Àwọn jàndùkú kọlu ilé ìwòsàn l’Ekiti, wọ́n bá dúkìá jẹ́, jí òkú gbé

Abawọle EKSUT ati ọkan lara awọn ibi ti wọn kọlu

Awọn dokita atawọn oṣiṣẹ diẹ ninu awọn ẹka miiran niile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti ipinlẹ Ekiti ti fariga lori ikọlu to waye laarin awọn mọlẹbi alaisan to jẹ ipe Ọlọrun atawọn dokita ni ile iwosan naa.

Ija waye lẹyin ti awọn mọlẹbi to gbe oloogbe lọ ile iwosan fẹsun kan awọn dokita pe iwa ko kan mi ti awọn dokita naa wu lo ṣokunfa iku eeyan wọn.

A gbọ pe awọn ara ile oloogbe naa fariga, ti wọn si bẹrẹ si ba nnkan jẹ ninu ọgba ile iwosan naa, ti wọn si tun ṣe ikọlu si awọn oṣiṣẹ mii nibẹ, eyii to ki ọpọ ninu wọn.

EKSU

Oríṣun àwòrán, bbc

Aworan ikọlu to waye nile iwosan naa

Awọn Alakoso ati awọn dokita ile iwosan ọhun sọ wi pe awọn gbiyanju agbara awọn lati dola ẹmi ologbe ọhun amọ pabo ni gbogbo igbiyanju awọn ja si.

Ọkan lara awọn adari ile iwosan ọhun, Dokita Adeyemi ṣalaye pe awọn yoo fi ile iwosan ọhun silẹ fun akoko diẹ nitori awọn ni lati doola ẹmi awọn funra wọn nitori awọn to siṣẹ buruku yii tun le pada wa ati pe, gbogbo ohun ti wọn ti bajẹ ko tii ni atunṣe.

Aworan ikọlu to waye nile iwosan naa

Ninu atejade ti olori ile iwosan ọhun fi sita, awọn ko ni fi aye gba irfufẹ iwa buruku ti awọn mọlẹbi oloogbe naa wu mọ nibẹ.

Koyade Olabanji ẹni to jẹ olori ile iwosan naa tun fi kun ọrọ pe, awọn alakoso ile iwosan naa to awọn agbofinro leti.

Bakan naa ni awọn Ọlọpaa to wa ni agbagbe ọhunfi da awọn loju pe, awọn ti ṣetan lati fun wọn ni eto abo to gbeye lori ẹmi ati dukia ile iwosan naa.