Ọkùnrin kan pokùnso l'Eko, àwọn oníṣẹ̀ṣe ṣètùtù rẹ̀

igbo naa

Oríṣun àwòrán, other

Wọn ti ri oku arakunrin kan to pokunso lagbegbe NEPA Junction ni ilu Agboroko ni ipinlẹ Eko.

Iroyin sọ pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ mọkaliki atọkọṣe to wa nitosi ibi ti iṣẹlẹ laabi yii ti ṣẹ lo ri oku arakunrin naa nigba to wọle si ẹnu iṣẹ ni owurọ ọjọ ti wọn ri oku rẹ.

Ọkan lara awọn mọkaliki naa ti orukọ rẹ n jẹ Ọlasumbọ Adewale ṣalaye pe aṣọ awọṣere t- shirt ati ṣokoto penpe funfun ni arakunrin naa wọ,

okun bẹliti ọkọ kan to ri lagbegbe ibi ti awọn fọga to n tu taya ọkọ ṣe nibẹ wa, lo si fi so ara rẹ lọrun pa.

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa, Jamiu Awosọji ni gbogbo akitiyan lati wa ẹbi oloogbe naa ati lati mọ orukọ rẹ gan lo ṣi ja si pabo.

O ni pẹlu bi o ṣe jẹ pe pọ ero lo wọ wa wo oku arakunrin naa, ko si ẹni to lee fi ọwọ sọya pe oun mọ arakunrin to pokunso naa,

Eyi to mu ki wọn pa ọkan pọ si pe o ṣeeṣe ko jẹ pe lati ọna jinjin lo ti wa pa ara rẹ sibẹ.

Olugbe ileto naa miran tun ṣalaye pe awọn oniṣẹṣe ni ilu naa ti wa ṣe etutu gbogbo to yẹ lati ṣe ki wọn to gbe oku rẹ sọkalẹ lori igi to pokunso si.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin pẹlu la gb pe o ti fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.