Network kò sálọ bí aláwàdà Màmá 'No Network' ti sé ìgbéyàwó bòńkẹ́lẹ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, ScreenGrab

Gbajugbaja adẹrinpaosonu Kudirat Abolore ti gbogbo aye mọ si Mama no Network ti se igbeyawo gbonkẹlẹ pẹlu ololufẹ rẹ .

Adẹrinposonu oun lo fi iroyin ayọ naa lede lori itakun ayelujara Instagram,nibiti o ti fi faran oun ati ọkọ rẹ lede.

Ninu fọnran to fi sita lori ikanni ayelujara rẹ ni Kudirat Abolore ni:

“Ti eeyan kan ba fẹ o pẹlu gbogbo ọkan rẹ yo fun o ni agbara ,bẹ gẹgẹ ni ti o ba fẹran eeyan kan yoo mu ki ifẹ rẹ bo ọ”.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screengrab

Lara awọn alabasiṣẹpọ Kudirat ati awọn ololufẹ ni wọn ti ki ku orire lẹyin ti o ti fi faran naa lede.

Lara awọn to ki ku orire ni Kemi Korede,Madam Saje,Gaaji ti awọn ololufẹ adẹrinposonu oun ba yọ ayọ igbeyawo .

Ṣaaju ni ọkọ rẹ tuntun ti ki fun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to waye lọjọ die sẹyin.