Awakọ̀ bọ́ọ̀sì BRT tó kọlu reluwé l’Eko fojú ba ilé ẹjọ́, ohun tó sọ rèé...

Aworan ijamba naa

Oríṣun àwòrán, lasema

Awakọ bọọsi akero BRT ijba ipinlẹ Eko to wa ọkọ kọlu reluwe lagbegbe Ikẹja nilu Eko loṣu ta ti foju ba ile ẹjọ lọjọ Iṣẹgun.

Ijọba ipinlẹ Eko wọ awakọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Oṣibanjọ Oluwaseun lọ si ile ẹjọ giga to wa ni Ikẹja labẹ onidajọ Oyindamọla Ọgala.

Ẹsun mẹrindinlogun to nii ṣe pẹlu ipaniyan laimọọmọ ati ṣiṣe eeyan ni jamba ni wọn fi kan an.

Adari ẹka ipẹjọ ijba, DPP ni ipinlẹ Eko, Babajide Martins fi to ile ẹjọ naa leti pe awakọ bọọsi BRT naa fi aibikita pa awọn eeyan inu kọ naa pẹlu bi o ṣe kọ eti ikun si awọn ami ikilọ gbogbo ti wọn gbe kalẹ fun un to si ṣe bẹẹ lọ kọlu ọkọ reluwe to n bọ loju opo rẹ.

Bakan naa lo ni olujẹjọ naatun fi aibikita rẹ ko awọn eeyan mẹwaa miran ninu bọọsi naa sinu ewu.

Eeyan mẹfa lo ku nigba ti bọọsi BRT naa kọlu reluwe l'Eko

Awọn kan lara awọn to farakaasa ijamba bọọsi BRT naa n gba itọju ni ileewosan nla LASU

Oríṣun àwòrán, LASG

Ni owurọ ọjọ kẹsan an oṣu kẹta ọdun 2023 ni iroyin jade pe ọkọ bọọsi akero BRT kan to n ko awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko kan lọ si ibi iṣẹ ti kọlu reluwe kan to n rin loju opo rẹ lagbegbe Ikẹja ni ipinlẹ Eko.

Eeyan mẹfa ni iṣẹlẹ naa ran lọ si ọrun ti ọpọ miran si fi ara pa.

Awakọ bọọsi naa, Oluwaseun sọ fun ile ẹjọ naa pe oun ko jẹbi eyikeyi ninu ẹsun mẹrindinlogun ti wọn fi kan oun naa.

Ile ẹjọ sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu karun un, ọjọ kẹrindinlogun ati ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹfa fun igbẹjọ naa.