Àwọn ọmọ ẹgbẹ̀ òkùnkùn kọ lẹ́tà sáwọn ọba ní ìpìnlẹ́ Ogun

Aworan ipinlẹ Ogun
Àkọlé àwòrán, Ogun

Ẹgbẹ okunkun meji, ’Neo Black Movement’ tawọn eeyan mọ si Aiye ati National Association of Airlords ti wọn tun n pe ni Ẹiyẹ Confraternity, ẹka ti ipinlẹ Ogun ni wọn ti kọ lẹta si Akarigbo Ilẹ Rẹmọ, Ọba Adewale Ajayi, atawọn ọba alaye kan nipinlẹ Ogun bayii.

Ninu lẹta naa ti ẹda rẹ tẹ BBC lọwọ ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti tọrọ aforiji lọwọ Akarigbo.

Wọn ni ki Kabiyesi ba awọn bẹ awọn ọba alaye yooku ni ilu Rẹmọ lorii rogbodiyan tawọn n da silẹ ni Ṣagamu ati agbegbe rẹ.

Ọjọ kejilelogun oṣu kejila ọdun 2023 lo wa lorii lẹta awọn Ẹiyẹ, nigba ti wọn kọ ti awọn Aiye lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kejila ọdun to kọja kan naa.

‘A n tọrọ aforiji lọwọ ẹyin baba wa, ọmọde ki i j’ẹkọ ko ma ra a lọwọ’

Leta Egbe okunkun
Leta egbe okunkun

Ninu lẹta ẹgbẹ mejeeji ti wọn buwọ lu ni wọn ti ṣalaye, pe ọmọde lo n ṣe awọn.

Wọn i ko si bi ọmọde yoo ṣe jẹkọ ti ko ni i ra a lọwọ.

‘’A n bẹ yin pe kẹ ẹ foriji wa fun gbogbo awọn aṣiṣe wa to ti ṣẹlẹ sẹyin. A n ṣeleri fun yin bayii pe ko ni i ṣẹlẹ mọ. A ti tọwọ ọmọ wa bọ aṣọ.’’

Tẹ o ba gbagbe, ipaniyan ati rogbodiyan oriṣiriiṣii lo ti n ṣẹlẹ ni Ṣagamu ati agbegbe rẹ fun igba pipẹ, igbesẹ ijọba Ogun lati kapa rẹ lo si fa a ti awọn ẹṣọ alaabo bii ọlọpaa, fijilante, Amọtẹkun, NSCDS ti i ṣe ẹṣọ aabo ara ẹni laabo ilu, ṣe n ṣiṣẹ pọ lati ṣẹgun awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n da ilu laamu naa.