Ọmọ ológun yìnbọn pa mínístà kan, ló bá tún gbẹ̀mí ara rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Alamy
Ọmọ ogun Orilẹede Uganda kan ti yinbon pa ọga rẹ to tun jẹ minisita,eyi ti oun ṣọ paa.
Ọgagu fẹyinti Charles Okello Engola to jẹ minisita fun iṣẹ,ninu ile rẹ ni Kyanja.
Ko si aridaju boya ariyanjiyan wa laarin ọmọ ologun naa ati Ọgagun Engola ko to doju ibọn kọ ara rẹ,awọn ti ọrọ ọhun soju wọn ni ọmọ iṣẹ ologun naa ti ṣaaju rin inu ọgba ile ọhun kaa ko to beeresi ni yinbon soke.
Ọga agba ile isẹ ọlọpaa agbegbe ti isẹlẹ naa ti waye ti fi orukọ ọmọ iṣẹ ologun naa lede gẹgẹ bi Wilson Sabiti o tun fihan wi pe iwadii ni kikun ti bẹrẹ lori isẹlẹ naa.
Agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa ni ẹsọ alabo ọhun yin ọpọlọpọ ibọn mo ọga rẹ nigba ti oun gbiyanju lati wọ inu ọkọ ijọba rẹ ti o si padanu ẹmi rẹ lẹsẹkẹsẹ.
Afurasi oun na tun yinbọn mo ọga ẹsọ alabo to n sọ minisita oun L.t Ronald Otim saaju ko to sare wo inu ọja to si yinbọ pa ara rẹ .
Ile iṣẹ ọlọpaa ni idi ti ọmọ ogun naa fi wu iwa buruku ohun ko ti ye ẹnikankan.











