Àyẹ̀wọ fihàn pé wọn fún awọn tó kú ní ṣọ́ọ̀ṣ̀ì lọ́rùn pa ni

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ayẹwo oku ti wọn se ti fihan pe nise ni wọn fun ọrun awọn to ku pa ni lorilẹede Kenya.

Dokita Johansen to jẹ onimọ ayẹwo oku ti ijọba Kenya ni ayewo ni wọn pa awọn eniyan naa ni nipa fifun wọn lọrun pa, wọn tun se eemi wọn ti wọn si tun lu awọn miran pa ninu wọn.

Ijọba ni wọn se ayẹwo awọn oku ti wọn gbe jade ninu igbo aginju naa to niise pẹlu awọn Kristẹni to wa ninu ẹgbẹ okunkun nibẹ.

Ẹsun ti wọn fi kan adari ti wọn fi panpẹ ọlọpaa mu nitori oun lo ni ilẹ ti wọn ti ri awọn oku naa ni pe o pasẹ fun awọn ọmọlẹyin rẹ pe ki wọn fi ebi pa ara wọn de oju iku.

Ileesẹ ọlọpaa ni orukọ adari wọn ti wọn fi panpẹ mu ni Paul Mackenzie Nthenge fun ọjọ mẹta.

Ijọba fẹ ki wọn gbelọ si ileẹjọ ki o ro ti ẹnu rẹ to fi mọ awọn ti wọn jọ wapọ lori ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ naa ni ileẹjọ.

Lara ẹsun ti wọn fi kan wọn ni iwa igbesunmọmi ati lilu owo ilu ni ponpo.

Kini iwadii oku naa safihan lori iṣẹlẹ naa

O kere tan idaji awọn oku ti wọn fayọ ninu igbo Shakahola ni wọn ti fi esi rẹ jade

Wọn ni iwadii oku to le ni ọgbọn ti wọn se safihan pe wọn fun awọn agbalagba meji ni ọrun pa ni, ti wọn si da eemi ọmọ kekere duro.

Awọn ọmọ miran ti wọn lu nkan mọ, ti wọn si fun ọrun awọn ọmọde mẹta.

Wọn ni mẹfa ninu oku naa ti jẹa to bẹẹ ti wọn ko lee sọ pato ohun to ṣẹlẹ si wọn.

Dokita onimọ nipa ayẹwo oku naa ni wẹrẹ ti wọn ba ti pari ayẹwo oku 110 to wa lọ wọn ni wọn yoo bẹrẹ si ni se ayẹwọ awọn miran ti wọn yoo fayọ.

Ọjọ Kẹtala, Osu Kẹrin, ọdun 2023 ni ikọ ọlọpaa ri oku awọn eniyan mẹrin kan, ti mejila si w ani ileewosan ni Kenya, ko to dipe ọlọpaa sawari wọn.

Awọn ti wọn sawari naa ni wọn ti wa ninu igbo fun ọjọ pipẹ lai jẹun nitori ki wọn ba le pade Jesu, olugbala wọn.