Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo fòfin dé lílọ-bíbọ̀ ọ̀kadà kọjá ago mẹ́wàá alẹ́

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn ọlọkọda ko ni lanfani lati ṣiṣẹ tayọ aago mẹwaa alẹ mọ n'ipinlẹ Ọyọ nipasẹ aba kan to di ofin nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ lọjọ Iṣẹgun
Atunṣe ofin ọdun 2019 to n ṣe akoso lilo ọkada naa ṣe agbekalẹ ẹgbẹrun marun un si mẹẹdogun Naira gẹgẹ bii owo itanran fun ọlọkada ti wọn ba gbamu wi pe o n rufin nipa ṣiṣe iṣẹ tayọ aago mẹwaa alẹ.
Alaga igbimọ ile to n ri si iṣẹ ode ati igbokegbodo, Họnọrebu Olatunde Kehinde ṣe alaye wi pe erongba agbekale ofin naa ni lati mu adinku ba lilo ọkada ati alupupu aladani fun iwa ọdaran.
Lara awọn alakalẹ ofin naa ni wi pe gbogbo ọlọkada gbudọ fi orukọ silẹ ni ẹka ileeṣẹ ijọba to n mojuto iṣẹ ode ati igbokegbodo laarin oṣu mẹfa ti ofin naa gbinaya, ki wọn si gba kaadi idanimọ.
Ọlọkada ti o ba kuna lati ṣe iforukọsilẹ gẹgẹ bi ofin ṣe sọ yoo jẹbi ẹsun ti yoo mu ki o san ẹgbẹrun marun un Naira tabi ki o fi ẹwọn oṣu kan jura.
Igun ikẹfa Ofin naa ti o jẹ imugbooro ofin to n ṣe akoso lilo alupupu fun ọdun 1995 tun tọka awọn ijiya mii fun ẹnikẹni ti o ba rufin iwakuwa ọkada.
Ẹni ti wọn ba gbamu wi pe o n wa iwakuwa yoo san ẹgbẹrun mẹwaa Naira gẹgẹ bii owo itanran tabi ki o lọ naju ni ọgba ẹwọn fun ọdun meji gbako.
Siwaju sii, igun ikeje ofin naa tọka rẹ wi pe ẹnikẹni ti o ba ṣe iku pa ẹlomii nipasẹ iwakuwa ọkada yoo san owo itanran ti o jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira tabi ki o fi ẹwọn ọdun marun jura.















