NIN deadline - Àwọn tí kò so NIN mọ́ nọ́mbà wọn kò ní le pè mọ́

Oríṣun àwòrán, Other
Ìjọba Naijiria ti sọ fun awọn ileesẹ to n ri si ibanisọrọ lati fi ofin de ipe lori nọmba foonu awọn ti ko so nọmba NIN wọn mọ siimu foonu wọn.
Ọjọ́ Aje, ọjọ kẹrin, oṣù Kẹrin, ọdun 2022, ni àṣẹ naa yoo bẹ̀rẹ̀ isẹ.
Ọdun 2020 ni ìjọba gbe àṣẹ jade pe gbogbo ẹni to ba n lo nọmba foonu alagbeka gbọdọ so o mọ NIN wọn.
Wọn ni afojusun eto ilana naa ni lati ni akọsilẹ nipa gbogbo ọmọ Naijiria.
Oludari ẹ̀ka ibanisọrọ ninu ajọ Nigerian Communications Commission, NCC, Ikechukwu Adinde, ati akẹẹgbẹ rẹ ninu ajọ to n mojuto iforukọsilẹ NIN, Kayode Adegoke, lo jọ fi ikede naa sita.
Wọn ni, lati ọjọ kẹrin, oṣù Kẹrin, ẹni ti ko ba so nọmba foonu rẹ mọ NIN, ko ni le pè lori foonu rẹ.
Wọn ni ọpọ igba ni ijọba ti fi ọjọ kun gbedeke titẹle asẹ naa, asiko si ti to lati fi opin sii.
"Nibi ti ọrọ de bayii, ijọba ti ṣe eto lati rii pe awọn ọmọ Naijiria tẹle asẹ naa.
" Eto yii jẹ ọna lati mu ki ìjọba ṣe awọn ilana to yẹ ni ẹka eto aabo ati ọrọ aje."
Nitori naa ni ìjọba ṣe pasẹ fun gbogbo awọn ileesẹ ibanisọrọ, lati ri daju pe wọn ko jẹ ki gbogbo ẹni to ba n lo siimu lori foonu wọn, yala onibaara tuntun tabi atijọ, ni anfaani lati pe ẹnikẹ́ni lori foonu, ti wọn ko ba fi so nọmba wọn mọ NIN.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"O di igba ti iru awọn eeyan naa ba ṣe nkan to yẹ, ki ileesẹ ibanisọrọ to gbẹsẹ kuro lori nọmba wọn.
" Eyi ko tumọ si pe siimu naa ti bajẹ.*
Ìjọba sọ pe àwọn ti ofin yii kan si le lo siimu wọn, ni wọn igba ti wọn ba fi orukọ silẹ.
Bawo ni o ṣe le so nọmba foonu rẹ mọ NIN?

Oríṣun àwòrán, Other
O le lọ si awọn ibudo ti ijọba fi ọwọ si lati gba NIN rẹ.
Lẹyin naa ni waa so mọ nọmba foonu rẹ nipa lilo oju opo ti ajọ NIMC ati awọn ileesẹ ibanisọrọ la kalẹ.
MTN - *785#
Glo - 109 nọ́mbà NIN rẹ#
Airtel - *121*1#
Etisalat - *996#
O si tun le lo ori ayelujara 'App' àjọ NIMC.















