TAMPAN máa ṣe ohun mánigbàgbé lórúkọ Olóògbé Olofa Ina - Latin

Oríṣun àwòrán, Latin/INSTAGRAM
Aarẹ ẹgbẹ awọn onitiata, TAMPAN, Bolaji Amusan ẹni ti gbogbo eeyan mọ sí Mr Latin ti sọ pe ẹgbẹ oṣere tiata lapapọ maa ṣe nnkan mánigbagbe lorukọ Oloogbe Adedeji Aderemi, ti ọpọ mọ si Olofa Ina.
Latin to sọ eyi níbi àdúrà ọjọ́ mẹjọ tó wà ní ìlú Ede, ìpínlẹ̀ Osun juwe oloogbe naa bí ẹni tó ní ìwà tó dara pupọ, to si kopa ribiribi ninu iṣẹ tiata.
Níbẹ̀ ni Mr Latin tun ti rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ òṣèré tiata lapapọ lati ni inu kan naa ati ero kan fun idagbasoke ẹgbẹ naa.
Awọn èèkàn nínú ẹgbẹ́ òṣèré tíátà ló peju pesẹ si ilu Ede láti ṣe ẹyẹ ìkẹyìn fún Olofa Ina to dagbere faye ni ọjọ Kẹrin oṣù Kìíní ọdún 2024.


Lara awọn agba òṣèré tó bá BBC News Yoruba sọrọ nípa olóògbé Olofa Ina ni Samson Eluwole ẹni tí gbogbo eeyan mọ sí Jinadu Ewele.
Jinadu Elewe ṣe apejuwe Olofa ina gẹgẹ bii opo pataki lawujọ òṣèré tiata Yoruba.
"Ka to le ri erin odigbo, eyi to tumọ si pe ka to le ri eeyan bii Oloogbe Olofa Ina ninu ẹgbẹ òṣèré tiata yoo lagbara."
Jinadu Ewele tun sọ pe, oloogbe Olofa Ina jẹ ọlọpọlọ pipe, oloye eeyan, olukọtan ọgbọn àti onisuuru eeyan lawujo òṣèré tiata.
Ọjọgbọn Siyan Oyeweso sọrọ nipa Oloogbe Olofa Ina, pe oloogbe Olofa Ina jẹ ọmọluabi eeyan ati olufẹ ilu Ede.
Ọjọgbọn Siyan Oyeweso tun sọ pe, ki wọn to le fi eeyan jẹ oye ninu ilu, iru eeyan bẹẹ ni lati jẹ ẹni rere.
O kọminú pé nǹkan ńlá lo sọnù ni ilu Ede bí àwọn ṣe pàdánù Olofa Ina nitori ó ṣeéṣe kí àwọn má ríi eeyan bii Olofa Ina lagbo òṣèré tiata tí yóò jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ede.
Ninu waasi rẹ, Alhaji Abdullahi Olorunlomoeruẹ rọ awọn ẹgbẹ òṣèré tiata lati ṣe ara wọn lọkan gidigidi.
Alhaji Olorunlomoeruẹ tun rọ wọn lati jawọ ninu iwa to le mu abuku ba iṣẹ wọn ati awọn iwa to le ṣàkóbá fun ẹni kọ̀ọ̀kan wọn bíi a n gbẹ ara ẹni lẹ́sẹ̀.
Alfa náà tun ṣèkìlọ̀ fún awọn ọmọ Oloogbe láti ṣe ara wọn lọkan ki orúkọ rere ti Baba Olofa Ina ti fi silẹ ko ma bajẹ lẹ́yìn ikú bàbá wọn.
Òní ni àdúrà ọjọ́ kẹjọ Fidau Baba Olofa Ina yóò wáyé

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Oni, ọjọ kejila, oṣu Kini, ọdun 2024 ni adura ọjọ kẹjọ, Fidau, yoo waye fun agba oṣere tiata Yoruba to di oloogbe, Adedeji Aderemi, ti ọpọ mọ si Olofa Ina.
Ṣaaju ni awọn mọlebi oloogbe naa ti kọkọ sìn oku rẹ ni ilana ẹsin Musulumi.
Alẹ Ọjọbọ, ọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2024, ni iroyin jade pe agba oṣere, Oloye Adedeji Aderẹmi ti ọpọ mọ si Ọlọfa ina ti jade laye.
Eni odun metalelaadorin ni agba òoṣere naa ki ọlọjọ to de.
BBC Yoruba ti lọ sile oloogbe, nibi ti akọroyin wa ti ba awọn ẹbi rẹ sọrọ
Ọkan lara awọn iyawo oloogbe Aderemi to ba BBC sọrọ, Arabinrin Modinatu Aderemi, to tun jẹ iyawo kekere sọ pe ni nnkan bi aago meje aabọ alẹ Ọjọbọ ni ọkọ oun dakẹ.
Wọn bi Adedeji Aderemi ni ọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 1950, ni agboole Jagun-Olukosi niluu Ede, nipinlẹ Osun.
Baba Olofa Ina lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ St. Peters Anglican Primary School.
Lẹyin naa lo lọ si ile ẹkọ girama Baptist Modern Secondary School.
Ṣaaju ko to o di oṣere, o kọ iṣẹ gbẹnagbẹna, ti wọn n pe ni Carpentry ni ede Gẹẹssi lọdun 1965 si 1970.
Awọn ere ti Olofa Ina ṣe nigba aye ree
I Omode
Idaamu Otunba
Ewe Orun
Kabiyesi Olodumare
Mayegun, Ejo Ngboro
Lisabi Agbongbo Akala, ati awọn mii.












