Ajagunfẹ̀yìntì tó yìnbọn pa ọmọdé padà yìnbọn pa ará rẹ̀ lẹ́yìn ọdún márún ùn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arakunrin ọmọ ogun kan to ṣeṣi yinbọn pa ọmọ kekere kan lasiko to wa lẹnu iṣẹ ni iyawo rẹ ti sọ pe o yinbọn gba ẹmi ara rẹ lẹyin ọdun marun un to fi duro de itọju.
George Du Preez to jẹ ọmọ ogun to kopa ni Afghanistan ni aisan iporuru ọkan taa mọ si PTSD de ba leyin iṣẹlẹ to ti yinbọn pa ọmọde ni ọdun 2011.
Iyawo rẹ, Katriona sọ pe ko mọ pe oun n yinbọn mọ ọmọde naa nigba to fi ṣẹlẹ.
Ajọ ileeṣẹ ìlera Cwm Taf Morgannwg sọ pe awọn ni ifarajin lati ṣe iranwọ fawọn ajagunfẹyinti to ba ni ipenija aarun ọpọlọ.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ologun sọ pe awọn ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ ilera awọn oṣiṣẹ awọn ṣugbọn wọn lawọn ko ni tu iṣu de isalẹ koko lori ọrọ oṣiṣẹ wọn
Orileede Namibia ni wọn ti bi Ọgbẹni Du Preez to si pada darapọ̀ mọ ìkọ ologun ilẹ Gẹẹsi to ba ṣiṣẹ ni Afghanistan.
Arabinrin Du Preez sọ pe oun gba ipe lati ọdọ ọkọ rẹ ní oṣu keji, ọdun 2011 nibi to ti beere pe ṣe Ọlọrun yoo forijin ẹni to ba sẹkupa ọmọde.
" Mo ro pe awọn Taliban lo n sọ nipa wọn ti mi o si sẹnu ku lati ṣọ pe iwa to buru ni"
Amọ nigba ti ọkọ rẹ pada de, ọrọ pọ to tun sọ.
" Aṣe nigba ti wọn pa George lasẹ lati yinbọn lu eeyan kan, iroyin wa lati ọdọ awọn ọga rẹ wí pe ọmọde lo yinbọn lu."
Bayi ni iyawo rẹ ṣẹ salaye.
O ni ohun tó ṣokunfa iporuru ọkan to de ba ọkọ oun ree.

Oríṣun àwòrán, Katriona Du Preez
O gba itọju nile iwosan awọn ologun ati ti araalu nigba to n gbe ni Colchester Essex níbi tí awọn ìkọ rẹ tẹdo sí.
Lọdun 2014 ni wọn kọwe pe ko kuro lẹnu iṣẹ tori ipenija àìlera to ni nípa iporuru ọkan.
Tọkọtaya yi ati ọmọ wọn okunrin kekere ko lọ sí Bridgend ni guusu Wales ki wọn baa le wa ni itosi mọlẹbi arabinrin Du Preez.
Níbẹ ni wọn ti sọ fun wọn pe wọn yoo gbe eto itọju rẹ lọ si ọdọ awọn akọṣẹmọṣẹ onimọ itọju ilera ọpọlọ.
Amọ eleyi ko pada ṣẹlẹ gẹgẹ bi arabinrin Du Preez ẹni ọdun mejilelogoji ṣe sọ.
O ni wọn ko tete da ọkọ oun loun nigba to de Wales.
"Eeyan daadaa to ni itiju to si tun pataki ẹsin lo jẹ"
"O koju ipenija ko maa ri awọn nkan to n mu eru ba ọkan rẹ pupọ."

Oríṣun àwòrán, JOE WYNDHAM
Ko pẹ si asiko yi ni iyawo arakunrin Du Preez ba oku rẹ ni oṣu Kọkanla, ọdun 2019.
Iyawo rẹ sọ pe o ṣi n duro de igba tí yoo ribi gba itọju ni o gba ẹmi ara rẹ.
O ni ajọ ilera Cwm Taf Morgannwg ko ṣe alaye kankan lori nkan to fa ti wọn fi ni lati bẹrẹ itọju rẹ lati ìbẹrẹ pẹpẹ nigba to pada de Wales.












