Wo ohun tí àwọn ọmọ Naijiria ń sọ lẹ́yìn ìdájọ́ Ike Ekweremadu àti ìyàwó rẹ̀

Lẹyin ti ile ẹjọ ilẹ Gẹẹsi kan sọ igbakeji aarẹ tẹlẹ ni ile igbimọ aṣofin agba ni Naijiria, Ike Ekweremadu lọ si ẹwọn ọdun mẹsan an ati oṣu mẹjọ fun lilo ẹya ara eeyan lọna ti ko tọ, ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n sọ eronghba wọn lẹyin idajọ naa.
Lapa kan, awọn eyan n da Sẹnetọ naa lẹbi pe ọrọ ki ba ti ma ri bayii fun un to ba jẹ pe o ṣagbekalẹ ile iwosan to dara si Naijiria.
Lapa keji ẹwẹ, awọn mii tun n sọ pe abiyamọ daadaa ni Sẹnetọ ọhun ati iyawo rẹ ti wọn lo gbogbo ọna lati ṣetọju ọmọ wọn to n ni arun kidinrin.
Ohun ti awọn eeyan n sọ ree
Lẹyin ifọrọwerọ BBC pẹlu ọmọ Sẹnetọ naa to n ṣaisan, @Adedokun Hammight Growmind sọ pe
“Awọn obi rẹ lo ṣokunfa wahala yii, o yẹ ki wọn gba ọna to ba ofin mu...
mo lero pe awọn oloṣelu atawọn ọlọrọ ni Naijiria yoo kẹkọọ nla lara iṣẹlẹ yii.”
@Dawood Adeniyi Horlarlekan ni:
“Ohun kan to mu inu mi dun nipa idajọ yi ni pe ilẹ okeere lo ti waye
bi bẹẹ kọ... hmmm.”

@Goke's Scuizzy Aia sọ pe
“Ṣe ẹ ri ile aye, wọn ko le kọ ile iwosan to dara si orilẹ-ede yii, amọ wọn le lo owo wọn lati ran ara wọn lẹwọn.”
@Ezekiel Oluwafemi Adeniji ni:
“Ọrọ yii gbomi loju mi, amọ bi aye ṣe ri niyẹn, owo kọ ni gbogbo nnkan...
aisan ti ko gboogun ko ni jẹ ti gbogbo wa lorukọ Jesu.”

Ni ti @Azeez Peter Kola, o ni:
“Ibinu Ọlọrun ti balẹ sori idile wọn, akoko si ti to fun wọn lati ko ere iṣẹ ọwọ wọn, amọ ti Ọlọrun ba fẹ, yoo boju aanu wo wọn.
Ẹkọ to wa nibi iṣẹlẹ yii ni pe ki a maa ṣe rere nibikibi ti a ba wa.”
@Gbola Oladejo sọ pe:
“Ko si ẹni ti ko le ṣe iru aṣiṣe bayii nitoti ọmọ ẹni.

Awọn ohun mii tawọn eeyan n sọ ree.



Ilé ẹjọ́ ti rán Sẹ́nétọ̀ Ike Ekweremadu lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́sàn án fún lílo ẹ̀yà ara ènìyàn lọ́nà tí kò bófin mu

Oríṣun àwòrán, met police
Ileẹjọ kan ni orilẹede UK ti ran igbakeji aarẹ tẹlẹ ni ile igbimọ aṣofin agba ni Naijiria, Ike Ekweremadu lọ si ẹwọn ọdun mẹsan an ati oṣu mẹjọ fun lilo ẹya ara eeyan lọna ti ko tọ.
Bakan naa ni ile ẹjọ tun ran iyawo rẹ, Beatrice lọ si ẹwọn ọdun mẹrin ati oṣu mẹfa.
Dokita to ran wọn lọwọ, gẹgẹ bi alarinna ninu ọrọ naa pẹlu gba idajọ ẹwọn ọdun mẹwaa, bẹẹni wọn si tun gbẹsẹ le iwe ẹri rẹ gẹgẹ bi oniṣegun oyinbo.
Ile ẹjọ kede idajọ fun Sẹnetọ Ekweremadu ati iyawo rẹ ati Obeta ni ọjọ Ẹti lẹyin to ti kọkọ da wọn lẹbi ni oṣu kẹta ọdun 2023 lori ẹsun lilo ẹya ara eniyan lẹyin ti wọn gbe ọdọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan wọ orilẹede UK lati ilu Eko lati le e lo kidinrin rẹ kan fi rọpo ti ọmọ wọn to ni aisan kidinrin.
Ile ẹjọ ni ẹtan ni Ekweremadu, iyawo rẹ ati dokita wọn fi tan ọmọdekunrin naa wa si ilẹ UK

Oríṣun àwòrán, Ekweremadu/Fcaebook
Ile ẹjọ naa sọ pe Sẹnetọ Ekweremadu, ẹni ọgọta ọdun, iyawo rẹ to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ati dokita Obinna Obeta to jẹ ẹni aadọta ọdun yoo fi aṣọ penpe roko ọba nitori pe wọn jẹbi gbigbimọ pọ lati fi ẹtan gba kidinrin arakunrin naa lara rẹ, eyi si ni akọkọ iru ẹ labẹ ofin to tako owo ẹrun igbalode ti wọn ṣẹṣẹ fidi rẹ sọlẹ lorilẹede naa.
Awọn alaṣẹ orilẹede UK sọ pe awọn mẹtẹta yii fi ẹtan gbe arakunrin naa kuro ni ilu Eko lorilẹede Naijiria lọ si orilẹede UK lọdun to kọja lati lo kidinrin rẹ ni ile iwosan kan ni ilu London.
Awọn ọlọpaa to pẹjọ naa sọ pe Ekweremadu gba lati san ẹgbẹrun meje pọun fun ọdọkunrin naa pẹlu ileri ati fun un ni igbe aye irọrun lorilẹede UK ati pe igba ti ọmọkunrin naa de ọdọ dokita ni ile iwosan naa lo to mọ ohun to n lọ ati pe kindinrin oun ni wọn fẹ lo.
Ọmọbinrin Sẹnetọ Ekweremadu ti orukọ rẹ n jẹ Sonia, ẹni ọdun marundinlọgbọn, ni wọn fẹ lo kindinrin naa fun.
Ile ẹjọ ni ọmọbinrin naa ko ni ẹṣẹ kankan nipa ti ẹjọ ọhun.
Ẹ fojú àánú wo Ekweremadu, ó tí kọ́ ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ìgbẹ́jọ́ yii-Ilé ìgbìmò aṣofin
Bi igbẹjọ Ike Ekweremadu, ẹniti o ti fi igba kan ri jẹ igbakeji adari ile igbimọ asofin Orilẹede yii lori ẹsun rira ẹya ara eeyan ti fẹ waye lọjọ ẹti ọsẹ yii.
Ile igbimọ asoju sofin ti rawọ ẹbẹ si ẹka to risi ọrọ idajọ ni United Kingdom lati siiju aanu wo,Ike Ekweremadu ati iyawo rẹ Beatrice.
Sẹnetọ Ike Ekweremadu to jẹ ẹni ọdun ọgọta, iyawo rẹ Beatrice to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ati Dokita Obinna Obeta toun naa jẹ aadọta ọdun ni ile ẹjọ ilẹ United Kingdom ti da lẹbi pe lootọ wọn jẹbi gbigbimọ pọ lati yọ ẹya ara arakunrin kan ti wọn mu lọ London lati ipinlẹ Eko ni Naijiria.
Ẹbẹ ohun lo waye lẹyin ti igbakeji ọmọ ile to kere julọ Toby Okechukwun gbe aba naa wa sile igbimọ asofin ninu ijoko ile to waye lana.
Ike Ekweremadu ti kọ ẹkọ bayii...Toby Okechukwu
Awọn asofin naa rọ akọwe ile igbimọ asofin lati ko we ransẹ si asoju ilu Ọba orilẹede yii ati ile igbimọ asofin ilu Ọba.
Okechukwu ẹniti o gbe aba naa wa ni Sẹneto Ike Ikweremadu gbe igbesẹ to gbe nitori ko m a ohun ti ofin ilu Ọba sọ nipa irufẹ igbese to gbe,nitori bayi o ti kọ ẹkọ bayii.
Idajọ Ike Ekweremadu,iyawo rẹ Beatrice ni yo waye lọjọ karun,osu karun,ọdun yii.
Ninu ọrọ rẹ Okechukwu ni, “Sẹnẹtọ Ike Ekweremadu wuwu gẹgẹ bi o ti ni oye ofin ile Geesi,o ni Sẹnẹtọ oun kọ we si ile ijọba ilẹ Gẹẹsi lori ohun to fẹ se saaju ki o to gbe igbesẹ.
Ile igbimo asaọfin rọ ijọba ilẹ Gẹẹsi lati wo ibasepọ to ni pẹlu Orilẹede Naijiria ki wọn si tẹ jẹjẹ pẹlu Ike Ekweremadu.















