amọ, gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti tan imọlẹ si iṣẹlẹ ọhun.
Makinde sọ ni pato ohun ti o ṣe okunfa ibugbamu naa ati awọn eeyan to ba iṣẹlẹ ọhun lọ to fi mọ awọn to farapa.
Gomina Seyi makinde ṣalaye ohun to fa ibugbamu ni Ibadan
Nigba ti Makinde ṣe abẹwo sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, o ṣapewuye iṣẹlẹ ọhun gẹgẹ bi eyi to ba ni lọkan jẹ nitori o mu ẹmi lọ.
Gomina ipinlẹ Oyo ṣalaye pe iwadii ti fihan pe ado oloro tawọn eeyan kan to n wa kusa lọna aitọ ko pamọ sibi kan lo ṣokunfa ibugbamu naa.
Makinde ni iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun, amọ gbogbo ẹni to ba wa nidi ibugbamu yii ni yoo foju wina ofin.
‘’Lẹsẹ kẹsẹ ni awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ti ipinlẹ Oyo ti lọ sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ti wọn si bere si ni ṣiṣẹ bakan naa.
Wọn ṣiṣẹ lati alẹ di aarọ Ọjọru ni, oriṣiiriṣii irinṣẹ idoola ẹmi, ọkọ anbulaunsi atawọn eṣọ eleto lo ti wa nibẹ.
Ni bayii, eeyan mẹtadinlọgọrin lo farapa ninu iṣẹlẹ naa, amọ, wọn ti gba itọju nile iwosan, wọn si ti pada sile wọn.
Amọ, o ṣeni laanu pe eeyan meji lo ba iṣẹlẹ naa lọ, ki Ọlọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere ki o si tu awọn ẹbi wọn ninu.
Ijọba ipinlẹ Oyo ni yoo san owo itọju awọn eeyan ti wọn ṣeeṣe nibi iṣẹlẹ yii.
Ijọba tun maa pese ilegbe fawọn ti ko nile lori mọ latari iṣelẹ yii,’’ Makinde lo sọ bẹẹ.
Gomina ipinlẹ Oyo wa rọ gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Oyo naa lati pe nọmba 615 fun iṣẹlẹ pajawiri nigba ti o tun rọ wọn pe ki wọn fara balẹ ati pe ki wọn jina si ibi ti ibugbamu naa ti waye kawọn oṣiṣẹ adoola ẹmi le raye ṣiṣẹ wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Kini ileeṣẹ ọlọpaa lori ibugbamu ilu Ibadan?
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Olumiyiwa Adejobi ṣalaye loju opo X rẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ti le sọ ohun to ṣokunfa ibugbamu naa ni pato.
Bakan naa ni o tun sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko le sọ iye yan to farapa tabi to ku ninu iṣẹlẹ naa.
Adejobi ni awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ṣi n ba iṣẹ wọn lọ bayii.
Agbẹnusọ ọlọpaa ni kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kọwọọ rin pẹlu awọn lọga lọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa lọ sibi ti ibugbamu naa ti waye lati mọ ohun to ṣẹlẹ gan an.
Bakan naa lo sọ wi pe awọn ọlọpaa ti wa nibẹ lati rii pe awọn eeyan ko maa huwa to lodi sofin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5















