Ọba Frederik X gorí oyè, ẹgbẹgbẹ̀rún èèyàn péjú síbi ayẹyẹ Ọba tuntun ní Denmark

Oríṣun àwòrán, Screenshot/BBC
Ogunlọgọ eeyan lo peju pesẹ si ibi iwuye Ọba Frederik Kẹwaa to gori itẹ awọn baba nla rẹ gẹgẹ ọba orilẹede Denmark.
Frederik rọpo iya rẹ lori itẹ ọhun eyi ti ẹgbẹẹgbẹrun peju sibẹ lati wo.
Nigba to n ba awọn eeyan sọrọ nibi ayẹyẹ naa, Ọba Frederik ti oju rẹ leroro fun omije sọ fawọn eeyan pe oun maa jẹ ọba ti yoo so awọn eeyan pọ fun ọjọ iwaju.
Bakan naa lo gboṣuba fun iya ẹni to fi ipo naa silẹ lẹyin to ti wa lori oye fun ọdun mejilelaadọta.
Iya rẹ ni ọba akọkọ ti yoo fipo ọba silẹ fun ra rẹ ninu itan orilẹede Denmark ni bii ẹgbẹrin ọdun bayii.
Bo tilẹ jẹ pe wọn o fẹ pariwo pẹlu eto ifinijoye ọhun, ọpọ eeyan lo peju siwaju Christiansborg Castle nibi ti eto naa ti waye lọjọ Aiku.
Igba mẹta ọtọtọ lawọn eeyan sọ pe ki Ọba Frederik pẹ lori oye nibi ayẹyẹ to waye ni aafin.
Ẹwẹ, Olootu ijọba Mette Frederiksen lo kede Frederik gẹgẹ bi Ọba Denmark, Greenland ati Faroe Islands.
Ọba Frederik Kẹwaa bawọn eeyan sọrọ

Oríṣun àwòrán, Screenshot/SHUTTERSTOCK
Nigba ti o n ba awọn eeyan sọrọ, Ọba Frederik sọ pe gbogbo ọjọ aye oun ni oun fi ṣe igbaradi lati jẹ
ọba ti yoo so awọn eeyan pọ fun ọjọ iwaju.
O ni pẹlu ayọ, ibọwọfun ati iwuri ni oun fi gba ipo ọba orilẹede Denmark.
Ọba Frederik ni iya oun ti di ẹni ti orukọ rẹ ko le parẹ mọ laelae ninu itan fun nkan nla ti o ṣe.
Niṣe ni Ọba Frederik n fi ọwọ nu oju nun bi o ti n sọrọ niwaju ọpọ eeyan.
Nibi ti o ti n sọrọ naa ni awọn ọmọ rẹ mẹrin ti darapọ mọ ọ to fi mọ Ọmọba Christian ọmọ ọdun mejidinlogun.
Ariwo sọ nigba ti Ọba Frederik ati iyawo rẹ, Ọbabinrin Mary to jẹ ọmọbibi orilẹede Australia fẹnu ko ara wọn lẹnu.
Ọpọ eeyan lo duro loju popo lati ṣe idagbere fun Ọbabinrin Margarerthe ẹni ọdun mẹtalelọgọrin to kede igbesẹ rẹ lati fi ipo ọba silẹ lori tẹlẹfisan lọjọ aisun ọdun.
Ọbabinrin Magareth ni oun gbe igbesẹ lati fipo naa silẹ latari iṣẹ abẹ ti oun ṣe lori ẹyin oun lọdun 2023.
Magarethe yoo si maa jẹ Ọbabinrin bo tilẹ jẹ pe o ti fi ipo naa silẹ.
Ọba Frederik ẹni ọdun marunlelaadọta ti di adari ile ọba ti o pẹ julọ nilẹ Yuroopu.
Ẹwẹ, Ọba Ilẹ Gẹẹsi, Charles ati iyawo rẹ, Camilla naa ti ranṣẹ ikini ko oriire si Ọba Denmark tuntun, bakan naa ni wọn ki Ọbabinrin Margarethe ku aṣeyọri rẹ.















