NIMC registration portal: Ìjọba Nàìjíríà fọjọ́ mọ́kànlélógún gbako kun ọjọ́ láti so NIN rẹ̀ mọ́ síìmù

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ijọba apapọ ti fi kun iye ọjọ ti ara ilu yoo fi forukọsilẹ lati so nọmba idanimọ NIN wọn mọ siimu wọn.
Anfaani afikun ọsẹ mẹta lawọn to ba ti ni NIN tẹlẹ yoo jẹ bayi ti awọn ti yoo si ṣẹṣẹ forukọsilẹ ni ọsẹ mẹfa.
Igbes yi waye lẹyin tara ilu faraya lori gbedeke ọlọjọkukuru ti ijọba ṣaaju gbe kalẹ.
Ọrọ ikede afikun yi waye ninu atjade kan ti ileeṣẹ ibaranisọrọ ati eto ọrọ aje ayelujara fi sita lọjọ Aje tii ṣe ọj kọkanlelogun oṣu Kejila.
Wọn sọ ninu atẹjade yi pe Minisita, Isa Pantami ati awọn alẹnulọrọ lẹka ibaraẹnisọrọ lo fẹnu ko lori igbes yi lasiko ipade kan.
Lara awọn to wa ni ipade naa ni awọn alaga NCC, EVC-NCC, DG-NITDA, DG-NIMC, ECTS/ECSM-NCC, Alaga ALTON ati awọn ileeṣẹ MTN, Airtel, Ntel, Glo, Smile, ati 9Mobile.

Oríṣun àwòrán, NATIONAL IDENTITY MANAGEMENT COMMISSION
"Ni ibamu pẹlu aṣẹ ijọba apapọ'' wọn ni awọn gbe igbesẹ wọn yi:
"Afikun ọsẹ mta fawọn to ni NIN bẹrẹ lati ọgbọnjọ Oṣu Kejila 2020- ọjọ Kọkandinlogun Oṣu Kini 2021'' ati
"Ọsẹ mẹfa fawọn ti ko ni NIN tẹlẹ lọgbọnjọ Oṣu Kejila 2020- Ọjọ Kẹsan oṣu Keji ọdun 2021."

Oríṣun àwòrán, Other
Saaju ni Ajọ NCC ti fun araalu ni gbedeke titi di ọgbọnjọ Oṣu Kejila ọdun 2020 lati lọ gba NIN wọn tabi ki wọn padanu siimu wọn.

Oríṣun àwòrán, Google
Àwọn ìgbésẹ̀ tóo lè fi so NIN rẹ̀ pọ mọ́ síìmù MTN, Glo, Airtel ati 9Mobile rẹ
MTN, Glo, Airtel àti 9mobile ni àwọn síìmù ìbánisọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jùlọ tí àwọn ènìyàn ń lò ní Nàìjíría, nítorí ìdí èyí ni wọ́n ṣe fí àwọn ìlànà tí ènìyàn le gbà láti mọ́ NIN rẹ̀ lórí ìtàkùn wọ́n, pàápàá jùlọ tó bá jk nọ́mbà náà ni ènìyàn lò lásìkò tó forúkọ sílẹ̀ fún ìwé ìdánimọ̀.
Èyí jẹyọ lẹ́yìn ti àjọ tó n rí sí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ (NCC) fún gbogbo ẹni tó ń lo ẹ̀rọ iléwọ́ láti lọ gba NIN wọ́n tàbi kí wọ́n pàdànú síìmù wọ́n.
Àjọ NCC fí gbèdéke ọ̀sẹ̀ méjì sílẹ̀, ìyẹn ọgbọ̀njọ́, oṣù kejìlá pá kí gbogbo àwọ́n ilé iṣẹ̀ tó mójútó ọ̀rọ̀ síìmù tí síìmù ẹni ti kò bá ní NIN pa.
- Kí ló tún ṣe Òṣèré fíìmù Yorùbá míì tó ń gba ẹ̀jẹ̀ àtomi níléèwòsàn?
- Àwọn agbébọn tún gbìyànjú láti gbé akẹ́kọ̀ọ́ ilé Keu 80 ní Katsina
- Njẹ́ ó wù ọ́ láti jànfàání ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ àjọ Commowealth 2020/2021? Wo ọ̀nà àbáyọ níbí
- Ọsẹ́ tí ọkọ̀ aképo tó gbiná lẹ́bàá Otedola Estate l'Eko ṣe rèé
- Ojúlówó ọmọ Oluyole gan ni Adedibu, ìpasẹ̀ akọni náà ló tọ̀ nígbà ayé rẹ̀
Ọ̀nà àbáyọ rèé lórí bi ó ṣe lé yẹ NIN rẹ̀ wò nípa lílo kóòdì USSD lórí ọẹ̀rọ ìléwọ́ rẹ.
Àjọ NIMC ni kí àwọn ènìyàn máa lo *346# láti ri nọ́mbà NIN.
Kóòdì USSD yìí wà fún àwọ oníbàárà MTN, Glo, Airtel ati 9mobile.

Oríṣun àwòrán, NATIONAL IDENTITY MANAGEMENT COMMISSION
NIN Àwọn ǹkan ti ó nílò láti fórukọsílẹ̀ fún NIN rẹ
Tí o bá fẹ́ fi orúkọ sílẹ̀ fún NIN fún nọ́mbà ìpè rẹ, àwọn ǹkan tí o nílò rèé:
- Nọ́mbà ìléwọ́ rẹ
- rẹ lẹ́kùnrẹ́rẹ́
- Nọ́mbà NIN tí o ri nígbà tí o tẹ kóòdù *346#
- Adírẹ̀ẹ̀sì méèlì rẹ̀
- Ọjọ́ ìbí rẹ
Bí o ṣe le soo NIN rẹ̀ pọ̀ mọ́ Nọ́mbà MTN
Bẹ́ ojú ọ̀pọ́ NIN fún àwọn oníbara yìí wò fún ìforúkọ sílẹ̀ https://mtnonline.com/nin/
Òó ri fọ́ọ̀mù tí ó kọ orúkọ rẹ sí lẹ́kúnrẹ́rẹ́.
Lẹ́yìn náà tẹ nọ́mbà MTN rẹ sójú rẹ̀.
Tẹ NIN rẹ̀.
Tẹ àdírẹ̀ẹ̀sí méèlì rẹ síbẹ̀
Tẹ bọ́tìnì ti wọ́n kọ "Submit" si

Oríṣun àwòrán, MTN
Kóòdù tí ó lè lò fún MTN
Ó tún le tẹ *785#
Yóò bèrè pé kí ẹ tẹ nọ́mbà mọ́kànlá tí àjọ NIMC fún ọ yóò sọ fún ọ pé ó ti yege.
Bí o ṣe le so NIN rẹ̀ pọ̀ mọ nọ́mbà Glo [Globacom]
Tí ó bá fẹ́ fi NIN rẹ sórí nọ́mbà Glo kọ "Update NIN(fi ààyè sílẹ̀) orúkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ (fi ààyè sílẹ̀) fi orúkọ kejì sí kí o sì fi ránsẹ́ sí 109
Bí o ṣe le so NIN mọ nọ́mba Airtel
- Ìgbẹ́sẹ̀ àkọ́kọ́ ni láti tẹ *121*1#
- Tẹ́ nọ́mba NIN rẹ oní nọ́mba mọ́kànlá síbẹ̀
- Lẹ́yìn èyí ni èsì yóòmwọlé bi àtẹ̀jísẹ́ pé, ó ti ṣe àṣeyege
Bí o ṣe le so NIN rẹ mọ́ Nọ́mbà 9mobile rẹ.
- Lọ sí ojú òpò website https://9mobile.com.ng/nin
- Tẹ ààyè tó ni àwọ ewé, níbi ti wọ́n kọ "Verify and link your NIN Now" si
- Tẹ nọ́mba rẹ àti gbogbo ǹkan tí wan ba bèrè síbẹ̀
Ilé iṣẹ́ tó n mójú tó ọ̀rọ̀ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àtí ọ̀rọ̀ orí ayélujára ti pàsẹ fún gbogbo àwọn ilé iṣk ibáraẹnisọ̀rọ̀ gbogbo láti wọ́gile ogún náírà tí wan yọ tí àwọn ará ìlú bá fk mọ nọ́mbà NIN wọ́n ni kíá.
Ilé iṣẹ náà sàlàyé pé èyí ni láti jẹ kí gbogbo ǹkan rọrùn fún ará ìlú.
Èyí túmọ̀ sí pé, ọ̀fẹ́ ni tí o bá ló kóòdú *346#.













