Owolabi Ajasa rèé láì wọ aṣọ Ọlọ́pàá lórí ètò "Ṣóo láyà", ẹ wo bóyá ó Yorùbá rẹ̀ dájú tàbí ó gbé e gbági

Àkọlé fídíò, Ajasa Ṣolaya
Owolabi Ajasa rèé láì wọ aṣọ Ọlọ́pàá lórí ètò "Ṣóo láyà", ẹ wo bóyá ó Yorùbá rẹ̀ dájú tàbí ó gbé e gbági

Yatọ fun ko wọ aṣọ bi ọlọpaa lori itage to ti maa n ko ipa rẹ daadaa, ipa mii lo delẹ yii ti BBC Yoruba ni ki gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Owolabi Ajasa ko lori eto onibeere wa, "Ṣoo laya".

Eto yii jẹ eto to wa fun idaraya amọ o lee mu ẹni ti ko gbọ ede Yoruba laagun tabi mọ ipo wo lo wa gan ninu mimọ ede abinibi rẹ daju daju.

Ajasa
Owolabi Ajasa

Nigba ti ikọ eto Ṣoo Laya ti BBC Yoruba bi Owolabi Ajasa pe ṣe o laya, o fi igboya dahun pe oun laya o si ṣetan lati ṣi igba taa gbe siwaju rẹ.

Nigba ti Ọga Ọlọpaa inu fiimu yoo fi ṣi igba, o ga bi oke o le kenka o.

Ẹ wo bi Ajasa ṣe dahun awọn ibeere to wa siwaju rẹ ati iye maaki to gba ninu mimọ ede Yoruba daadaa.

Ṣoo Laya