Owolabi Ajasa police in Yoruba film: Irungbọ̀n tí mi ò ní ló mú mi ṣe oríire kíkó'pa ọlọ́pàá
"Mo tà epo bẹntiróò nílé epo débi pé wọ́n sọ mí lórúkọ kí n tó di olókìkì pẹ̀lú ṣíṣe ọlọ́pàá nínú fíìmù Yorùbá".
Oriṣiriṣi ipa ninu ere lo ti sọ ọpọ awọn oṣere di eekan ti gbogbo eeyan mọ.

Eeyan to jẹ pe bẹẹ ba ti ri orukọ rẹ lori pali fiimu, ẹ o ti mọ pe oun ni ọga ọlọpaa ti yoo maa mu ọdaran ninu fiimu ọhun.
Owolabi Ajasa gangan ni orukọ rẹ, o ba BBC Yoruba sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ti ṣalaye bo ṣe di ilumọọka oṣere torii pe o n ko ipa gẹgẹ bi ọlọpaa.
"Ọ̀pọ̀ gbàgbá pé ọlọ́pàá gangan ni mí kí ń tó wọ eré Tíátà – ìdí tí mi ò ṣe lè láyé láyé ṣe iṣẹ́ ọlọ́pàá ni pé kìí ṣe ohun ti a kọ mọ mi tabi ayanmọ mi".
Owolabi ni awọn eeyan tilẹ ti ṣi oun pe ni ọlọpaa ri loju aye ti wọn n pariwo pe "ara wọn ni o ti oun si sare pariwo pe oun ki ṣe ara wọn".

Oríṣun àwòrán, owolabiajasa1

Oríṣun àwòrán, OITHERS
Owolabi tun jẹ ka mọ wipe atapata dide ni oun amọ bo ṣe tiraka titi to fi doke kii ṣe kekere.
O ṣalaye pe kii ṣe nkan ti oun ba bẹrẹ ninu fiimu niyẹn amọ alakoso ere loun n ṣe tẹlẹ lẹyin Kamẹra ko to di pe wọn bẹrẹ si ni wo oun sunsun ti wọn ba ti fẹ yan eeyan fun ipa ọlọpaa ti wọn a si rii pe oun nikan ni ko ni irungbọn ninu gbogbo awọn ọkunrin to wa nibẹ tori eyi jẹ kan lara ohun amuyẹ pataki fun iṣẹ ọlọpaa ni Naijiria.

