Ẹnikẹ́ni tí ọwó bá tẹ̀ tó ń ṣe àdó olóró yóò fi ẹ̀wọ̀n gbére jura- Ilé Ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní Naijiria

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile igbimọ aṣofin agba ni Naijiria ti buwọlu abadofin to ni ẹwọn gbere ni ki wọn fun awọn ti ọwọ ba tẹ ti wọn se ado oloro ni Naijiria.

Ile Igbimọ aṣofin ni ko ni si aaye fun gbigba owo itanran awọn ti wọn ba n se iṣẹ rirọ ado oloro ni orilẹede Naijiria.

Abadofin naa ni wọn buwọlu ni Ọjọru lẹyin ti igbimọ ile asofin lori ohun alumọni ati irin ni Naijiria se ayẹwo rẹ finifini.

Awọn asofin naa ni awọn ọdaran ti wọn n lo ẹrọ igbalode lati se ohun elo ibugbamu ti pọsi lorilẹede Naijiria.

Bakan naa ni wọn fikun un pe ọpọlọpọ awọn agbesunmọmi lo n lo ado oloro lati pa awọn ọmọ Naijiria ni ọgọọrọ.

Ohun to kan ni ki awọn aṣofin naa sọrọ nipa abadofin naa ki wọn to fi ṣọwọ si ileeṣẹ aarẹ lati buwọlu.

Awọn asofin naa ni chemical ni awọn agbesunmọmi naa nlo ni ọpọ igba lati se ado oloro naa.

Ikọ Boko Haram ti fi ado oloro ṣọsẹ ni iha ariwa orilẹede Naijiria, ti wọn si ti gba ẹmi ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan.

Bakan naa ni awọn ajinigbe ati awọn agbebọn ti fi ohun ija ṣọsẹ lasiko ti wọn ba sekọlu si ọkọ tabi ohun irinsẹ lati ji awọn eniyan gbe lorilẹede naa.

Ko tan sibẹ, awọn ikọ agbebọn ni ilẹ ẹya Igbo lorilẹede Naijiria naa ti lo ado oloro lati sekọlu si awọn ileeṣẹ ijọba to fi mọ awọn agọ ọlọpaa.

Eleyii si ti fa ipaya fun awọn araalu, ti ọpọlọpọ ẹmi ati dukia si ti ba awọn iṣẹlẹ yii lọ.