Ìjàm̀bá ọkọ̀ tírélà gbẹ̀mí ọlọ́kadà kan, ènìyàn márùn-ún míì farapa

Awon osise FRSC nibi ijamba oko naa

Oríṣun àwòrán, FRSC

Arakunrin kan ti ẹnikẹni ko tii mọ orukọ rẹ ni o ti pade iku ojiji ninu ijamba ọkọ to waye ni oríta ti o wọ ilu ilẹ Oluji ni ipinlẹ Ondo.

Gẹgẹ bi BBC YORUBA ṣe gbọ, ijamba ọkọ naa lo waye ni owurọ ọjọ Jimoh ọjọ Kejìlá oṣù Kiini ọdun 2024 ni agbegbe t'ọpọ eeyan mọ si "itanla" láàrin ilu Ondo si Ilẹ oluji.

Awọn oṣoju mi koro sọ pe awakọ tirela kan ni o kùnà lati ṣe idari ọkọ re ko to di pe o lọ kọlù arakunrin kan to n wa okada ti o si jade laye loju ẹsẹ.

Tirela ati okada ninu ijamba oko

Oríṣun àwòrán, FRSC

Ọkọ tirela, okada méjì ati ọkọ ayọkẹlẹ kan ni ijamba ọhun ṣe àkóbá fún.

Awọn eeyan marun-un lo f'arapa ti wọn sì ti di ero ile iwosan.

Ijamba ọkọ naa fà sunkẹrẹ fakẹrẹ ni opopona to wọ ilu Ondo ati ilẹ Oluji.

Awon oṣiṣẹ FRSC ti ilu Ondo wa ni oriko iṣẹlẹ na ti won sì ti gbè oku ọlọkada ti ijamba naa gbẹmi rẹ lọ si ile ti wọn maa n gbe oku si.