Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo ti kéde ètò ìsìnkú Gómìnà tẹ́lẹ̀ Akeredolu?

Aworan Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, ROTIMIAKETI

Lati bii ọsẹ kan sẹyin ni awọn kan ti n pin iroyin kan loju opo atẹjiṣẹ WhatsApp eyi ti wọn pe ni alakalẹ eto isinku gomina ipinlẹ Ondo to papoda, Oluwarotimi Akeredolu.

Iroyin sọ pe ọjọ kẹtalelogun oṣu Keji ọdun yii ni Akeredolu yoo wọ kaa ilẹ sun.

Koda, ileeṣẹ iroyin ori ayelujara kan naa bawọn gbe pe alakalẹ naa wa latọwọ ijọba ipinlẹ Ondo.

Ninu ilana isinku ọhun, eto yoo bẹrẹ lati ilu Ibadan titi de ile ijọba nilu Akurẹ, ti yoo si pari si ilu Owo to jẹ ilu abinibi Akeredolu, nibi ti wọn pe isinku yoo ti waye.

Ẹwẹ, oniruuru awuyewuye lo ti jẹyọ lẹyin ti awọn kan fi alakalẹ naa lede.

Bi awọn kan ṣe n beere ẹni to fọwọ si alakalẹ naa, lawọn miran n beere ipa ti mọlẹbi oloogbe, ijọba ipinlẹ Ondo, to fi mọ awọn gomina ilẹ Yoruba to ku yoo ko ninu isinku ọhun.

Bẹẹ lawọn kan wi pe alakalẹ yii lo ti fa ija laarin gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa, ati akọwe ijọba ipinlẹ naa, Ọmọbabinrin Oladunni Odu.

Awọn agbọyisọyi naa wi pe Odu lo gbena woju Aiyedatiwa ninu ipade igbimọ iṣejọba ipinlẹ naa tori pe Aiyedatiwa ko fi orukọ akọwe ijọba ọun sinu igbimọ ti yoo ṣeto isinku naa.

Wọn ti lẹ tun fi kun pe eyi lo faa ti ijọba ko tii fi alakalẹ naa lede taara.

‘Mi o le yaju si Gomina Aiyedatiwa’

Ninu ọrọ lati fesi si itankalẹ ahesọ nipa aawọ oun ati gomina lori ọrọ alakalẹ isinku Akeredolu, akọwe ijọba ipinlẹ Ondo, Ọmọbabinrin Oladunni Odu wi pe irọ nla ni pe oun yaju si Aiyedatiwa.

Odu, ninu atẹjade to fi fesi sọrọ naa wi pe “ẹni ti ko ba mọ ohunkohun nipa iṣejọba nikan lo le maa bawọn sọ pe mo yaju si gomina.

“Mo ni ọwọ gidi fun ọfiisi gomina, ti eleyi si han gbangba.

Bakan naa ni mo bọwọ fun Gomina Aiyedatiwa to jẹ ‘arakunrin’ mi.

“Ki awọn to ba n gbiyanju lati da omi alaafia ipinlẹ Ondo ru o ranti ẹsan, ati pe awọn alalẹ ipinlẹ yii yoo kọju ija siru ẹni bẹẹ.”

Akọwe ijọba naa wa rọ Gomina Aiyedatiwa la ti wo saakun awọn ọmọ igbimọ iṣejọba rẹ lati lee mọ awọn agbọyisọyi to n sọ ohun ti ko ṣẹlẹ ninu ipade wọn ki wọn too ba iṣejọba rẹ jẹ.

A ko tii fi ilana isinku Akeredolu lede - Aiyedatiwa

Lati lee fi idi ọrọ mulẹ, BBC Yoruba kan si agbẹnusọ gomina ipinlẹ Ondo, Ọmọọba Ebenezer Adeniyan.

Adeniyan ṣalaye pe ijọba ipinlẹ naa ko tii kede ilana isinku gomina wọn tẹlẹ to papoda.

Agbẹnusọ gomina naa wi pe “ijọba ko fọwọ si alakalẹ ti wọn n pin kiri lori ayelujara”.

O fi kun un pe ijọba ipinlẹ naa yoo kede ilana isinku Amofin-agba Oluwarotimi Akeredolu lai pẹ.

Akeredolu to jẹ gomina ipinlẹ Ondo lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keji, ọdun 2017 dagbere faye ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2023 lẹyin ọpọ oṣu ti aisan jẹjẹrẹ ti ba a finra.

Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Akeredolu to d'oloogbe

Aworan Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, ROTIMIAKETI

Ko si ẹni to waye ti ko ni ku.

Akeredolu jade laye lẹyin aarẹ to ti ba finra fun igba diẹ.

Ohun ni Gomina ipinlẹ iwọ oorun Naijiria keji ti yoo ku lori oye.

Ninu itan oloṣelu Naijiria awọn eeyan ko ni gbagbe Rotimi Akeredolu to jẹ akọṣẹmọṣẹ agbẹjọro agba to si tun jẹ gbajugbaja oloṣelu ni Naijiria.

O fi iyawo ati awọn ọmọ silẹ lọ.

Ọdun 1956 ni wọn bi Oluwarotimi Odunayo Akeredolu to si jẹ ọmọ ilu Owo ni ipinlẹ Ondo.

Arakunrin ni inagijẹ rẹ ti ọpọ a maa fi pe paapa lagbo oṣelu ipinlẹ Ondo nibi to ti jẹ Gomina fun saa ẹmeeji ọtọọtọ.

Ile ẹkọ ibẹrẹ Government School lo ti bẹrẹ ẹkọ rẹ to si tẹsiwaju lati ibẹ lọ si St Aquinas College, Loyola College ni Ibadan ati Comprehensive High School Aiyetoro nibi to ti gba sabuke ile ẹkọ girama.

FasitiObafemi Awolowo ni Ile Ife lo ti kẹkọ nipa imọ ofin to sipari ẹkọ rẹ lọdun 1977.

Ọdun 1978 ni wọn pe si ẹgbẹ awọn agbẹjọro lorileede Naijiria.

Rotimi Akeredolu, agbẹjọro ati oloṣelu ilumọọka

Idi iṣẹ agbẹjọro yi lo ti di ilumọọka to si pada de ipo agbẹjọro agba iyẹn Senior Advocate of Nigeria,SAN lọdun 1998.

Laarin ọdun 2008-2010 o jẹ alaga ẹgbẹ awọn agbẹjọro Naijiria.

Lasiko to wa lori ipo yi lo sọrọ nipa ipo ilera aarẹ Naijiria tẹlẹ Umaru Musa Yar'Adua to si ni o yẹ ki Yar''Adua gbe ijọba kalẹ fun igbakeji rẹ tori pe ko le maa ṣe ijọba nipo ailera.

Ọrọ ṣiṣe ijọba niupo ailera yi yoo pada wa kan Akeredolu naa to kọ lati fi ipo silẹ fun igbakeji rẹ nigba ti aarẹ de kaṣan ara rẹ mọlẹ.

Lara ipo ti Akeredolu tun dimu nipa iṣẹ imọ ofin ni ti Agbẹjọro agba ati Kmiṣana feto idajọ ni ipinlẹ Ondo laarin ọdun 1997 si ọdun 1999.

Lọdun 2012, ẹgbẹ awọn agbẹjọro ṣe ayẹsi rẹ nipa fifi olu ileeṣẹ wọn lAbuja peri Akeredolu fun ipa ribi to ko nipa idagbasoke ọrọ imọ ofin ni Naijiiria.