Abuja-Kaduna Train Attack: Bí èèyàn kan lára èrò ọkọ̀ rélùwè tí wọ́n kọlù ní Kaduna ṣe gba òmìnira láhàámọ́ ajínigbé

Alwan Hassan

Oríṣun àwòrán, FALWAN HASSAN

Àwọn agbebọn to kọlu ọkọ reluwe kan nipinlẹ Kaduna, ti yọnda ẹnikan lara awọn ero ọkọ ti wọn jigbe.

Ọjọ Aje ọ̀sẹ̀ to kọja ni ìkọlù naa waye lasiko ti ọkọ reluwe naa n rinrinajo lati ilu Abuja si Kaduna.

Mọlẹbi ẹni ti wọn yọnda, Alwan Hassan, to jẹ oludari Banki eto iṣẹ agbẹ ni Naijiria, sọ fun BBC pe alẹ Ọjọ́rú ni wọn tu u silẹ.

Hassan ni ẹni àkọ́kọ́ to gba ominira lara awọn ero ọkọ reluwe ti awọn agbebọn naa jigbe.

Ninu fidio kan to wa lori ayelujara, eyi ti àwọn ajinigbe naa yà ṣáájú ominira rẹ, a ri Hassan to duro laarin gende ọkùnrin mẹrin to fi nkan bo oju wọn, ti wọn si gbe ìbọn dani.

Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn akẹgbẹ́ mi tó jóná nínú ọkọ̀ jáde, ṣe lara wọn ń bó, wọ́n ń tẹ́ wọn s'atẹ́gùn - Akẹkọ̀ọ́ Akungba

"Wọn duro ninu igbó lẹgbẹ́ ọkọ ijagun kan to dabi pe o ti jona".

Àwọn agbebọn naa sọ pe awọn pinnu lati yọnda rẹ nitori pe aanu rẹ ṣe wọn, paapaa nitori ọjọ́ ori rẹ, ẹ̀bẹ̀ to bẹ àwọn, ati nitori awẹ Ramadan to n lọ lọwọ.

Ẹnikan lara awọn agbebọn naa sọ pe ijọba gbọ́dọ̀ ṣe nkan ti awọn n fẹ́, ki àwọn to fun àwọn eeyan to ku ni òmìnira.

Ṣùgbọ́n wọn ko sọ awọn nkan ti wọn fẹ, tabi iye eeyan to kù si ahamọ wọn.

Àmọ́ wọn ni kii ṣe owó itusilẹ ni àwọn n fẹ́.

"Ìjọba, a ko fẹ owo yin. Ẹ mọ awọn nkan ti a n beere lọwọ yin."

Bakan naa ni wọn kò sọ ẹgbẹ́ ti wọn n sisẹ fun.

Àkọlé fídíò, Seye Malaolu: Bí mo ṣe rí àgbára ẹ̀jẹ̀ tó kúnlẹ̀, mò ń bèrè pé ṣé wọ́n pa Turkey níbí ni,

Titi di asiko yii, a ko tii mọ iye eeyan ti wọn jigbe lasiko ìkọlù naa.

Ṣùgbọ́n awọn alaṣẹ sọ pe ọtalelọọdunrun ati meji, 362, eeyan lo wa ninu ọkọ reluwe naa.

Wọn pa eeyan mẹjọ. Ko si iroyin kankan ti a gbọ nipa eeyan mejidinlaadọsan.

A ko le sọ boya gbogbo awọn ero ọkọ to di awati ni wọn jigbe tabi boya àwọn kan lara wọn ti lọ si ile wọn lẹyin ti wọn bọ́ ninu ikọlu naa, lai sọ fun ijọba.

Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir el-Rufai sọ pe àwọn agbesunmọmi Boko Haram lo ṣe ikọlu naa, pẹlu ajọṣepọ awọn ọ̀daràn kan to n sisẹ ni agbegbe ọhun.

Ọkọ reluwe

Oríṣun àwòrán, NRC

Àkọlé àwòrán, O kere tan eniyan mẹjọ lo ku ninu iṣẹlẹ naa to waye ni Ọjọ Kejidinlọgbọn, Osu Kẹta, ọdun 2022.

Eeyan 168 la ṣi n wa lara awọn to wa ninu ọkọ Reluwee

lleeṣẹ ọkọ reluwe ti kede pe eniyan mejidinlaadọjọ(168) ni awọn ṣi n wa lẹyin oṣẹ kan ti awọn agbebọn ṣekọlu si ọkọ irinna reluwe Abuja si Kaduna.

O kere tan eniyan mẹjọ lo ku ninu iṣẹlẹ naa to waye ni Ọjọ Kejidinlọgbọn, Osu Kẹta, ọdun 2022.

Awọn agbebọn naa lo lo ado oloro lati fi ṣọṣẹ ti wọn bẹrẹ si ni yinbọn lu ọkọ naa.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọkọ reluwe gbe jade ni wọn ti salaye pe eniyan ọ́talelọ́ọ̀dúnrún (362) lo wa ninu ọkọ reluwe naa nigba ti awọn agbebọn ṣekọlu si wọn.

Wọn fikun un pe awọn ko mọ ibi ti eniyan mejidinlaadọjọ(168) wa lọwọlọwọ.

Ileeṣẹ reluwe naa fikun un pe o ṣeeṣẹ ki awọn ẹlomiran ninu wọn ti pada si ile wọn tabi ki wọn wa lara awọn ti wọn jigbe lọ.

Ọkọ reluwe Abuja-Kaduna

N kò rí oorun sùn lórí iṣẹ́ ibi àwọn agbésùnmọ̀mí, òògùn oorun gan kò ràn mí - El-Rufai

Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai ti tọrọ aforijin lọwọ araalu lori ikọlu asekupani to n waye nipinlẹ Kaduna, paapaa si reluwe.

Gomina naa, ẹni ti ara rẹ si n gbọn lori awọn ikọlu lemọlemọ ọhun ni oun ko tii ri oorun sun lati ọjọbọ, koda oogun oorun gan ko sisẹ lara oun nitori iporuru ọkan.

El-Rufai ati reluwe ti wọn kọlu

Oríṣun àwòrán, KDGOV

El-Rufai, ẹni ti igbakeji rẹ, Hajiya Hadiza Sabuwa Balarabe atawọn ọmọ igbimọ alasẹ ijọba rẹ kọwọrin lọ sabẹwo si ijọba ibilẹ Giwa lọjọbọ lati bawọn eeyan ibẹ kẹdun, lo salaye bẹẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí pọ́ọ̀sì “customer” tí mi ò mọ

Ninu fọnran ohun gomina ti amugbalẹgbẹ gomina naa fi ransẹ si BBC, El-Rufai ni akoko diẹ ni ohun ni ẹtọ lati se adari ijọba mọ.

Amọ o ni lọjọ kan, oun yoo duro niwaju Oluwa lati salaye nipa awọn ohun to n sẹlẹ yii ati igbesẹ ti oun gbe nipa rẹ.

Àkọlé fídíò, Abdulfatai Balogun: N kò ríran àmọ́ oníṣòwò Yoghurt ní mí tó ń fi àwìn sàánú fún oníbàárà

"Mo n bẹru ọjọ ti maa duro niwaju Oluwa lati sọ awọn ohun gbogbo ti mo ti gbe ile aye se, ki wa ni maa ma sọ?

Nitori naa, mo n bẹbẹ fun idarijin yin, ki n le roju raye se ijọba."

Ko si aniani pe a ti kuna, ohun gbogbo si ti dojuru:

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Kaduna n fi ika hanu pe ijba to wa lode yii ti kuna, awọn ko si ni awijare kankan lori awọn ohun to n sẹlẹ yii.

O ni labẹ irora to lagbara ni oun ti n jẹwọ ẹsẹ oun, bẹẹ si ni ijẹwọ ẹsẹ naa gan tun n mu irora nla ba oun.

"Mo n ro tẹlẹ pe ko si isoro rara, amọ lọwọ lọwọ bayii, mo ti ri pe wahala gidi lo wa.

Lọdun meji si mẹta sẹyin, a mọ ibi tawọn adunkookomni naa wa, gbogbo rẹ la mọ.

A ni awọn eeyan to n se alami fun wa, to fi mọ awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ, ọlọpaa, ologun atawọn osisẹ alaabo miran.

Koda, a da awọn olubi ẹda to n sisẹ laabi yii mọ nitori ọ̀pọ wọn ni wọn ti pa sẹyin."

Àkọlé fídíò, Omi Adio Robbery: Èèyàn márùn-ún tí kò mọwọ́-mẹsẹ̀ ló kú lásìkò ìdigunjalè PoS l‘Omi Adio

Wọn ko awọn aba mi danu ni:

El-Rufai tẹsiwaju pe akoko kan wa ti oun daba pe ki awọn yabo gbogbo awọn igbo kijikiji ati abule tawọn agbesunmọmi yii wa, ka si maa jo wọn nina kanlẹ.

O ni oun daba naa nitori bi ọwọja isẹ ibi awọn agbesunmọmi naa se n peleke si lojoojumọ ni.

Amọ o ni oun ko ri atilẹyin awọn ologun gba lori aba naa nitori wọn ni niwọn igba ti kii se ogun lawọn n ja, tawọn ba se amusẹ aba mi, awọn le kan isoro lọjọ iwaju.

El-Rufai ni awọn ologun naa lo lero pe ni ọjọ iwaju, wọn le mu awọn tawọn ba lọ soke okun, ki wọn si fi ẹsun hihu iwa ọdaran loju ogun kan awọn pe awọn pa araalu.

O wa n kabamọ pe wọn ko se da ẹbi fawọn apaniyan yii, to si ni niwọn igba ti ile ẹjọ ti kede pe agbesunmọmi ni wọn, lawọn ti n pariwo pe ki wọn sun awn igbo nlanla naa, amọ wn ko tẹle imọran oun.

Àkọlé fídíò, Ọwọ́ mi méjèjì ni Fulani gé jábọ́, wọn ò tilẹ̀ jẹ́ kí n rí ìbọn gbèjà ara mi - Fijilante

Mo ti gbọ saaju pe wọn yoo kọlu reluwe:

Gomina ipinlẹ Kaduna ni o ti to osu meji sẹyin ti oun ti gbọ latẹnu awọn osisẹ alaabo ọtẹlẹmuyẹ pe awọn agbesunmọmi n gbero lati kọlu reluwe.

"Koda, gbogbo awọn ihuwasi ati lilọ bibọ awọn agbesunmọmi yii la mọ ati ibuba wọn pẹlu

Koda a ba awọn alasẹ ileesẹ reluwe sọrọ lori pe ki wọn mase rin ni alẹ amọ wọn kọ jalẹ.

A salaye ninu lẹta ta tun kọ si wọn pe o rọrun lati se akoso eto irinna loju mọmọ ti ohunkohun ba tiẹ sẹlẹ amọ wọn ko gbọ."

Mo n sọ gbogbo eleyi lati jẹ kawọn araalu mọ pe awọn eeyan kan to yẹ ki wọn se isẹ wọn, ni wọn kọ, ti wọn kuna lati se.

Amọ gomina naa ni awọn ko ni tu eekanna lọrun aarẹ ati ileesẹ ologun titi ti eto aabo to peye yoo fi fidi mulẹ.

Àkọlé fídíò, Roheem Bamimore: Ará àdúgbò ní àwọn afurasí tó pa ọmọ náà ti máa ń jalè tẹ́lẹ̀